Mak 11:12-25
Mak 11:12-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ni ijọ keji, nigbati nwọn ti Betani jade, ebi si npa a: O si ri igi ọpọtọ kan li òkere ti o li ewé, o wá, bi bọya on le ri ohun kan lori rẹ̀: nigbati o si wá si idi rẹ̀, ko ri ohun kan, bikoṣe ewé; nitori akokò eso ọpọtọ kò ti ito. Jesu si dahùn o si wi fun u pe, Ki ẹnikẹni má jẹ eso lori rẹ mọ́ titi lai. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si gbọ́ ọ. Nwọn si wá si Jerusalemu: Jesu si wọ̀ inu tẹmpili lọ, o bẹ̀rẹ si ilé awọn ti ntà ati awọn ti nrà ni tẹmpili jade, o si tari tabili awọn onipaṣiparọ owo danù, ati ijoko awọn ti ntà ẹiyẹle. Kò si jẹ ki ẹnikẹni ki o gbe ohun èlo kọja larin tẹmpili. O si nkọ́ni, o nwi fun wọn pe, A ko ti kọwe rẹ̀ pe, Ile adura fun gbogbo orilẹ-ède li a o ma pè ile mi? ṣugbọn ẹnyin ti ṣọ di ihò awọn ọlọsà. Awọn akọwe ati awọn olori alufa si gbọ́, nwọn si nwá ọ̀na bi nwọn o ti ṣe pa a run: nitori nwọn bẹ̀ru rẹ̀, nitori ẹnu yà gbogbo ijọ enia si ẹkọ́ rẹ̀. Nigbati alẹ ba si lẹ, a jade kuro ni ilu. Bi nwọn si ti nkọja lọ li owurọ, nwọn ri igi ọpọtọ na gbẹ ti gbongbo ti gbongbo. Peteru si wa iranti o wi fun u pe, Rabbi, wò bi igi ọpọtọ ti iwọ fi bú ti gbẹ. Jesu si dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹ ni igbagbọ́ si Ọlọrun. Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba wi fun òke yi pe, Ṣidi, ki o si bọ sinu okun; ti kò ba si ṣiyemeji li ọkàn rẹ̀, ṣugbọn ti o ba gbagbọ́ pe ohun ti on wi yio ṣẹ, yio ri bẹ̃ fun u. Nitorina mo wi fun nyin, Ohunkohun ti ẹnyin ba tọrọ nigbati ẹ ba ngbadura, ẹ gbagbọ́ pe ẹ ti ri wọn gbà na, yio si ri bẹ̃ fun nyin. Nigbati ẹnyin ba si duro ngbadura, ẹ darijì, bi ẹnyin ba ni ohunkohun si ẹnikẹni: ki Baba nyin ti mbẹ li ọrun ba le dari ẹṣẹ nyin jì nyin pẹlu.
Mak 11:12-25 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ keji, bí wọ́n ti ń jáde kúrò ní Bẹtani, ebi ń pa á. Ó rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan tí ó ní ewé lókèèrè, ó bá lọ wò ó bí yóo rí èso lórí rẹ̀. Nígbà tí ó dé ìdí rẹ̀ kò rí ohunkohun àfi ewé, nítorí kò ì tíì tó àkókò èso. Jesu wí fún igi náà pé, “Kí ẹnikẹ́ni má rí èso jẹ lórí rẹ mọ́ lae!” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbọ́. Nígbà tí wọ́n dé Jerusalẹmu, Jesu wọ àgbàlá Tẹmpili lọ, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn tí wọn ń tà ati àwọn tí wọn ń rà jáde. Ó ti tabili àwọn onípàṣípààrọ̀ owó ṣubú, ó da ìsọ̀ àwọn tí ń ta ẹyẹlé rú. Kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni gbé ohunkohun la àgbàlá Tẹmpili kọjá. Ó ń kọ́ wọn pé, “Kò ha wà ninu àkọsílẹ̀ pé, ‘Ilé adura fún gbogbo orílẹ̀-èdè ni a óo máa pe ilé mi?’ Ṣugbọn ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibi tí àwọn ọlọ́ṣà ń sápamọ́ sí!” Nígbà tí àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin gbọ́, wọ́n ń wá ọ̀nà tí wọn yóo fi pa á. Ṣugbọn wọ́n bẹ̀rù rẹ̀, nítorí ìyàlẹ́nu ni ẹ̀kọ́ rẹ̀ jẹ́ fún gbogbo eniyan. Nígbà tí ọjọ́ rọ̀ Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jáde kúrò ní ìlú. Nígbà tí ó di òwúrọ̀, bí wọ́n ti ń kọjá lọ, wọ́n rí i tí igi ọ̀pọ̀tọ́ àná ti gbẹ patapata láti orí dé gbòǹgbò. Peteru wá ranti ọ̀rọ̀ àná. Ó wí fún Jesu pé, “Olùkọ́ni, wo igi ọ̀pọ̀tọ́ tí o fi gégùn-ún, ó ti gbẹ!” Jesu dáhùn, ó wí fún wọn pé, “Ẹ ní igbagbọ ninu Ọlọrun; mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, bí ẹnikẹ́ni bá wí fún òkè yìí pé, ‘ṣídìí kúrò níbi tí o wà, kí o bọ́ sí inú òkun,’ tí kò bá ṣiyèméjì, ṣugbọn tí ó gbàgbọ́ pé, ohun tí òun wí yóo rí bẹ́ẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún un. Nítorí èyí, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé, ohun gbogbo tí ẹ bá bèèrè ninu adura, ẹ gbàgbọ́ pé ẹ ti rí i gbà, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fun yín. Nígbà tí ẹ bá dìde dúró láti gbadura, ẹ dáríjì ẹnikẹ́ni tí ẹ bá ní ohunkohun ninu sí, kí Baba yín ọ̀run lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín. [
Mak 11:12-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí wọ́n ti kúrò ní Betani, ebi ń pa Jesu. Ó rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan lọ́ọ̀ọ́kán tí ewé kún orí rẹ̀. Nígbà náà, ó lọ sí ìdí rẹ̀ láti wò ó bóyá ó léso tàbí kò léso. Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ewé lásán ni ó rí, kò rí èso lórí rẹ̀. Nítorí pé àkókò náà kì í ṣe àkókò tí igi ọ̀pọ̀tọ́ máa ń so. Lẹ́yìn náà, Jesu pàṣẹ fún igi náà pé, “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe jẹ èso lórí rẹ mọ́ títí láé.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́ nígbà tí ó wí bẹ́ẹ̀. Nígbà ti wọ́n padà sí Jerusalẹmu, ó wọ inú tẹmpili. Ó bẹ̀rẹ̀ sí nílé àwọn oníṣòwò àti àwọn oníbàárà wọn síta. Ó ti tábìlì àwọn tí ń pààrọ̀ owó nínú tẹmpili ṣubú. Bákan náà ni ó ti ìjókòó àwọn tí ń ta ẹyẹlé lulẹ̀. Kò sì gba ẹnikẹ́ni láààyè láti gbé ẹrù ọjà títà gba inú tẹmpili wọlé. Gẹ́gẹ́ bí ó ti kọ́ wọn, ó wí pé, “Ṣé a kò ti kọ ọ́ pé: ‘Ilé àdúrà ni a o máa pe ilé mi, ní gbogbo orílẹ̀-èdè?’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibùgbé àwọn ọlọ́ṣà.” Nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin gbọ́ ohun tí ó ti ṣe, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ń gbà èrò bí wọn yóò ti ṣe pa á. Wọ́n bẹ̀rù rògbòdìyàn tí yóò bẹ́ sílẹ̀, nítorí tí àwọn ènìyàn ní ìgbóná ọkàn sí ẹ̀kọ́ rẹ̀. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, bí ìṣe wọn, Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jáde kúrò ní ìlú Jerusalẹmu. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí wọ́n ti ń kọjá lọ, wọ́n rí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí Jesu fi bú. Wọ́n rí i pé ó ti gbẹ tigbòǹgbò tigbòǹgbò. Peteru rántí pé Jesu ti bá igi náà wí. Nígbà náà ni ó sọ fún Jesu pé, “Rabbi, Wò ó! Igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ìwọ fi bú ti gbẹ!” Jesu sì dáhùn pé, “Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, Lóòótọ́ ni mò wí fún un yín, bí ẹnikẹ́ni bá wí fún òkè ‘ṣídìí, gbé ara rẹ sọ sínú Òkun’ ti kò sì ṣe iyèméjì nínú ọkàn rẹ̀ ṣùgbọ́n tí ó gbàgbọ́ pé ohun tí òun wí yóò ṣẹ, yóò rí bẹ́ẹ̀ fún un. Torí náà, mo wí fún yín ohunkóhun tí ẹ bá béèrè fún nínú àdúrà, ẹ ní ìgbàgbọ́ pé, ó tí tẹ̀ yín lọ́wọ́, yóò sì jẹ́ tiyín. Nígbà tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ kọ́kọ́ dáríjì, bí ẹ̀yin bá ní ohunkóhun sí ẹnikẹ́ni, kí baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run bá à le dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tiyín náà jì yín.