Mak 15:1-23

Mak 15:1-23 Bibeli Mimọ (YBCV)

ATI lojukanna li owurọ, awọn olori alufa jọ gbìmọ pẹlu awọn alàgba, ati awọn akọwe, ati gbogbo ajọ ìgbimọ, nwọn si dè Jesu, nwọn si mu u lọ, nwọn si fi i le Pilatu lọwọ. Pilatu si bi i lẽre, wipe Iwọ ha li Ọba awọn Ju? O si dahùn wi fun u pe, Iwọ wi i. Awọn olori alufa si fi i sùn li ohun pipọ: ṣugbọn on ko dahùn kan. Pilatu si tún bi i lẽre, wipe, Iwọ ko dahùn ohun kan? wò ọ̀pọ ohun ti nwọn njẹri si ọ. Ṣugbọn Jesu ko da a ni gbolohùn kan: tobẹ̃ ti ẹnu fi yà Pilatu. Njẹ nigba ajọ na, on a ma dá ondè kan silẹ fun wọn, ẹnikẹni ti nwọn ba bere. Ẹnikan si wà ti a npè ni Barabba, ẹniti a sọ sinu tubu pẹlu awọn ti o ṣọ̀tẹ pẹlu rẹ̀, awọn ẹniti o si pania pẹlu ninu ìṣọtẹ na. Ijọ enia si bẹ̀rẹ si ikigbe soke li ohùn rara, nwọn nfẹ ki o ṣe bi on ti ima ṣe fun wọn ri. Ṣugbọn Pilatu da wọn lohùn, wipe, Ẹnyin nfẹ ki emi ki o da Ọba awọn Ju silẹ fun nyin? On sá ti mọ̀ pe nitori ilara ni awọn olori alufa ṣe fi i le on lọwọ. Ṣugbọn awọn olori alufa rú awọn enia soke pe, ki o kuku dá Barabba silẹ fun wọn. Pilatu si dahùn o tún wi fun wọn pe, Kili ẹnyin ha nfẹ ki emi ki o ṣe si ẹniti ẹnyin npè li Ọba awọn Ju? Nwọn si tún kigbe soke, wipe, Kàn a mọ agbelebu. Nigbana ni Pilatu si bi wọn lẽre, wipe, Eṣe? buburu kili o ṣe? Nwọn si kigbe soke gidigidi, wipe, Kàn a mọ agbelebu. Pilatu si nfẹ se eyi ti o wù awọn enia, o da Barabba silẹ fun wọn. Nigbati o si nà Jesu tan, o fà a le wọn lọwọ lati kàn a mọ agbelebu. Awọn ọmọ-ogun si fà a jade lọ sinu gbọ̀ngan, ti a npè ni Pretorioni; nwọn si pè gbogbo ẹgbẹ awọn ọmọ-ogun jọ. Nwọn si fi aṣọ elesè àluko wọ̀ ọ, nwọn hun ade ẹgún, nwọn si fi dé e li ori; Nwọn si bẹ̀rẹ si ikí i, wipe, Kabiyesi, Ọba awọn Ju! Nwọn si fi ọpá iye lù u lori, nwọn si tutọ́ si i lara, nwọn si kunlẹ niwaju rẹ̀, nwọn si foribalẹ fun u. Nigbati nwọn si fi i ṣẹ̀sin tan, nwọn si bọ́ aṣọ elesè àluko na kuro lara rẹ̀, nwọn si fi aṣọ rẹ̀ wọ̀ ọ, nwọn si mu u jade lọ lati kàn a mọ agbelebu. Nwọn si fi agbara mu ọkunrin kan, lati rù agbelebu rẹ̀, Simoni ara Kirene, ẹniti nkọja lọ, ti nti igberiko bọ̀, baba Aleksanderu ati Rufu. Nwọn si mu u wá si ibi ti a npè ni Golgota, itumọ eyi ti ijẹ́, Ibi agbari. Nwọn si fi ọti-waini ti a dàpọ mọ ojia fun u lati mu: ṣugbọn on kò gbà a.

Mak 15:1-23 Yoruba Bible (YCE)

Gbàrà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn olórí alufaa pẹlu àwọn àgbà ati àwọn amòfin ati gbogbo Ìgbìmọ̀ yòókù forí-korí, wọ́n de Jesu, wọ́n bá fà á lọ láti fi lé Pilatu lọ́wọ́ fún ìdájọ́. Pilatu bi Jesu pé, “Ṣé ìwọ ni ọba àwọn Juu?” Jesu dá a lóhùn pé, “O ti fi ẹnu ara rẹ sọ ọ́.” Àwọn olórí alufaa ń fi ẹ̀sùn pupọ kàn án. Pilatu bá tún bi í pé, “O kò sì fèsì rárá? Ìwọ kò gbọ́ bí wọ́n ti ń fi oríṣìíríṣìí ẹ̀sùn kàn ọ́ ni?” Ṣugbọn Jesu kò tún dá a lóhùn rárá mọ́, èyí mú kí ẹnu ya Pilatu. Ní ọdọọdún, ni àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá, Pilatu a máa dá ẹlẹ́wọ̀n kan tí wọ́n bá bẹ̀bẹ̀ fún sílẹ̀. Ẹnìkan wà tí ó ń jẹ́ Baraba, tí ó wà ninu ẹ̀wọ̀n pẹlu àwọn ọlọ̀tẹ̀ kan tí wọ́n pa eniyan ní àkókò ọ̀tẹ̀. Àwọn eniyan bá gòkè tọ Pilatu lọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀ ẹ́ pé kí ó ṣe bí ó ti máa ń ṣe fún wọn. Pilatu wá bi wọ́n pé, “Ẹ fẹ́ kí n dá ọba àwọn Juu sílẹ̀ fun yín bí?” Nítorí ó mọ̀ pé àwọn olórí alufaa ń jowú Jesu, wọ́n sì ń ṣe kèéta rẹ̀, ni wọ́n ṣe fà á wá siwaju òun. Ṣugbọn àwọn olórí alufaa rú àwọn eniyan sókè pé Baraba ni kí ó kúkú dá sílẹ̀ fún wọn. Pilatu tún bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ fẹ́ kí n ṣe sí ẹni tí ẹ̀ ń pè ní ọba àwọn Juu?” Nígbà náà ni gbogbo wọn kígbe pé, “Kàn án mọ́ agbelebu!” Ṣugbọn Pilatu bi wọ́n pé, “Nítorí kí ni? Nǹkan burúkú wo ni ó ṣe?” Ṣugbọn wọ́n sá tún kígbe pé, “Kàn án mọ́ agbelebu!” Pilatu bá dá Baraba sílẹ̀ fún wọn kí ó lè baà tẹ́ wọn lọ́rùn. Lẹ́yìn tí ó ti ní kí wọ́n na Jesu tán, ó bá fà á fún wọn láti kàn mọ́ agbelebu. Àwọn ọmọ-ogun bá mú un lọ sí inú agbo-ilé tí ààfin gomina wà. Wọ́n pe gbogbo àwọn ọmọ-ogun yòókù, wọ́n wọ̀ ọ́ ní aṣọ àlàárì, wọ́n wá fi ẹ̀gún hun adé, wọ́n fi dé e lórí. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí kí i pé, “Kabiyesi! Ọba àwọn Juu!” Wọ́n ń lù ú ní igi lórí, wọ́n ń tutọ́ sí i lára, wọ́n wá ń kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n ń júbà yẹ̀yẹ́. Nígbà tí wọ́n ti fi ṣe ẹlẹ́yà tán, wọ́n bọ́ aṣọ àlàárì kúrò ní ara rẹ̀, wọ́n fi aṣọ tirẹ̀ wọ̀ ọ́, wọ́n bá fà á jáde láti lọ kàn án mọ́ agbelebu. Bí ọkunrin kan tí ń jẹ́ Simoni, ará Kirene, baba Alẹkisanderu ati Rufọsi, ti ń ti ọ̀nà ìgbèríko bọ̀, bí ó ti ń kọjá lọ, wọ́n fi tipátipá mú un láti gbé agbelebu Jesu. Wọ́n wá mú Jesu lọ sí ibìkan tí à ń pè ní Gọlgọta (ìtumọ̀ èyí tíí ṣe “Ibi Agbárí”). Wọ́n fún un ní ọtí tí wọ́n ti po òjíá mọ́, ṣugbọn kò gbà á.

Mak 15:1-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní kùtùkùtù òwúrọ̀, àwọn olórí àlùfáà, àwọn àgbàgbà, àwọn olùkọ́ òfin àti gbogbo àjọ ìgbìmọ̀ fi ẹnu kò lórí ohun tí wọn yóò ṣe. Wọ́n sì de Jesu, wọ́n mú un lọ, wọ́n sì fi lé Pilatu lọ́wọ́. Pilatu sì bi í léèrè, ó ni, “Ṣe ìwọ ni ọba àwọn Júù?” Jesu sì dáhùn pé, “gẹ́gẹ́ bi ìwọ ti wí náà ni.” Àwọn olórí àlùfáà fi ẹ̀sùn ohun púpọ̀ kàn án. Pilatu sì tún bi í léèrè pé, “Ṣe ìwọ kò dáhùn ni? Wo gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn ọ.” Ṣùgbọ́n Jesu kò dalóhùn síbẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ ti ẹnu fi ya Pilatu. Ní báyìí, nígbà àjọ, gẹ́gẹ́ bí àṣà, òun a máa dá òǹdè kan sílẹ̀ fún wọn, ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá béèrè fún. Ọkùnrin kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Baraba. Wọ́n ti ju òun àti àwọn ọlọ̀tẹ̀ ẹgbẹ́ rẹ̀ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n, nítorí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba, wọ́n sì pa ènìyàn nínú ìdìtẹ̀ wọn. Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì lọ bá Pilatu, wọ́n ní kí ó ṣe bí ó ti máa ń ṣe fún wọn ní ọdọọdún. Pilatu béèrè lọ́wọ́ wọn wí pé, “Ṣe ẹ̀yin ń fẹ́ kí èmi dá ọba àwọn Júù sílẹ̀ fún yin?” Òun mọ̀ pé nítorí ìlara ni àwọn olórí àlùfáà ṣe fà Jesu lé òun lọ́wọ́. Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà ru ọ̀pọ̀ ènìyàn sókè pé, kí ó kúkú dá Baraba sílẹ̀ fún wọn. Pilatu sì tún béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni ẹ̀yin ń fẹ́ kí èmi kí ó ṣe pẹ̀lú ẹni ti ẹ̀yin n pè ní ọba àwọn Júù?” Wọ́n sì tún kígbe sókè pé, “Kàn án mọ àgbélébùú!” Nígbà náà ni Pilatu bi wọn léèrè pé, “Èéṣe? Búburú kí ni ó ṣe?” Wọ́n sì kígbe sókè gidigidi wí pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú!” Pilatu sì ń fẹ́ ṣe èyí tí ó wu àwọn ènìyàn, ó dá Baraba sílẹ̀ fún wọn. Nígbà tí ó sì na Jesu tan o fà á lé wọn lọ́wọ́ láti kàn an mọ́ àgbélébùú. Àwọn ọmọ-ogun sì fà á jáde lọ sínú ààfin (tí a ń pè ní Praetoriumus), wọ́n sì pe gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ọmọ-ogun jọ. Wọn sì fi aṣọ aláwọ̀ àlùkò wọ̀ ọ́, wọ́n hun adé ẹ̀gún, wọ́n sì fi dé e ní orí. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí i kí ì, wí pé Kábíyèsí, ọba àwọn Júù Wọ́n sì fi ọ̀pá lù ú lórí, wọ́n sì tutọ́ sí i lára, wọ́n sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún un. Nígbà tí wọ́n sì fi ṣẹ̀sín tan, wọ́n sì bọ aṣọ elése àlùkò náà kúrò lára rẹ̀, wọ́n sì fi aṣọ rẹ̀ wọ̀ ọ́, wọ́n sì mú un jáde lọ láti kàn án mọ́ àgbélébùú. Wọ́n rí ọkùnrin kan tí ń kọjá lọ. Simoni ará Kirene. Òun ni baba Aleksanderu àti Rufusi. Wọ́n sì mú un ní tipátipá, pé kí ó rú àgbélébùú Jesu. Wọ́n sì mú Jesu wá sí Gọlgọta, (èyí tí ìtumọ̀ rẹ̀ ń jẹ́ Ibi Agbárí) Wọ́n sì fi (myrri) wáìnì tí a dàpọ̀ mọ́ òjìá fún un mu, ṣùgbọ́n òun kò gbà á.