Mik 7
7
Ìwà Ìbàjẹ́ Israẹli
1EGBE ni fun mi! nitori emi dàbi ikojọpọ̀ eso ẹ̃rùn, bi ẽṣẹ́ ikorè eso àjara: kò si ití kan lati jẹ: akọso ti ọkàn mi fẹ.
2Oninurere ti run kuro li aiye: kò si si olotitọ kan ninu enia: gbogbo wọn ba fun ẹ̀jẹ, olukuluku wọn nfi àwọn dẹ arakunrin rẹ̀.
3Ọwọ́ wọn ti mura tan lati ṣe buburu, olori mbère, onidajọ si mbère fun ẹsan; ẹni-nla nsọ ìro ika rẹ̀, nwọn si nyi i po.
4Ẹniti o sànjulọ ninu wọn dàbi ẹ̀gun: ìduroṣiṣin julọ mú jù ẹgún ọgbà lọ: ọjọ awọn olùṣọ rẹ ati ti ìbẹwo rẹ de; nisisiyi ni idãmu wọn o de.
5Ẹ má gba ọrẹ́ kan gbọ́, ẹ má si gbẹkẹ̀le amọ̀na kan: pa ilẹkùn ẹnu rẹ mọ fun ẹniti o sùn ni õkan-àiya rẹ.
6Nitori ọmọkunrin nṣàibọ̀wọ fun baba, ọmọbinrin dide si ìya rẹ̀, aya-ọmọ si iyakọ rẹ̀; ọta olukuluku ni awọn ara ile rẹ̀.
7Nitorina emi o ni ireti si Oluwa: emi o duro de Ọlọrun igbala mi: Ọlọrun mi yio gbọ́ temi.
OLUWA Mú Ìgbàlà Wá
8Má yọ̀ mi, Iwọ ọta mi: nigbati mo ba ṣubu, emi o dide; nigbati mo ba joko li okùnkun, Oluwa yio jẹ imọlẹ fun mi.
9Emi o rù ibinu Oluwa, nitori emi ti dẹṣẹ si i, titi yio fi gbà ẹjọ mi rò, ti yio si ṣe idajọ mi; yio mu mi wá si imọlẹ, emi o si ri ododo rẹ̀.
10Nitori ọta mi yio ri i, itiju yio si bò ẹniti o wipe, Nibo ni Oluwa Ọlọrun rẹ wà? oju mi yio ri i, nisisiyi ni yio di itẹ̀mọlẹ bi ẹrẹ̀ ita.
11Ọjọ ti a o mọ odi rẹ, ọjọ na ni aṣẹ yio jinà rére.
12Ọjọ na ni nwọn o si ti Assiria wá sọdọ rẹ, ati lati ilu olodi, ati lati ile iṣọ́ alagbara titi de odò, ati lati okun de okun, ati oke-nla de oke-nla.
13Ilẹ na yio si di ahoro fun awọn ti ngbe inu rẹ̀, nitori eso ìwa wọn.
Àánú OLUWA Lórí Israẹli
14Fi ọpa rẹ bọ́ enia agbo ini rẹ, ti ndágbe inu igbó lãrin Karmeli: jẹ ki wọn jẹ̀ ni Baṣani ati Gileadi, bi ọjọ igbãni.
15Bi ọjọ ti o jade kuro ni ilẹ Egipti li emi o fi ohun iyanu han a.
16Awọn orilẹ-ède yio ri, oju o si tì wọn ninu gbogbo agbara wọn: nwọn o fi ọwọ́ le ẹnu, eti wọn o si di.
17Nwọn o lá erùpẹ bi ejò, nwọn o si jade kuro ninu ihò wọn bi ekòlo ilẹ: nwọn o bẹ̀ru Oluwa Ọlọrun wa, nwọn o si bẹ̀ru nitori rẹ.
18Tani Ọlọrun bi iwọ, ti o ndari aiṣedede jì, ti o nre iyokù ini rẹ̀ kọja? kò dá ibinu rẹ̀ duro titi lai, nitori on ni inudidun si ãnu.
19Yio yipadà, yio ni iyọnú si wa; yio si tẹ̀ aiṣedede wa ba; iwọ o si sọ gbogbo ẹ̀ṣẹ wọn sinu ọgbun okun.
20Iwọ o fi otitọ fun Jakobu, ãnu fun Abrahamu, ti iwọ ti bura fun awọn baba wa, lati ọjọ igbani.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Mik 7: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.