O si pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mejila jọ, o si fun wọn li agbara on aṣẹ lori awọn ẹmi èṣu gbogbo, ati lati wò arùn sàn.
O si rán wọn lọ iwasu ijọba Ọlọrun, ati lati mu awọn olokunrun larada.
O si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe mu nkan lọ fun àjo nyin, ọpá, tabi àpo tabi akara, tabi owo; bẹ̃ni ki ẹnyin ki o má si ṣe ni àwọtẹlẹ meji.
Ni ilekile ti ẹnyin ba si wọ̀, nibẹ̀ ni ki ẹnyin ki o gbé, lati ibẹ̀ ni ki ẹnyin ki o si ti jade.
Iye awọn ti kò ba si gbà nyin, nigbati ẹnyin ba jade kuro ni ilu na, ẹ gbọ̀n ekuru ẹsẹ nyin fun ẹrí si wọn.
Nwọn si jade, nwọn nlà iletò lọ, nwọn si nwasu ihinrere, nwọn si nmu enia larada nibi gbogbo.
Herodu tetrarki si gbọ́ nkan gbogbo ti nṣe lati ọdọ rẹ̀ wá: o si damu, nitoriti awọn ẹlomiran nwipe, Johanu li o jinde kuro ninu okú;
Awọn ẹlomiran si wipe Elijah li o farahàn; ati awọn ẹlomiran pe, ọkan ninu awọn woli atijọ li o jinde.
Herodu si wipe, Johanu ni mo ti bẹ́ lori: ṣugbọn tali eyi, ti emi ngbọ́ irú nkan wọnyi si? O si nfẹ lati ri i.
Nigbati awọn aposteli si pada de, nwọn ròhin ohun gbogbo fun u ti nwọn ti ṣe. O si mu wọn, o si lọ si apakan nibi ijù si ilu ti a npè ni Betsaida.
Nigbati ọpọ enia si mọ̀, nwọn tẹle e: o si gbà wọn, o si sọ̀rọ ijọba Ọlọrun fun wọn; awọn ti o fẹ imularada, li o si mu larada.
Nigbati ọjọ bẹ̀rẹ si irẹlẹ, awọn mejila wá, nwọn si wi fun u pe, Tú ijọ enia ká, ki nwọn ki o le lọ si iletò ati si ilu yiká, ki nwọn ki o le wọ̀, ati ki nwọn ki o le wá onjẹ: nibi ijù li awa sá gbé wà nihinyi.
Ṣugbọn o wi fun wọn pe, Ẹ fi onjẹ fun wọn jẹ. Nwọn si wi fun u pe, Awa kò ni jù iṣu akara marun lọ, pẹlu ẹja meji; bikoṣepe awa lọ irà onjẹ fun gbogbo awọn enia wọnyi.
Nitori awọn ọkunrin to ìwọn ẹgbẹdọgbọn enia. O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, ki nwọn ki o mu wọn joko li ẹgbẹ-ẹgbẹ, li aradọta.
Nwọn si ṣe bẹ̃, nwọn si mu gbogbo wọn joko.
Nigbana li o mu iṣu akara marun, ati ẹja meji na, nigbati o gbé oju soke, o sure si i, o si bù u, o si fifun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ki nwọn ki o gbé e kalẹ niwaju awọn enia.
Nwọn si jẹ, gbogbo wọn si yó: nwọn ṣà agbọ̀n mejila jọ ninu ajẹkù ti o kù fun wọn.
O si ṣe, nigbati o kù on nikan, o ngbadura, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wà lọdọ rẹ̀: o si bi wọn pe, Tali awọn enia nfi emi pè?
Nwọn si dahùn wipe, Johanu Baptisti; ṣugbọn ẹlomiran ni, Elijah ni; ati awọn ẹlomiran wipe, ọkan ninu awọn woli atijọ li o jinde.
O si bi wọn pe, Ṣugbọn tali ẹnyin nfi emi ipè? Peteru si dahùn, wipe, Kristi ti Ọlọrun.
O si kìlọ fun wọn, o si paṣẹ fun wọn, pe, ki nwọn ki o máṣe sọ ohun na fun ẹnikan.
O si wipe, Ọmọ-enia ko le ṣaima jìya ohun pipọ, a o si kọ̀ ọ lati ọdọ awọn àgbagba ati lati ọdọ awọn olori alufa, ati lati ọdọ awọn akọwe wá, a o si pa a, ni ijọ kẹta a o si ji i dide.
O si wi fun gbogbo wọn pe, Bi ẹnikan ba nfẹ lati mã tọ̀ mi lẹhin, ki o sẹ́ ara rẹ̀, ki o si gbé agbelebu rẹ̀ ni ijọ gbogbo, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin.
Nitori ẹnikẹni ti o ba fẹ gbà ẹmí rẹ̀ là, yio sọ ọ nù: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba sọ ẹmí rẹ̀ nù nitori mi, on na ni yio si gbà a là.
Nitoripe ère kini fun enia, bi o jère gbogbo aiye, ti o si sọ ara rẹ̀ nù, tabi ki o fi ara rẹ̀ ṣòfò.
Nitori ẹnikẹni ti o ba tiju mi, ati ọ̀rọ mi, oju rẹ̀ li Ọmọ-enia yio si tì, nigbati o ba de inu ogo tirẹ̀, ati ti baba rẹ̀, ati ti awọn angẹli mimọ́.
Ṣugbọn emi wi fun nyin nitõtọ, ẹlomiran duro nihinyi, ti kì yio ri ikú, titi nwọn o fi ri ijọba Ọlọrun.
O si ṣe bi iwọn ijọ kẹjọ lẹhin ọ̀rọ wọnyi, o mu Peteru, ati Johanu, ati Jakọbu, o gùn ori òke lọ lati gbadura.
Bi o si ti ngbadura, àwọ oju rẹ̀ yipada, aṣọ rẹ̀ si fun lawu, o njo fòfo.
Si kiyesi i, awọn ọkunrin meji, ti iṣe Mose on Elijah, nwọn mba a sọ̀rọ:
Ti nwọn fi ara hàn ninu ogo, nwọn si nsọ̀rọ ikú rẹ̀, ti on ó ṣe pari ni Jerusalemu.
Ṣugbọn oju Peteru ati ti awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀ wuwo fun õrun. Nigbati nwọn si tají, nwọn ri ogo rẹ̀, ati ti awọn ọkunrin mejeji ti o ba a duro.
O si ṣe, nigbati nwọn lọ kuro lọdọ rẹ̀, Peteru wi fun Jesu pe, Olukọni, o dara fun wa ki a mã gbé ihinyi: jẹ ki awa ki o pa agọ́ mẹta; ọkan fun iwọ, ati ọkan fun Mose, ati ọkan fun Elijah: kò mọ̀ eyi ti o nwi.
Bi o ti nsọ bayi, ikũkũ kan wá, o ṣiji bò wọn: ẹ̀ru si ba wọn nigbati nwọn nwọ̀ inu ikuku lọ.
Ohùn kan si ti inu ikũkũ wá, o ni, Eyiyi li ayanfẹ Ọmọ mi: ẹ mã gbọ́ tirẹ̀.
Nigbati ohùn na si dakẹ, Jesu nikanṣoṣo li a ri. Nwọn si pa a mọ́, nwọn kò si sọ ohunkohun ti nwọn ri fun ẹnikẹni ni ijọ wọnni.