Neh 13:10-31
Neh 13:10-31 Bibeli Mimọ (YBCV)
Mo si mọ̀ pe, a kò ti fi ipin awọn ọmọ Lefi fun wọn; awọn ọmọ Lefi ati awọn akọrin, ti nṣe iṣẹ, si ti salọ olukuluku si oko rẹ̀. Nigbana ni mo si ba awọn ijoye jà, mo si wipe, Ẽṣe ti a fi kọ̀ ile Ọlọrun silẹ? Mo si ko wọn jọ, mo si fi wọn si ipò wọn. Nigbana ni gbogbo Juda mu idamẹwa ọka ati ọti-waini titun ati ororo wá si ile iṣura. Mo si yàn olupamọ si ile iṣura, Ṣelemiah alufa ati Sadoku akọwẹ, ati ninu awọn ọmọ Lefi, Pedaiah: ati lọwọkọwọ wọn ni Hanani ọmọ Sakkuri, ọmọ Mattaniah: nitoriti a kà wọn si olõtọ, iṣẹ́ wọn si ni lati ma pin fun awọn arakunrin wọn. Ranti mi, Ọlọrun mi, nitori eyi, ki o má si nu iṣẹ rere ti mo ti ṣe fun ile Ọlọrun mi, nu kuro, ati fun akiyesi rẹ̀. Li ọjọ wọnni ni mo ri awọn kan ti nfunti ni Juda li ọjọ isimi, awọn ti nmu iti ọka wale, ti ndi ẹrù rù kẹtẹkẹtẹ; ti ọti-waini, pẹlu eso àjara, ati eso ọ̀pọtọ, ati gbogbo oniruru ẹrù ti nwọn nmu wá si Jerusalemu li ọjọ isimi: mo si jẹri gbè wọn li ọjọ ti nwọn ntà ohun jijẹ. Awọn ara Tire ngbe ibẹ pẹlu, ti nwọn mu ẹja, ati oniruru ohun èlo wá, nwọn si ntà li ọjọ isimi fun awọn ọmọ Juda, ati ni Jerusalemu. Nigbana ni mo ba awọn ijoye Juda jà, mo si wi fun wọn pe, ohun buburu kili ẹnyin nṣe yi, ti ẹ si mba ọjọ isimi jẹ. Bayi ha kọ́ awọn baba nyin ṣe, Ọlọrun kò ha mu ki gbogbo ibi yi wá sori wa, ati sori ilu yi? ṣugbọn ẹnyin mu ibinu ti o pọ̀ju wá sori Israeli nipa biba ọjọ isimi jẹ. O si ṣe, nigbati ẹnu-bode Jerusalemu bẹ̀rẹ si iṣu okunkun ṣaju ọjọ isimi, mo paṣẹ pe, ki a tì ilẹkun, ki ẹnikẹni má ṣi i titi di ẹhin ọjọ isimi, ninu awọn ọmọkunrin mi ni mo fi si ẹnu-bode, ki a má ba mu ẹrù wọle wá li ọjọ isimi. Bẹ̃ni awọn oniṣòwo ati awọn ti ntà oniruru nkan sùn lẹhin odi Jerusalemu li ẹrinkan tabi ẹrinmeji. Nigbana ni mo jẹri gbè wọn, mo si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi sùn lẹhin odi, bi ẹnyin ba tun ṣe bẹ̃, emi o fọwọ bà nyin. Lati àkoko na lọ ni nwọn kò si wá lọjọ isimi mọ. Mo si paṣẹ fun awọn ọmọ Lefi, ki nwọn ya ara wọn si mimọ, ki nwọn si wa ṣọ ẹnu-bode lati pa ọjọ isimi mọ. Ranti mi Ọlọrun mi nitori eyi pẹlu, ki o si da mi si gẹgẹ bi ọ̀pọ ãnu rẹ. Pẹlupẹlu li ọjọ wọnni, mo ri ara Juda ti mba obinrin awọn ara Aṣdodi, Ammoni, ati ti Moabu gbe: Awọn ọmọ wọn si nsọ apakan ède Aṣdodi, nwọn kò si le sọ̀rọ li ède awọn ara Juda, ṣugbọn gẹgẹ bi ède olukuluku. Mo si ba wọn jà, mo gàn wọn, mo lù ninu wọn, mo tu irun wọn, mo mu wọn fi Ọlọrun bura pe, Ẹnyin kì yio fi ọmọbinrin nyin fun ọmọkunrin nwọn, tabi ọmọbinrin nwọn fun ọmọkunrin nyin tabi fun ara nyin. Solomoni ọba Israeli kò ha dẹṣẹ nipa nkan wọnyi? Bẹ̃ni li ãrin orilẹ-ède pupọ, kò si ọba kan bi on ti Ọlọrun rẹ̀ fẹràn; Ọlọrun si fi jẹ ọba li ori gbogbo Israeli, bẹ̃ni on li awọn àjeji obinrin mu ki o ṣẹ̀. Njẹ ki awa ha gbọ́ ti nyin, lati ṣe gbogbo buburu nla yi, lati ṣẹ̀ si Ọlọrun sa, ni gbigbe awọn àjeji obinrin ni iyawo? Ati ọkan ninu awọn ọmọ Jehoiada, ọmọ Eliaṣibu olori alufa, jẹ ana Sanballati, ara Horoni, nitori na mo le e kuro lọdọ mi. Ranti wọn, Ọlọrun mi, nitoriti nwọn ti ba oyè alufa jẹ, pẹlu majẹmu oyè-alufa, ati ti awọn ọmọ Lefi. Bayi ni mo wẹ̀ wọn nù kuro ninu gbogbo awọn alejo, mo si yan ẹ̀ṣọ awọn alufa, ati ti awọn ọmọ Lefi, olukuluku ninu iṣẹ tirẹ̀. Ati fun ẹ̀bun igi li àkoko ti a yàn, ati fun akọso. Ranti mi, Ọlọrun mi, fun rere.
Neh 13:10-31 Yoruba Bible (YCE)
Mo tún rí i wí pé wọn kò fún àwọn ọmọ Lefi ní ẹ̀tọ́ wọn, tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ọmọ Lefi ati àwọn akọrin, tí wọn ń ṣe iṣẹ́ náà fi sá lọ sí oko wọn. Nítorí náà, mo bá àwọn olórí wí, mo ní “Kí ló dé tí ilé Ọlọrun fi di àpatì?” Mo kó wọn jọ, mo sì dá wọn pada sí ààyè wọn. Gbogbo àwọn ọmọ Juda mú ìdámẹ́wàá ọkà, ati waini ati òróró wá sí ilé ìṣúra. Mo bá yan àwọn kan tí yóo máa mójútó ètò ìsúná owó ní àwọn ilé ìṣúra. Àwọn ni: Ṣelemaya, alufaa, Sadoku, akọ̀wé, ati Pedaaya, ọmọ Lefi. Ẹni tí ó jẹ́ igbákejì wọn ni Hanani ọmọ Sakuri, ọmọ Matanaya, nítorí pé wọ́n mọ̀ wọ́n sí olóòótọ́, iṣẹ́ wọn sì ni láti fún àwọn arakunrin wọn ní ẹ̀tọ́ wọn. Ọlọrun mi, ranti mi, nítorí nǹkan wọnyi, kí o má sì pa gbogbo nǹkan rere tí mo ti ṣe sí tẹmpili rẹ rẹ́ ati àwọn iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Ní àkókò náà mo rí àwọn ọmọ Juda tí wọn ń fún ọtí waini ní ọjọ́ ìsinmi, tí wọ́n sì ń kó ìtí ọkà jọ, tí wọn ń dì wọ́n ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, tí wọn sì ń gbé waini, ati èso girepu, ati igi ọ̀pọ̀tọ́ ati oríṣìíríṣìí ẹrù wúwo wá sí Jerusalẹmu ní ọjọ́ ìsinmi, mo bá kìlọ̀ fún wọn nípa ọjọ́ tí ó yẹ kí wọ́n máa ta oúnjẹ. Àwọn ọkunrin kan láti Tire pàápàá tí wọn ń gbé ààrin ìlú náà mú ẹja wá ati oríṣìíríṣìí àwọn nǹkan títà, wọ́n sì ń tà wọ́n fún àwọn eniyan Juda ati ni Jerusalẹmu ní ọjọ́ ìsinmi. Mo bá àwọn ọlọ́lá Juda wí, mo ní, “Irú nǹkan burúkú wo ni ẹ̀ ń ṣe yìí, tí ẹ̀ ń rú òfin ọjọ́ ìsinmi? Irú nǹkan burúkú yìí kọ́ ni àwọn baba yín pàápàá ṣe tí Ọlọrun fi mú kí ibi bá àwa ati ìlú yìí? Sibẹ, ẹ tún ń rú òfin ọjọ́ ìsinmi, ẹ̀ ń fa ìrúnú Ọlọrun sórí Israẹli.” Nígbà tí ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ṣú ní àwọn Ẹnubodè Jerusalẹmu kí ó tó di ọjọ́ ìsinmi, mo pàṣẹ pé kí wọ́n ti gbogbo ìlẹ̀kùn, ati pé wọn kò gbọdọ̀ ṣí i sílẹ̀ títí tí ọjọ́ ìsinmi yóo fi rékọjá. Mo yan díẹ̀ lára àwọn iranṣẹ mi sí àwọn ẹnubodè náà, kí wọ́n má baà kó ẹrù kankan wọlé ní ọjọ́ ìsinmi. Gbogbo àwọn oníṣòwò ati àwọn tí wọn ń ta oríṣìíríṣìí nǹkan sùn sí ẹ̀yìn odi Jerusalẹmu bíi ẹ̀ẹ̀kan tabi ẹẹmeji. Ṣugbọn mo kìlọ̀ fún wọn, mo sì sọ fún wọn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ odi? Bí ẹ bá tún ṣe bẹ́ẹ̀ n óo jẹ yín níyà.” Láti ìgbà náà ni wọn kò wá ní ọjọ́ ìsinmi mọ́. Mo kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Lefi pé kí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́, kí wọ́n wá láti ṣọ́ àwọn ẹnubodè, kí wọn lè pa ọjọ́ ìsinmi mọ́. Ranti eléyìí fún rere mi, Ọlọrun mi, kí o sì dá mi sí gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ńlá rẹ tí kì í yẹ̀. Nígbà náà, mo rí àwọn Juu tí wọn fẹ́ iyawo lára àwọn ará Aṣidodu, àwọn ará Amoni ati ti Moabu, ìdajì àwọn ọmọ wọn ni kò gbọ́ èdè Juda àfi èdè Aṣidodu. Èdè àwọn àjèjì nìkan ni wọ́n gbọ́. Mo bínú sí wọn mo sì gbé wọn ṣépè, mo na àwọn mìíràn, mo sì fa irun wọn tu. Mo sì mú wọn búra ní orúkọ Ọlọrun wí pé: “Ẹ kò gbọdọ̀ fi àwọn ọmọbinrin yín fún àwọn ọmọ wọn, tabi kí ẹ fẹ́ àwọn ọmọ wọn fún àwọn ọmọkunrin yín tabi kí ẹ̀yin pàápàá fẹ́mọ lọ́wọ́ wọn. Ṣebí Solomoni ọba pàápàá dẹ́ṣẹ̀ nítorí ó fẹ́ irú àwọn obinrin bẹ́ẹ̀. Kò sí ọba tí ó dàbí rẹ̀ láàrin àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, Ọlọrun sì fẹ́ràn rẹ̀, Ọlọrun sì fi jọba lórí gbogbo Israẹli, sibẹsibẹ, àwọn obinrin àjèjì ni wọ́n mú un dẹ́ṣẹ̀. Ṣé a óo wá tẹ̀lé ìṣìnà yín, kí á sì máa ṣe irú nǹkan burúkú yìí, kí á sì máa fẹ́ àwọn obinrin àjèjì tí ó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọrun wa?” Ọ̀kan ninu àwọn ọmọkunrin Jehoiada, ọmọ Eliaṣibu olórí alufaa, fẹ́ ọmọ Sanbalati ará Horoni kan, nítorí náà mo lé e kúrò lọ́dọ̀ mi. Ranti, Ọlọrun mi, nítorí pé wọ́n rú òfin àwọn alufaa, wọn kò sì mú ẹ̀jẹ́ àwọn alufaa ati ti àwọn ọmọ Lefi ṣẹ. Nítorí náà mo wẹ̀ wọ́n mọ́ ninu gbogbo nǹkan àjèjì, mo sì fi ìdí iṣẹ́ wọn múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alufaa ati ọmọ Lefi. Olukuluku sì ní iṣẹ́ tí ó ń ṣe, mo pèsè igi ìrúbọ, ní àkókò tí ó yẹ ati àwọn èso àkọ́so. Ranti mi sí rere, Ọlọrun mi.
Neh 13:10-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mo sì tún gbọ́ pé, kò fi àwọn ìpín tí a yà sọ́tọ̀ fún àwọn Lefi, àwọn akọrin tí ń ṣe àkóso ìsìn sì ti padà sí ẹnu onírúurú iṣẹ́ wọn. Nígbà náà ni mo bá àwọn ìjòyè wí, mo sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí a fi kọ ilé Ọlọ́run sílẹ̀?” Nígbà náà ni mo pè wọ́n jọ pọ̀, mo sì fi olúkúlùkù sí ẹnu iṣẹ́ rẹ̀. Gbogbo Juda mú ìdámẹ́wàá ọkà, wáìnì tuntun àti òróró wá sínú yàrá ìkó-nǹkan-pamọ́-sí. Mo sì fi àlùfáà Ṣelemiah, Sadoku akọ̀wé àti ọmọ Lefi kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Pedaiah ṣe alákòóso àwọn yàrá ìkó-nǹkan-pamọ́-sí. Mo sì yan Hanani ọmọ Sakkuri, ọmọ Mattaniah bí olùrànlọ́wọ́ ọ wọn. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni a kà sí àwọn tó ṣé e gbẹ́kẹ̀lé. Àwọn ni a yàn láti máa pín ohun èlò fún àwọn arákùnrin wọn. Rántí ì mi fún èyí, Ọlọ́run mi, kí o má sì ṣe gbàgbé ohun tí mo fi òtítọ́ ṣe fún ilé Ọlọ́run mi yìí àti fún iṣẹ́ ẹ rẹ̀ gbogbo. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, mo rí àwọn ènìyàn ní Juda tí wọ́n ń fúntí ní ọjọ́ ìsinmi, tí wọ́n sì ń gbé ọkà wọlé, tí wọn ń di ẹrù lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ pẹ̀lú wáìnì, èso àjàrà, ọ̀pọ̀tọ́ àti onírúurú ẹrù. Wọ́n sì ń kó gbogbo èyí wá sí Jerusalẹmu ní ọjọ́ ìsinmi. Nítorí náà, mo kìlọ̀ fún wọn nípa títa oúnjẹ ní ọjọ́ náà. Àwọn ará Tire ti ń gbé nínú Jerusalẹmu ń gbé ẹja àti onírúurú ọjà wá fún títà ní ọjọ́ ìsinmi fún àwọn ènìyàn Jerusalẹmu àti fún àwọn ọmọ Juda. Mo bá àwọn ọlọ́lá Juda wí, mo wí fún wọn pé, “Èwo ni ohun búburú tí ẹ ń ṣe yìí ti ẹ ń ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́. Ṣé àwọn baba ńlá yín kò ha ti ṣe nǹkan kan náà tí Ọlọ́run wa fi mú gbogbo àjálù yìí wá orí wa, àti sórí ìlú yìí? Báyìí, ẹ̀yin tún ń ru ìbínú sókè sí i sórí Israẹli nípa bíba ọjọ́ ìsinmi jẹ́.” Nígbà tí ojú ọjọ́ ń bora ní ẹnu ibodè Jerusalẹmu, ṣáájú ọjọ́ ìsinmi, mo pàṣẹ pé kí a ti àwọn ìlẹ̀kùn, kí wọn má sì ṣí i títí tí ọjọ́ ìsinmi yóò fi kọjá. Mo yan àwọn ìránṣẹ́ mi láti ṣọ́ ẹnu ibodè, kí a má ba à lè gbé ẹrù kankan wọlé ní ọjọ́ ìsinmi. Síbẹ̀, àwọn tí ń tà àti àwọn tí ń rà sùn ẹ̀yìn odi Jerusalẹmu ní ẹ̀ẹ̀kan tàbí ẹ̀ẹ̀mejì. Ṣùgbọ́n mo kìlọ̀ fún wọn pé, “Èétijẹ́ ti ẹ̀yin fi ń sùn ní ẹ̀yin odi ní òru? Bí ẹ̀yìn bá tún dánwò mọ́, èmi yóò fi ọwọ́ líle mú yín.” Láti ọjọ́ náà lọ, wọn kò sì wá ní ọjọ́ ìsinmi mọ́. Nígbà náà ni mo pàṣẹ fún àwọn ọmọ Lefi pé kí wọn ya ara wọn sí mímọ́, kí wọn sì ṣọ́ ẹnu ibodè kí a lè pa ọjọ́ ìsinmi mọ́. Tún rántí mi fún èyí, Ọlọ́run mi, kí o sì fi àánú un rẹ hàn fún mi gẹ́gẹ́ bí i títóbi ìfẹ́ ẹ̀ rẹ. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, mo rí àwọn ọkùnrin Juda tí wọ́n fẹ́ àwọn obìnrin láti Aṣdodu, Ammoni àti Moabu. Ìdajì àwọn ọmọ wọn ń sọ èdè Aṣdodu tàbí èdè ọ̀kan lára àwọn ènìyàn mìíràn tókù, wọn kò sì mọ bí a ṣe ń sọ èdè Juda. Mo bá wọn wí mo sì gégùn ún lé wọn lórí. Mo lu àwọn ènìyàn díẹ̀ nínú wọn mo sì fa irun orí wọn tu. Mo mú kí wọn búra ní orúkọ Ọlọ́run, kí wọn wí pé, “Ẹ̀yin kì yóò fi àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín ní ìyàwó tàbí fún ẹ̀yin tìkára yín. Kì í ha á ṣe àwọn ìgbéyàwó bí irú èyí ni ọba Solomoni fi dá ẹ̀ṣẹ̀? Láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, kò sí ọba kan bí i tirẹ̀. Ọlọ́run rẹ̀ fẹ́ràn rẹ̀, Ọlọ́run sì fi jẹ ọba lórí i gbogbo Israẹli, ṣùgbọ́n àwọn obìnrin àjèjì ti sọ ọ́ sínú òfin ẹ̀ṣẹ̀. Ǹjẹ́ ó ha yẹ kí àwa tún gbọ́ báyìí pé ẹ̀yin náà tún ń ṣe àwọn nǹkan tí ó burú jọjọ wọ̀nyí tí ẹ sì ń ṣe aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wa nípa fífẹ́ àwọn obìnrin àjèjì?” Ọ̀kan lára àwọn ọmọ Joiada, ọmọ Eliaṣibu olórí àlùfáà jẹ́ àna Sanballati ará a Horoni. Mo sì lé e jáde kúrò lọ́dọ̀ mi. Rántí wọn, Ọlọ́run mi, nítorí wọ́n ti ba iṣẹ́ àlùfáà jẹ́ pẹ̀lú májẹ̀mú iṣẹ́ àlùfáà àti ti àwọn Lefi. Nítorí náà, mo ya àwọn àlùfáà àti àwọn Lefi sí mímọ́ kúrò nínú gbogbo ohun àjèjì, mo sì yan iṣẹ́ fún wọn, olúkúlùkù sí ẹnu iṣẹ́ rẹ̀ Mo sì tún pèsè fún ọrẹ, igi—pákó ní àkókò tí a yàn àti fún àwọn èso àkọ́so.