AWỌN ti o fi èdidi di i ni Nehemiah, bãlẹ, ọmọ Hakaliah, ati Sidkijah.
Seraiah, Asariah, Jeremiah,
Paṣuri, Amariah, Malkijah,
Hattuṣi, Ṣebaniah, Malluki,
Harimu, Meremoti, Obadiah,
Danieli, Ginnetoni, Baruki,
Meṣullamu, Abijah, Mijamini,
Maaṣiah, Bilgai, Ṣemaiah: alufa li awọn wọnyi.
Ati awọn ọmọ Lefi: ati Jeṣua ọmọ Asaniah, Binnui, ọkan ninu awọn ọmọ Henadadi, Kadmieli;
Ati awọn arakunrin wọn, Ṣebaniah, Hodijah, Kelita, Pelaiah, Hanani,
Mika, Rehobu, Haṣabiah,
Sakkuri, Ṣerebiah, Ṣebaniah,
Hodijah, Bani, Beninu.
Awọn olori awọn enia; Paroṣi, Pahati-moabu, Elamu, Sattu, Bani.
Bunni, Asgadi, Bebai,
Adonijah, Bigfai, Adini,
Ateri, Hiskijah, Assuri,
Hodijah, Haṣumu, Besai,
Harifi, Anatoti, Nebai,
Magpiaṣi, Meṣullamu, Hasiri,
Meṣesabeeli, Sadoku, Jaddua,
Pelatiah, Hanani, Anaiah,
Hoṣea, Hananiah, Haṣubu,
Halloheṣi, Pileha, Ṣobeki,
Rehumu, Hasabna, Maaseiah,
Ati Ahijah, Hanani, Anani,
Malluku, Harimu, Baana.
Ati awọn enia iyokù, awọn alufa, awọn ọmọ Lefi, awọn adèna, awọn akọrin, awọn Netinimu, ati gbogbo awọn ti o ya ara wọn kuro lọdọ awọn enia ilẹ na si ofin Ọlọrun, aya wọn, awọn ọmọ wọn ọkunrin, ati awọn ọmọ wọn obinrin, gbogbo ẹniti o ni ìmọ ati oye;
Nwọn faramọ awọn arakunrin wọn, awọn ijoye wọn, nwọn si wọ inu èpe ati ibura, lati ma rìn ninu ofin Ọlọrun, ti a fi lelẹ nipa ọwọ Mose iranṣẹ Ọlọrun, lati kiyesi, ati lati ṣe gbogbo aṣẹ Jehofah, Oluwa wa, ati idajọ rẹ̀, ati ilana rẹ̀;
Ati pe awa kì yio fi awọn ọmọbinrin wa fun awọn enia ilẹ na, bẹ̃li awa kì yio fẹ ọmọbinrin wọn fun awọn ọmọ wa.
Bi awọn enia ilẹ na ba mu ọjà tabi ohun jijẹ wa li ọjọ isimi lati tà, awa kì yio rà a li ọwọ wọn li ọjọ isimi, tabi li ọjọ mimọ́: awa o si fi ọdun keje silẹ, ati ifi-agbara-gba gbèse.
Awa si ṣe ilàna fun ara wa pe, ki olukuluku ma san idamẹta ṣekeli li ọdọdun fun iṣẹ ile Ọlọrun wa.
Nitori àkara ifihàn, ati nitori ẹbọ ohun jijẹ igbagbogbo, ati nitori ẹbọ sisun igbagbogbo, ti ọjọ isimi, ti oṣù titun, ti àse ti a yàn, ati nitori ohun mimọ́, ati nitori ẹbọ ẹ̀ṣẹ lati ṣe ètutu fun Israeli, ati fun gbogbo iṣẹ ile Ọlọrun wa.
Awa si dìbo larin awọn alufa awọn ọmọ Lefi, ati awọn enia, fun ọrẹ igi, lati mu u wá si ile Ọlọrun wa, gẹgẹ bi idile awọn baba wa li akoko ti a yàn li ọdọdun, lati fi daná li ori pẹpẹ Oluwa Ọlọrun wa, gẹgẹ bi a ti kọ ọ ninu ofin.
Ati lati mu akọso ilẹ wa wá, ati gbogbo akọso eso igi gbogbo, li ọdọdun si ile Oluwa wa:
Pẹlu akọbi awọn ọmọ wa ọkunrin, ati ti ohun ọ̀sin wa, gẹgẹ bi ati kọ ninu ofin, akọbi awọn ẹran-nla wa, ati ti agutan wa, lati mu wọn wá si ile Ọlọrun wa, fun awọn alufa ti nṣiṣẹ ni ile Ọlọrun wa.
Ki awa si mu akọso iyẹfun pipò wa wá, ati ọrẹ wa, ati eso oniruru igi wa, ti ọti-waini ati ti ororo fun awọn alufa, si iyẹwu ile Ọlọrun wa, ati idamẹwa ilẹ wa fun awọn ọmọ Lefi, ki awọn ọmọ Lefi ki o le ni idamẹwa ninu gbogbo ilu arọko wa.
Alufa ọmọ Aaroni yio si wà pẹlu awọn ọmọ Lefi, nigbati awọn ọmọ Lefi yio gba idamẹwa: awọn ọmọ Lefi yio si mu idamẹwa ti idamẹwa na wá si ile Ọlọrun wa, sinu iyẹwu, sinu ile iṣura.
Nitori awọn ọmọ Israeli ati awọn ọmọ Lefi ni yio mu ọrẹ ọkà wá, ti ọti-waini titun, ati ororo, sinu iyẹwu, nibiti ohun èlo ibi mimọ́ gbe wà, ati awọn alufa ti nṣiṣẹ, ati awọn adèna, ati awọn akọrin: awa kì yio si kọ̀ ile Ọlọrun wa silẹ.