Ni ijọ keji, nigbati nwọn ti Betani jade, ebi si npa a:
O si ri igi ọpọtọ kan li òkere ti o li ewé, o wá, bi bọya on le ri ohun kan lori rẹ̀: nigbati o si wá si idi rẹ̀, ko ri ohun kan, bikoṣe ewé; nitori akokò eso ọpọtọ kò ti ito.
Jesu si dahùn o si wi fun u pe, Ki ẹnikẹni má jẹ eso lori rẹ mọ́ titi lai. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si gbọ́ ọ.
Nwọn si wá si Jerusalemu: Jesu si wọ̀ inu tẹmpili lọ, o bẹ̀rẹ si ilé awọn ti ntà ati awọn ti nrà ni tẹmpili jade, o si tari tabili awọn onipaṣiparọ owo danù, ati ijoko awọn ti ntà ẹiyẹle.
Kò si jẹ ki ẹnikẹni ki o gbe ohun èlo kọja larin tẹmpili.
O si nkọ́ni, o nwi fun wọn pe, A ko ti kọwe rẹ̀ pe, Ile adura fun gbogbo orilẹ-ède li a o ma pè ile mi? ṣugbọn ẹnyin ti ṣọ di ihò awọn ọlọsà.
Awọn akọwe ati awọn olori alufa si gbọ́, nwọn si nwá ọ̀na bi nwọn o ti ṣe pa a run: nitori nwọn bẹ̀ru rẹ̀, nitori ẹnu yà gbogbo ijọ enia si ẹkọ́ rẹ̀.
Nigbati alẹ ba si lẹ, a jade kuro ni ilu.
Bi nwọn si ti nkọja lọ li owurọ, nwọn ri igi ọpọtọ na gbẹ ti gbongbo ti gbongbo.
Peteru si wa iranti o wi fun u pe, Rabbi, wò bi igi ọpọtọ ti iwọ fi bú ti gbẹ.
Jesu si dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹ ni igbagbọ́ si Ọlọrun.
Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba wi fun òke yi pe, Ṣidi, ki o si bọ sinu okun; ti kò ba si ṣiyemeji li ọkàn rẹ̀, ṣugbọn ti o ba gbagbọ́ pe ohun ti on wi yio ṣẹ, yio ri bẹ̃ fun u.
Nitorina mo wi fun nyin, Ohunkohun ti ẹnyin ba tọrọ nigbati ẹ ba ngbadura, ẹ gbagbọ́ pe ẹ ti ri wọn gbà na, yio si ri bẹ̃ fun nyin.
Nigbati ẹnyin ba si duro ngbadura, ẹ darijì, bi ẹnyin ba ni ohunkohun si ẹnikẹni: ki Baba nyin ti mbẹ li ọrun ba le dari ẹṣẹ nyin jì nyin pẹlu.