Mak 15

15
A Mú Jesu Lọ Siwaju Pilatu
(Mat 27:1-2,11-14; Luk 23:1-5; Joh 18:28-38)
1ATI lojukanna li owurọ, awọn olori alufa jọ gbìmọ pẹlu awọn alàgba, ati awọn akọwe, ati gbogbo ajọ ìgbimọ, nwọn si dè Jesu, nwọn si mu u lọ, nwọn si fi i le Pilatu lọwọ.
2Pilatu si bi i lẽre, wipe Iwọ ha li Ọba awọn Ju? O si dahùn wi fun u pe, Iwọ wi i.
3Awọn olori alufa si fi i sùn li ohun pipọ: ṣugbọn on ko dahùn kan.
4Pilatu si tún bi i lẽre, wipe, Iwọ ko dahùn ohun kan? wò ọ̀pọ ohun ti nwọn njẹri si ọ.
5Ṣugbọn Jesu ko da a ni gbolohùn kan: tobẹ̃ ti ẹnu fi yà Pilatu.
6Njẹ nigba ajọ na, on a ma dá ondè kan silẹ fun wọn, ẹnikẹni ti nwọn ba bere.
7Ẹnikan si wà ti a npè ni Barabba, ẹniti a sọ sinu tubu pẹlu awọn ti o ṣọ̀tẹ pẹlu rẹ̀, awọn ẹniti o si pania pẹlu ninu ìṣọtẹ na.
8Ijọ enia si bẹ̀rẹ si ikigbe soke li ohùn rara, nwọn nfẹ ki o ṣe bi on ti ima ṣe fun wọn ri.
9Ṣugbọn Pilatu da wọn lohùn, wipe, Ẹnyin nfẹ ki emi ki o da Ọba awọn Ju silẹ fun nyin?
10On sá ti mọ̀ pe nitori ilara ni awọn olori alufa ṣe fi i le on lọwọ.
11Ṣugbọn awọn olori alufa rú awọn enia soke pe, ki o kuku dá Barabba silẹ fun wọn.
12Pilatu si dahùn o tún wi fun wọn pe, Kili ẹnyin ha nfẹ ki emi ki o ṣe si ẹniti ẹnyin npè li Ọba awọn Ju?
13Nwọn si tún kigbe soke, wipe, Kàn a mọ agbelebu.
14Nigbana ni Pilatu si bi wọn lẽre, wipe, Eṣe? buburu kili o ṣe? Nwọn si kigbe soke gidigidi, wipe, Kàn a mọ agbelebu.
15Pilatu si nfẹ se eyi ti o wù awọn enia, o da Barabba silẹ fun wọn. Nigbati o si nà Jesu tan, o fà a le wọn lọwọ lati kàn a mọ agbelebu.
Àwọn Ọmọ-ogun Fi Jesu Ṣe Ẹlẹ́yà
(Mat 27:27-31; Joh 19:2-3)
16Awọn ọmọ-ogun si fà a jade lọ sinu gbọ̀ngan, ti a npè ni Pretorioni; nwọn si pè gbogbo ẹgbẹ awọn ọmọ-ogun jọ.
17Nwọn si fi aṣọ elesè àluko wọ̀ ọ, nwọn hun ade ẹgún, nwọn si fi dé e li ori;
18Nwọn si bẹ̀rẹ si ikí i, wipe, Kabiyesi, Ọba awọn Ju!
19Nwọn si fi ọpá iye lù u lori, nwọn si tutọ́ si i lara, nwọn si kunlẹ niwaju rẹ̀, nwọn si foribalẹ fun u.
20Nigbati nwọn si fi i ṣẹ̀sin tan, nwọn si bọ́ aṣọ elesè àluko na kuro lara rẹ̀, nwọn si fi aṣọ rẹ̀ wọ̀ ọ, nwọn si mu u jade lọ lati kàn a mọ agbelebu.
A Kan Jesu Mọ́ Agbelebu
(Mat 27:32-44; Luk 23:26-43; Joh 19:17-27)
21Nwọn si fi agbara mu ọkunrin kan, lati rù agbelebu rẹ̀, Simoni ara Kirene, ẹniti nkọja lọ, ti nti igberiko bọ̀, baba Aleksanderu ati Rufu.
22Nwọn si mu u wá si ibi ti a npè ni Golgota, itumọ eyi ti ijẹ́, Ibi agbari.
23Nwọn si fi ọti-waini ti a dàpọ mọ ojia fun u lati mu: ṣugbọn on kò gbà a.
24Nigbati nwọn si kàn a mọ agbelebu tan, nwọn si pín aṣọ rẹ̀, nwọn si ṣẹ gège lori wọn, eyi ti olukuluku iba mú.
25Ni wakati kẹta ọjọ, on ni nwọn kàn a mọ agbelebu.
26A si kọwe akọle ọ̀ran ifisùn rẹ̀ si igberi rẹ̀ ỌBA AWỌN JU.
27Nwọn si kàn awọn olè meji mọ agbelebu pẹlu rẹ̀; ọkan li ọwọ́ ọtún, ati ekeji li ọwọ́ òsi rẹ̀.
28Iwe-mimọ si ṣẹ, ti o wipe, A si kà a mọ awọn arufin.
29Awọn ti nrekọja lọ si nfi i ṣe ẹlẹyà, nwọn si nmì ori wọn, wipe, A, Iwọ ti o wó tẹmpili, ti o si kọ́ ọ ni ijọ mẹta,
30Gbà ara rẹ, ki o si sọkalẹ lati ori agbelebu wá.
31Gẹgẹ bẹ̃li awọn olori alufa pẹlu, nwọn nsin i jẹ ninu ara wọn pẹlu awọn akọwe, wipe, O gbà awọn ẹlomiran là; kò le gbà ara rẹ̀.
32Jẹ ki Kristi, Ọba Israeli, sọkalẹ lati ori agbelebu wá nisisiyi, ki awa ki o le ri i, ki a si le gbagbọ́. Awọn ti a kàn mọ agbelebu pẹlu rẹ̀ si nkẹgan rẹ̀.
Ikú Jesu
(Mat 27:45-56; Luk 23:44-49; Joh 19:28-30)
33Nigbati o di wakati kẹfa, òkunkun si ṣú bò gbogbo ilẹ titi o fi di wakati kẹsan.
34Ni wakati kẹsan ni Jesu si kigbe soke li ohùn rara, wipe, Eloi, Eloi, lama sabaktani? itumọ eyi ti ijẹ, Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, ẽṣe ti iwọ fi kọ̀ mi silẹ?
35Nigbati awọn kan ninu awọn ti o duro nibẹ̀ gbọ́ eyi, nwọn wipe, Wò o, o npè Elijah.
36Ẹnikan si sare, o fi sponge bọ ọti kikan, o fi le ori ọpá iyè, o fifun u mu, wipe, Ẹ jọwọ rẹ̀ si; ẹ jẹ ki a ma wò bi Elijah yio wá gbé e sọkalẹ.
37Jesu si kigbe soke li ohùn rara, o jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ.
38Aṣọ ikele tẹmpili si ya si meji lati oke de isalẹ.
39Nigbati balogun ọrún, ti o duro niha ọdọ rẹ̀ ri ti o kigbe soke bayi, ti o si jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ, o wipe, Lõtọ Ọmọ Ọlọrun li ọkunrin yi iṣe.
40Awọn obinrin pẹlu si wà li òkere nwọn nwò: ninu awọn ẹniti Maria Magdalene wà, ati Maria iya Jakọbu kekere, ati ti Jose ati Salome;
41(Awọn ẹniti, nigbati o wà ni Galili, ti nwọn ntọ̀ ọ lẹhin, ti nwọn si nṣe iranṣẹ fun u;) ati ọ̀pọ obinrin miran pẹlu, ti o ba a goke wá si Jerusalemu.
Ìsìnkú Jesu
(Mat 27:57-61; Luk 23:50-56; Joh 19:38-42)
42Nigbati alẹ si lẹ, nitoriti iṣe ọjọ ipalẹmọ, eyini ni, ọjọ ti o ṣiwaju ọjọ isimi,
43Josefu ara Arimatea, ọlọlá ìgbimọ, ẹniti on tikalarẹ̀ pẹlu nreti ijọba Ọlọrun, o wá, o si wọle tọ̀ Pilatu lọ laifòya, o si tọrọ okú Jesu.
44Ẹnu si yà Pilatu gidigidi, bi o ti kú na: o si pè balogun ọrún, o bi i lẽre bi igba ti o ti kú ti pẹ diẹ.
45Nigbati o si mọ̀ lati ọdọ balọgun ọrún na, o si fi okú na fun Josefu.
46O si rà aṣọ ọgbọ wá, o si sọ̀ ọ kalẹ, o si fi aṣọ ọgbọ na dì i, o si tẹ́ ẹ sinu ibojì ti a gbẹ́ ninu apata, o si yi okuta kan di ẹnu-ọ̀na ibojì na.
47Ati Maria Magdalene, ati Maria iya Jose, ri ibi ti a gbé tẹ́ ẹ si.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Mak 15: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀