Neh 10:1-39

Neh 10:1-39 Bibeli Mimọ (YBCV)

AWỌN ti o fi èdidi di i ni Nehemiah, bãlẹ, ọmọ Hakaliah, ati Sidkijah. Seraiah, Asariah, Jeremiah, Paṣuri, Amariah, Malkijah, Hattuṣi, Ṣebaniah, Malluki, Harimu, Meremoti, Obadiah, Danieli, Ginnetoni, Baruki, Meṣullamu, Abijah, Mijamini, Maaṣiah, Bilgai, Ṣemaiah: alufa li awọn wọnyi. Ati awọn ọmọ Lefi: ati Jeṣua ọmọ Asaniah, Binnui, ọkan ninu awọn ọmọ Henadadi, Kadmieli; Ati awọn arakunrin wọn, Ṣebaniah, Hodijah, Kelita, Pelaiah, Hanani, Mika, Rehobu, Haṣabiah, Sakkuri, Ṣerebiah, Ṣebaniah, Hodijah, Bani, Beninu. Awọn olori awọn enia; Paroṣi, Pahati-moabu, Elamu, Sattu, Bani. Bunni, Asgadi, Bebai, Adonijah, Bigfai, Adini, Ateri, Hiskijah, Assuri, Hodijah, Haṣumu, Besai, Harifi, Anatoti, Nebai, Magpiaṣi, Meṣullamu, Hasiri, Meṣesabeeli, Sadoku, Jaddua, Pelatiah, Hanani, Anaiah, Hoṣea, Hananiah, Haṣubu, Halloheṣi, Pileha, Ṣobeki, Rehumu, Hasabna, Maaseiah, Ati Ahijah, Hanani, Anani, Malluku, Harimu, Baana. Ati awọn enia iyokù, awọn alufa, awọn ọmọ Lefi, awọn adèna, awọn akọrin, awọn Netinimu, ati gbogbo awọn ti o ya ara wọn kuro lọdọ awọn enia ilẹ na si ofin Ọlọrun, aya wọn, awọn ọmọ wọn ọkunrin, ati awọn ọmọ wọn obinrin, gbogbo ẹniti o ni ìmọ ati oye; Nwọn faramọ awọn arakunrin wọn, awọn ijoye wọn, nwọn si wọ inu èpe ati ibura, lati ma rìn ninu ofin Ọlọrun, ti a fi lelẹ nipa ọwọ Mose iranṣẹ Ọlọrun, lati kiyesi, ati lati ṣe gbogbo aṣẹ Jehofah, Oluwa wa, ati idajọ rẹ̀, ati ilana rẹ̀; Ati pe awa kì yio fi awọn ọmọbinrin wa fun awọn enia ilẹ na, bẹ̃li awa kì yio fẹ ọmọbinrin wọn fun awọn ọmọ wa. Bi awọn enia ilẹ na ba mu ọjà tabi ohun jijẹ wa li ọjọ isimi lati tà, awa kì yio rà a li ọwọ wọn li ọjọ isimi, tabi li ọjọ mimọ́: awa o si fi ọdun keje silẹ, ati ifi-agbara-gba gbèse. Awa si ṣe ilàna fun ara wa pe, ki olukuluku ma san idamẹta ṣekeli li ọdọdun fun iṣẹ ile Ọlọrun wa. Nitori àkara ifihàn, ati nitori ẹbọ ohun jijẹ igbagbogbo, ati nitori ẹbọ sisun igbagbogbo, ti ọjọ isimi, ti oṣù titun, ti àse ti a yàn, ati nitori ohun mimọ́, ati nitori ẹbọ ẹ̀ṣẹ lati ṣe ètutu fun Israeli, ati fun gbogbo iṣẹ ile Ọlọrun wa. Awa si dìbo larin awọn alufa awọn ọmọ Lefi, ati awọn enia, fun ọrẹ igi, lati mu u wá si ile Ọlọrun wa, gẹgẹ bi idile awọn baba wa li akoko ti a yàn li ọdọdun, lati fi daná li ori pẹpẹ Oluwa Ọlọrun wa, gẹgẹ bi a ti kọ ọ ninu ofin. Ati lati mu akọso ilẹ wa wá, ati gbogbo akọso eso igi gbogbo, li ọdọdun si ile Oluwa wa: Pẹlu akọbi awọn ọmọ wa ọkunrin, ati ti ohun ọ̀sin wa, gẹgẹ bi ati kọ ninu ofin, akọbi awọn ẹran-nla wa, ati ti agutan wa, lati mu wọn wá si ile Ọlọrun wa, fun awọn alufa ti nṣiṣẹ ni ile Ọlọrun wa. Ki awa si mu akọso iyẹfun pipò wa wá, ati ọrẹ wa, ati eso oniruru igi wa, ti ọti-waini ati ti ororo fun awọn alufa, si iyẹwu ile Ọlọrun wa, ati idamẹwa ilẹ wa fun awọn ọmọ Lefi, ki awọn ọmọ Lefi ki o le ni idamẹwa ninu gbogbo ilu arọko wa. Alufa ọmọ Aaroni yio si wà pẹlu awọn ọmọ Lefi, nigbati awọn ọmọ Lefi yio gba idamẹwa: awọn ọmọ Lefi yio si mu idamẹwa ti idamẹwa na wá si ile Ọlọrun wa, sinu iyẹwu, sinu ile iṣura. Nitori awọn ọmọ Israeli ati awọn ọmọ Lefi ni yio mu ọrẹ ọkà wá, ti ọti-waini titun, ati ororo, sinu iyẹwu, nibiti ohun èlo ibi mimọ́ gbe wà, ati awọn alufa ti nṣiṣẹ, ati awọn adèna, ati awọn akọrin: awa kì yio si kọ̀ ile Ọlọrun wa silẹ.

Neh 10:1-39 Yoruba Bible (YCE)

Àwọn tí wọ́n fi ọwọ́ sí ìwé náà tí wọ́n sì fi èdìdì dì í nìwọ̀nyí: Nehemaya, gomina, ọmọ Hakalaya, ati Sedekaya. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ alufaa wọnyi: Seraya, Asaraya, ati Jeremaya, Paṣuri, Amaraya, ati Malikija, Hatuṣi, Ṣebanaya, ati Maluki, Harimu, Meremoti, ati Ọbadaya, Daniẹli, Ginetoni, ati Baruku, Meṣulamu, Abija, ati Mijamini, Maasaya, Biligai, Ṣemaaya. Àwọn ni alufaa. Lẹ́yìn náà àwọn ọmọ Lefi wọnyi: Jeṣua ọmọ Asanaya, Binui ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Henadadi, ati Kadimieli, ati àwọn arakunrin wọn: Ṣebanaya ati Hodaya, Kelita, Pelaaya, ati Hanani, Mika, Rehobu, ati Haṣabaya, Sakuri, Ṣerebaya, ati Ṣebanaya, Hodaya, Bani, ati Beninu. Àwọn ìjòyè wọn tí wọ́n fọwọ́ sí ìwé náà ni: Paroṣi, Pahati Moabu, Elamu, Satu, ati Bani, Bunni, Asigadi, ati Bebai, Adonija, Bigifai, ati Adini, Ateri, Hesekaya ati Aṣuri, Hodaya, Haṣumu, ati Besai, Harifi, Anatoti, ati Nebai, Magipiaṣi, Meṣulamu, ati Hesiri, Meṣesabeli, Sadoku, ati Jadua, Pelataya, Hanani, ati Anaaya, Hoṣea, Hananaya, ati Haṣubu, Haloheṣi, Pileha, ati Ṣobeki, Rehumu, Haṣabina, ati Maaseaya, Ahija, Hanani, ati Anani, Maluki, Harimu, ati Baana. Àwọn eniyan yòókù, àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, àwọn aṣọ́nà, àwọn akọrin, àwọn iranṣẹ tẹmpili ati àwọn tí wọ́n ti ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí òfin Ọlọrun, àwọn iyawo wọn, àwọn ọmọ wọn ọkunrin, àwọn ọmọ wọn obinrin, gbogbo àwọn tí wọ́n gbọ́njú mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀, wọ́n parapọ̀ pẹlu àwọn arakunrin wọn ati àwọn ọlọ́lá wọn; wọ́n gégùn-ún, wọ́n sì búra pé àwọn ó máa pa òfin Ọlọrun mọ́, àwọn óo sì máa tẹ̀lé e, bí Mose iranṣẹ rẹ̀ ti fún wọn. Wọ́n óo máa ṣe gbogbo ohun tí OLUWA tíí ṣe Oluwa wọn paláṣẹ, wọn ó sì máa tẹ̀lé ìlànà ati òfin rẹ̀. A kò ní fi àwọn ọmọ wa obinrin fún àwọn ọmọ àwọn àlejò tí ń gbé ilẹ̀ wa, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní fẹ́ àwọn ọmọbinrin wọn fún àwọn ọmọ wa. Bí wọn bá sì kó ọjà tabi oúnjẹ wá tà ní ọjọ́ ìsinmi, a kò ní rà á lọ́wọ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi tabi ní ọjọ́ mímọ́ kankan. A óo sì yọ̀ǹda gbogbo èso ọdún keje keje, ati gbogbo gbèsè tí eniyan bá jẹ wá. A óo sì tún fẹnu kò sí ati máa dá ìdámẹ́ta ṣekeli wá fún iṣẹ́ ilé Ọlọrun wa lọdọọdun. A óo máa pèsè burẹdi ìfihàn ati ẹbọ ohun jíjẹ ìgbà gbogbo, ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, ẹbọ ọjọ́ ìsinmi, ati ti oṣù tuntun fún àwọn àsè tí wọ́n ti là sílẹ̀, ati fún gbogbo ohun mímọ́, fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ láti mú ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli kúrò, ati fún gbogbo iṣẹ́ ilé Ọlọrun wa. A ti dìbò láàrin àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi ati àwọn eniyan, bí wọn yóo ṣe máa ru igi wá sí ilé Ọlọrun wa, ní oníléjilé, ní ìdílé ìdílé, ní àwọn àkókò tí a yàn lọdọọdun, tí wọn yóo fi máa rúbọ lórí pẹpẹ OLUWA Ọlọrun wa, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin. A ti gbà á bí ojúṣe wa pé àkọ́so èso ilẹ̀ wa ati àkọ́so gbogbo èso igi wa lọdọọdun, ni a óo máa gbé wá sí ilé OLUWA. A óo máa mú àwọn àkọ́bí ọmọ wa, ati ti àwọn mààlúù wa lọ sí ilé Ọlọrun wa, fún àwọn alufaa tí wọn ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni àkọ́já ewébẹ̀ wa, ati àkọ́bí àwọn ẹran ọ̀sìn wa. Bẹ́ẹ̀ náà ni ìyẹ̀fun tí a kọ́kọ́ kù, ati ọrẹ wa, èso gbogbo igi, ọtí waini, ati òróró. A óo máa kó wọn tọ àwọn alufaa lọ sí gbọ̀ngàn ilé Ọlọrun wa. A óo sì máa mú ìdámẹ́wàá èso ilẹ̀ wa lọ fún àwọn ọmọ Lefi, nítorí pé àwọn ọmọ Lefi ni wọ́n máa ń gba ìdámẹ́wàá káàkiri gbogbo ilẹ̀ wa. Àwọn alufaa, ọmọ Aaroni yóo wà pẹlu àwọn ọmọ Lefi nígbà tí àwọn ọmọ Lefi bá ń gba ìdámẹ́wàá, àwọn ọmọ Lefi yóo yọ ìdámẹ́wàá gbogbo ìdámẹ́wàá tí wọ́n bá gbà lọ sí ilé Ọlọrun wa. Wọn óo kó o sinu gbọ̀ngàn ninu ilé ìpa-nǹkan-mọ́-sí. Àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn ọmọ Lefi yóo dá oúnjẹ, waini ati òróró jọ sinu àwọn gbọ̀ngàn, níbi tí àwọn ohun èlò tí a ti yà sí mímọ́ fún lílò ní ilé Ọlọrun wa, pẹlu àwọn alufaa tí wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ati àwọn olùṣọ́ tẹmpili, ati àwọn akọrin. A kò ní fi ọ̀rọ̀ ilé Ọlọrun wa falẹ̀.

Neh 10:1-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Àwọn tí ó fi èdìdì dì í ni: Nehemiah baálẹ̀, ọmọ Hakaliah. Sedekiah Seraiah, Asariah, Jeremiah, Paṣuri, Amariah, Malkiah, Hattusi, Ṣebaniah, Malluki, Harimu, Meremoti, Ọbadiah, Daniẹli, Ginetoni, Baruku, Meṣullamu, Abijah, Mijamini, Maasiah, Bilgai àti Ṣemaiah. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn àlùfáà. Àwọn ọmọ Lefi: Jeṣua ọmọ Asaniah, Binnui ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Henadadi, Kadmieli, àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn: Ṣebaniah, Hodiah, Kelita, Pelaiah, Hanani, Mika, Rehobu, Haṣabiah, Sakkuri, Ṣerebiah, Ṣebaniah, Hodiah, Bani àti Beninu. Àwọn olórí àwọn ènìyàn: Paroṣi, Pahati-Moabu, Elamu, Sattu, Bani, Bunni, Asgadi, Bebai. Adonijah, Bigfai, Adini, Ateri, Hesekiah, Assuri, Hodiah, Haṣumu, Besai, Harifu, Anatoti, Nebai, Magpiaṣi, Meṣullamu, Hesiri Meṣesabeli, Sadoku, Jaddua Pelatiah, Hanani, Anaiah, Hosea, Hananiah, Haṣubu, Halloheṣi, Pileha, Ṣobeki, Rehumu, Haṣabna, Maaseiah, Ahijah, Hanani, Anani, Malluki, Harimu, àti Baanah. “Àwọn ènìyàn tókù—àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi, àwọn aṣọ́nà, àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti gbogbo àwọn tí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn àjèjì nítorí òfin Ọlọ́run, papọ̀ pẹ̀lú ìyàwó wọn, gbogbo ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn, tí òye yé gbogbo wọn fi ara mọ́ àwọn arákùnrin wọn, àwọn ọlọ́lá, wọ́n sì fi ègún àti ìbúra dé ara wọn láti máa tẹ̀lé òfin Ọlọ́run tí a fi fún wọn ní ipasẹ̀ Mose ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti láti pa gbogbo àṣẹ, ìlànà àti òfin OLúWA, wa mọ́ dáradára. “A ti ṣe ìlérí pé, a kò ní fi àwọn ọmọbìnrin wa fún àwọn tí wọ́n wà ní àyíká wa bí ìyàwó, tàbí fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin wa. “Nígbà tí àwọn ènìyàn àdúgbò bá mú ọjà tàbí oúnjẹ wá ní ọjọ́ ìsinmi láti tà, àwa kò ní rà á ní ọwọ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi tàbí ní ọjọ́ mímọ́ kankan. Ní gbogbo ọdún keje àwa kò ní ro ilẹ̀ náà, a ó sì pa gbogbo àwọn gbèsè rẹ́. “Àwa gbà ojúṣe láti máa pa àṣẹ mọ́ pé a ó máa san ìdámẹ́ta ṣékélì ní ọdọọdún fún iṣẹ́ ilé Ọlọ́run wa: Nítorí oúnjẹ tí ó wà lórí tábìlì; nítorí ọrẹ ohun jíjẹ àti ẹbọ sísun ìgbà gbogbo; nítorí ọrẹ ọjọ́ ìsinmi, ti àyajọ́ oṣù tuntun àti àjọ̀dún tí a yàn; nítorí ọrẹ mímọ́; nítorí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún Israẹli; àti fún gbogbo iṣẹ́ ilé Ọlọ́run wa. “Àwa, àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi àti àwọn ènìyàn náà ti dìbò láti pinnu ìgbà tí olúkúlùkù àwọn ìdílé yóò mú ọrẹ igi wá láti sun lọ́ríi pẹpẹ OLúWA Ọlọ́run wa sí ilé Ọlọ́run wa, ní àkókò tí a yàn ní ọdọọdún. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sínú ìwé òfin. “Àwa tún gbà ojúṣe láti mú àkọ́so àwọn èso wa wá àti gbogbo èso igi wá ní ilé OLúWA. “Gẹ́gẹ́ bí a sì ti kọ ọ́ sínú ìwé òfin, àwa yóò mú àkọ́bí àwọn ọmọkùnrin wa, ti ohun ọ̀sìn wa, ti àwọn abo màlúù àti ti àwọn àgùntàn wa, wá sí ilé Ọlọ́run wa, fún àwọn àlùfáà tí ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀. “Síwájú sí i, àwa yóò mú àkọ́so oúnjẹ ilẹ̀ wa ti ọrẹ oúnjẹ, ti gbogbo èso àwọn igi àti ti wáìnì tuntun wa àti ti òróró wá sí yàrá ìkó-nǹkan-pamọ́-sí ilé Ọlọ́run wa àti fún àwọn àlùfáà. Àwa yóò sì mú ìdámẹ́wàá ohun ọ̀gbìn wá fún àwọn ọmọ Lefi, nítorí àwọn ọmọ Lefi ni ó ń gba ìdámẹ́wàá ní gbogbo àwọn ìlú tí a ti ń ṣiṣẹ́. Àlùfáà tí o ti ìdílé Aaroni wá ni yóò wá pẹ̀lú àwọn ọmọ Lefi nígbà tí wọ́n bá ń gba ìdámẹ́wàá, àwọn ọmọ Lefi yóò sì mú ìdámẹ́wàá ti ìdámẹ́wàá náà wá sí ilé Ọlọ́run, sí yàrá ìkó-nǹkan-pamọ́-sí inú ilé ìṣúra. Àwọn ènìyàn Israẹli, àti àwọn ọmọ Lefi gbọdọ̀ mú ọrẹ oúnjẹ, wáìnì tuntun àti òróró wá sí yàrá ìkó-nǹkan-pamọ́-sí níbi tí a pa ohun èlò ibi mímọ́ mọ́ sí àti ibi tí àwọn àlùfáà tí ń ṣe ìránṣẹ́ lọ́wọ́, àwọn aṣọ́nà àti àwọn akọrin máa ń dúró sí. “Àwa kì yóò gbàgbé tàbí ṣe àìbìkítà nípa ilé Ọlọ́run wa.”