Mak 15:1-23

Mak 15:1-23 YBCV

ATI lojukanna li owurọ, awọn olori alufa jọ gbìmọ pẹlu awọn alàgba, ati awọn akọwe, ati gbogbo ajọ ìgbimọ, nwọn si dè Jesu, nwọn si mu u lọ, nwọn si fi i le Pilatu lọwọ. Pilatu si bi i lẽre, wipe Iwọ ha li Ọba awọn Ju? O si dahùn wi fun u pe, Iwọ wi i. Awọn olori alufa si fi i sùn li ohun pipọ: ṣugbọn on ko dahùn kan. Pilatu si tún bi i lẽre, wipe, Iwọ ko dahùn ohun kan? wò ọ̀pọ ohun ti nwọn njẹri si ọ. Ṣugbọn Jesu ko da a ni gbolohùn kan: tobẹ̃ ti ẹnu fi yà Pilatu. Njẹ nigba ajọ na, on a ma dá ondè kan silẹ fun wọn, ẹnikẹni ti nwọn ba bere. Ẹnikan si wà ti a npè ni Barabba, ẹniti a sọ sinu tubu pẹlu awọn ti o ṣọ̀tẹ pẹlu rẹ̀, awọn ẹniti o si pania pẹlu ninu ìṣọtẹ na. Ijọ enia si bẹ̀rẹ si ikigbe soke li ohùn rara, nwọn nfẹ ki o ṣe bi on ti ima ṣe fun wọn ri. Ṣugbọn Pilatu da wọn lohùn, wipe, Ẹnyin nfẹ ki emi ki o da Ọba awọn Ju silẹ fun nyin? On sá ti mọ̀ pe nitori ilara ni awọn olori alufa ṣe fi i le on lọwọ. Ṣugbọn awọn olori alufa rú awọn enia soke pe, ki o kuku dá Barabba silẹ fun wọn. Pilatu si dahùn o tún wi fun wọn pe, Kili ẹnyin ha nfẹ ki emi ki o ṣe si ẹniti ẹnyin npè li Ọba awọn Ju? Nwọn si tún kigbe soke, wipe, Kàn a mọ agbelebu. Nigbana ni Pilatu si bi wọn lẽre, wipe, Eṣe? buburu kili o ṣe? Nwọn si kigbe soke gidigidi, wipe, Kàn a mọ agbelebu. Pilatu si nfẹ se eyi ti o wù awọn enia, o da Barabba silẹ fun wọn. Nigbati o si nà Jesu tan, o fà a le wọn lọwọ lati kàn a mọ agbelebu. Awọn ọmọ-ogun si fà a jade lọ sinu gbọ̀ngan, ti a npè ni Pretorioni; nwọn si pè gbogbo ẹgbẹ awọn ọmọ-ogun jọ. Nwọn si fi aṣọ elesè àluko wọ̀ ọ, nwọn hun ade ẹgún, nwọn si fi dé e li ori; Nwọn si bẹ̀rẹ si ikí i, wipe, Kabiyesi, Ọba awọn Ju! Nwọn si fi ọpá iye lù u lori, nwọn si tutọ́ si i lara, nwọn si kunlẹ niwaju rẹ̀, nwọn si foribalẹ fun u. Nigbati nwọn si fi i ṣẹ̀sin tan, nwọn si bọ́ aṣọ elesè àluko na kuro lara rẹ̀, nwọn si fi aṣọ rẹ̀ wọ̀ ọ, nwọn si mu u jade lọ lati kàn a mọ agbelebu. Nwọn si fi agbara mu ọkunrin kan, lati rù agbelebu rẹ̀, Simoni ara Kirene, ẹniti nkọja lọ, ti nti igberiko bọ̀, baba Aleksanderu ati Rufu. Nwọn si mu u wá si ibi ti a npè ni Golgota, itumọ eyi ti ijẹ́, Ibi agbari. Nwọn si fi ọti-waini ti a dàpọ mọ ojia fun u lati mu: ṣugbọn on kò gbà a.