Luk 9:1-36

Luk 9:1-36 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mejila jọ, o si fun wọn li agbara on aṣẹ lori awọn ẹmi èṣu gbogbo, ati lati wò arùn sàn. O si rán wọn lọ iwasu ijọba Ọlọrun, ati lati mu awọn olokunrun larada. O si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe mu nkan lọ fun àjo nyin, ọpá, tabi àpo tabi akara, tabi owo; bẹ̃ni ki ẹnyin ki o má si ṣe ni àwọtẹlẹ meji. Ni ilekile ti ẹnyin ba si wọ̀, nibẹ̀ ni ki ẹnyin ki o gbé, lati ibẹ̀ ni ki ẹnyin ki o si ti jade. Iye awọn ti kò ba si gbà nyin, nigbati ẹnyin ba jade kuro ni ilu na, ẹ gbọ̀n ekuru ẹsẹ nyin fun ẹrí si wọn. Nwọn si jade, nwọn nlà iletò lọ, nwọn si nwasu ihinrere, nwọn si nmu enia larada nibi gbogbo. Herodu tetrarki si gbọ́ nkan gbogbo ti nṣe lati ọdọ rẹ̀ wá: o si damu, nitoriti awọn ẹlomiran nwipe, Johanu li o jinde kuro ninu okú; Awọn ẹlomiran si wipe Elijah li o farahàn; ati awọn ẹlomiran pe, ọkan ninu awọn woli atijọ li o jinde. Herodu si wipe, Johanu ni mo ti bẹ́ lori: ṣugbọn tali eyi, ti emi ngbọ́ irú nkan wọnyi si? O si nfẹ lati ri i. Nigbati awọn aposteli si pada de, nwọn ròhin ohun gbogbo fun u ti nwọn ti ṣe. O si mu wọn, o si lọ si apakan nibi ijù si ilu ti a npè ni Betsaida. Nigbati ọpọ enia si mọ̀, nwọn tẹle e: o si gbà wọn, o si sọ̀rọ ijọba Ọlọrun fun wọn; awọn ti o fẹ imularada, li o si mu larada. Nigbati ọjọ bẹ̀rẹ si irẹlẹ, awọn mejila wá, nwọn si wi fun u pe, Tú ijọ enia ká, ki nwọn ki o le lọ si iletò ati si ilu yiká, ki nwọn ki o le wọ̀, ati ki nwọn ki o le wá onjẹ: nibi ijù li awa sá gbé wà nihinyi. Ṣugbọn o wi fun wọn pe, Ẹ fi onjẹ fun wọn jẹ. Nwọn si wi fun u pe, Awa kò ni jù iṣu akara marun lọ, pẹlu ẹja meji; bikoṣepe awa lọ irà onjẹ fun gbogbo awọn enia wọnyi. Nitori awọn ọkunrin to ìwọn ẹgbẹdọgbọn enia. O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, ki nwọn ki o mu wọn joko li ẹgbẹ-ẹgbẹ, li aradọta. Nwọn si ṣe bẹ̃, nwọn si mu gbogbo wọn joko. Nigbana li o mu iṣu akara marun, ati ẹja meji na, nigbati o gbé oju soke, o sure si i, o si bù u, o si fifun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ki nwọn ki o gbé e kalẹ niwaju awọn enia. Nwọn si jẹ, gbogbo wọn si yó: nwọn ṣà agbọ̀n mejila jọ ninu ajẹkù ti o kù fun wọn. O si ṣe, nigbati o kù on nikan, o ngbadura, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wà lọdọ rẹ̀: o si bi wọn pe, Tali awọn enia nfi emi pè? Nwọn si dahùn wipe, Johanu Baptisti; ṣugbọn ẹlomiran ni, Elijah ni; ati awọn ẹlomiran wipe, ọkan ninu awọn woli atijọ li o jinde. O si bi wọn pe, Ṣugbọn tali ẹnyin nfi emi ipè? Peteru si dahùn, wipe, Kristi ti Ọlọrun. O si kìlọ fun wọn, o si paṣẹ fun wọn, pe, ki nwọn ki o máṣe sọ ohun na fun ẹnikan. O si wipe, Ọmọ-enia ko le ṣaima jìya ohun pipọ, a o si kọ̀ ọ lati ọdọ awọn àgbagba ati lati ọdọ awọn olori alufa, ati lati ọdọ awọn akọwe wá, a o si pa a, ni ijọ kẹta a o si ji i dide. O si wi fun gbogbo wọn pe, Bi ẹnikan ba nfẹ lati mã tọ̀ mi lẹhin, ki o sẹ́ ara rẹ̀, ki o si gbé agbelebu rẹ̀ ni ijọ gbogbo, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin. Nitori ẹnikẹni ti o ba fẹ gbà ẹmí rẹ̀ là, yio sọ ọ nù: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba sọ ẹmí rẹ̀ nù nitori mi, on na ni yio si gbà a là. Nitoripe ère kini fun enia, bi o jère gbogbo aiye, ti o si sọ ara rẹ̀ nù, tabi ki o fi ara rẹ̀ ṣòfò. Nitori ẹnikẹni ti o ba tiju mi, ati ọ̀rọ mi, oju rẹ̀ li Ọmọ-enia yio si tì, nigbati o ba de inu ogo tirẹ̀, ati ti baba rẹ̀, ati ti awọn angẹli mimọ́. Ṣugbọn emi wi fun nyin nitõtọ, ẹlomiran duro nihinyi, ti kì yio ri ikú, titi nwọn o fi ri ijọba Ọlọrun. O si ṣe bi iwọn ijọ kẹjọ lẹhin ọ̀rọ wọnyi, o mu Peteru, ati Johanu, ati Jakọbu, o gùn ori òke lọ lati gbadura. Bi o si ti ngbadura, àwọ oju rẹ̀ yipada, aṣọ rẹ̀ si fun lawu, o njo fòfo. Si kiyesi i, awọn ọkunrin meji, ti iṣe Mose on Elijah, nwọn mba a sọ̀rọ: Ti nwọn fi ara hàn ninu ogo, nwọn si nsọ̀rọ ikú rẹ̀, ti on ó ṣe pari ni Jerusalemu. Ṣugbọn oju Peteru ati ti awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀ wuwo fun õrun. Nigbati nwọn si tají, nwọn ri ogo rẹ̀, ati ti awọn ọkunrin mejeji ti o ba a duro. O si ṣe, nigbati nwọn lọ kuro lọdọ rẹ̀, Peteru wi fun Jesu pe, Olukọni, o dara fun wa ki a mã gbé ihinyi: jẹ ki awa ki o pa agọ́ mẹta; ọkan fun iwọ, ati ọkan fun Mose, ati ọkan fun Elijah: kò mọ̀ eyi ti o nwi. Bi o ti nsọ bayi, ikũkũ kan wá, o ṣiji bò wọn: ẹ̀ru si ba wọn nigbati nwọn nwọ̀ inu ikuku lọ. Ohùn kan si ti inu ikũkũ wá, o ni, Eyiyi li ayanfẹ Ọmọ mi: ẹ mã gbọ́ tirẹ̀. Nigbati ohùn na si dakẹ, Jesu nikanṣoṣo li a ri. Nwọn si pa a mọ́, nwọn kò si sọ ohunkohun ti nwọn ri fun ẹnikẹni ni ijọ wọnni.

Luk 9:1-36 Yoruba Bible (YCE)

Jesu pe àwọn mejila jọ. Ó fún wọn ní agbára ati àṣẹ láti lé gbogbo ẹ̀mí èṣù jáde ati láti ṣe ìwòsàn oríṣìíríṣìí àìsàn. Ó rán wọn láti waasu ìjọba Ọlọrun ati láti ṣe ìwòsàn. Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe mú nǹkankan lọ́wọ́ lọ ìrìn àjò yìí: ẹ má mú ọ̀pá lọ́wọ́, tabi àpò báárà tabi oúnjẹ tabi owó, tabi àwọ̀tẹ́lẹ̀ meji. Ilé tí ẹ bá wọ̀ sí, níbẹ̀ ni kí ẹ máa gbé títí ẹ óo fi kúrò ní ìlú náà. Ibikíbi tí wọn kò bá ti gbà yín, nígbà tí ẹ bá jáde kúrò ninu ìlú náà, ẹ gbọn eruku ẹsẹ̀ yín sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí sí wọn.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bá ń lọ láti abúlé dé abúlé, wọ́n ń waasu ìyìn rere, wọ́n sì ń ṣe ìwòsàn níbi gbogbo. Nígbà tó yá, Hẹrọdu, baálẹ̀, gbọ́ nípa gbogbo nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀, ó dààmú; nítorí àwọn kan ń sọ pé Johanu ni ó jí dìde kúrò ninu òkú. Ṣugbọn àwọn mìíràn ń sọ pé Elija ni ó fara hàn. Àwọn mìíràn ní ọ̀kan ninu àwọn wolii àtijọ́ ni ó tún pada. Ṣugbọn Hẹrọdu ní “Ní ti Johanu, mo ti bẹ́ ẹ lórí. Ta wá ni òun, tí mò ń gbọ́ gbogbo nǹkan wọnyi nípa rẹ̀?” Hẹrọdu bá ń wá ọ̀nà láti fojú kàn án. Àwọn aposteli tí Jesu rán níṣẹ́ pada wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ròyìn gbogbo ohun tí wọ́n ti ṣe fún un. Ó bá rọra dá àwọn nìkan mú lọ sí ìlú kan tí ń jẹ́ Bẹtisaida. Ṣugbọn àwọn eniyan mọ̀, ni wọ́n bá tẹ̀lé e. Ó gbà wọ́n pẹlu ayọ̀, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ìjọba Ọlọrun, ó tún ń wo àwọn aláìsàn sàn. Nígbà tí ọjọ́ rọ̀, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila sọ fún un pé, “Tú àwọn eniyan wọnyi ká kí wọ́n lè lọ sí àwọn abúlé káàkiri ati àwọn ìletò láti wọ̀ sí ati láti wá oúnjẹ, nítorí aṣálẹ̀ ni ibi tí a wà yìí.” Ṣugbọn Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni kí ẹ fún wọn ní oúnjẹ.” Wọ́n dáhùn pé, “A kò ní oúnjẹ pupọ, àfi burẹdi marun-un ati ẹja meji, ṣé kí àwa fúnra wa lọ ra oúnjẹ fún gbogbo àwọn eniyan wọnyi ni?” (Àwọn ọkunrin ninu wọn tó bíi ẹgbẹẹdọgbọn (5,000).) Ó bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí wọ́n jókòó ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ bí araadọta.” Wọ́n bá ṣe bí ó ti wí: wọ́n fi gbogbo wọn jókòó. Jesu bá mú burẹdi marun-un yìí ati ẹja meji, ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó gbadura sí i, ó pín wọn sí wẹ́wẹ́, ó bá fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n fún àwọn eniyan. Gbogbo àwọn eniyan jẹ, wọ́n yó. Wọ́n kó àjẹkù jọ, ó sì kún apẹ̀rẹ̀ mejila. Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Jesu nìkan ń dá gbadura tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Ó bi wọ́n pé, “Ta ni àwọn eniyan rò pé mo jẹ́?” Wọ́n dáhùn pé, “Àwọn kan ní Johanu Onítẹ̀bọmi ni ọ́, ṣugbọn àwọn mìíràn ní, Elija ni ọ. Àwọn mìíràn tún sọ pé ọ̀kan ninu àwọn wolii àtijọ́ ni ó jí dìde.” Ó wá bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ńkọ́? Ta ni ẹ rò pé mo jẹ́?” Peteru dáhùn pé, “Mesaya Ọlọrun ni ọ́.” Jesu wá kìlọ̀ fún wọn kí wọn má sọ fún ẹnikẹ́ni. Ó ní, “Dandan ni kí Ọmọ-Eniyan jìyà pupọ, kí àwọn àgbà ati àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin kọ̀ ọ́, kí wọ́n sì pa á, ṣugbọn a óo jí i dìde ní ọjọ́ kẹta.” Ó bá sọ fún gbogbo àwọn eniyan pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ máa tẹ̀lé mí, ó níláti sẹ́ ara rẹ̀, kí ó gbé agbelebu rẹ̀ lojoojumọ, kí ó wá máa tọ̀ mí lẹ́yìn. Nítorí pé ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là, yóo pàdánù rẹ̀, ṣugbọn ẹni tí ó bá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nítorí mi, òun ni yóo gba ẹ̀mí rẹ̀ là. Nítorí anfaani wo ni ó jẹ́ fún ẹnikẹ́ni, bí ó bá jèrè gbogbo ayé, ṣugbọn tí ó pàdánù ẹ̀mí ara rẹ̀? Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá tijú mi ati àwọn ọ̀rọ̀ mi, òun ni Ọmọ-Eniyan yóo tijú nígbà tí ó bá dé ninu ògo rẹ̀ ati ògo Baba rẹ̀, pẹlu àwọn angẹli mímọ́. Ṣugbọn mo sọ fun yín dájúdájú, àwọn mìíràn wà ninu àwọn tí ó dúró níhìn-ín tí wọn kò ní kú títí wọn óo fi rí ìjọba Ọlọrun.” Ó tó bí ọjọ́ mẹjọ lẹ́yìn tí ọ̀rọ̀ yìí ṣẹlẹ̀, Jesu mú Peteru, Johanu ati Jakọbu lọ sí orí òkè kan láti gbadura. Bí ó ti ń gbadura, ìwò ojú rẹ̀ yipada, aṣọ rẹ̀ wá funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Àwọn ọkunrin meji kan yọ lójijì, wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀. Àwọn ni Mose ati Elija. Wọ́n farahàn ninu ògo, wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀ nípa irú ikú tí yóo kú láìpẹ́, ní Jerusalẹmu. Ṣugbọn oorun ti ń kun Peteru ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀. Nígbà tí wọ́n tají, wọ́n rí ògo rẹ̀ ati àwọn ọkunrin meji tí wọ́n dúró tì í. Bí àwọn meji yìí ti ń kúrò lọ́dọ̀ Jesu, Peteru sọ fún un pé, “Ọ̀gá, ìbá dára tí a bá lè máa wà níhìn-ín. Jẹ́ kí á pa àgọ́ mẹta, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mose, ati ọ̀kan fún Elija.” Ó sọ èyí nítorí kò mọ ohun tíì bá sọ. Bí ó ti ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, ìkùukùu bá ṣíji bò wọ́n. Ẹ̀rù ba Peteru ati Johanu ati Jakọbu nígbà tí Mose ati Elija wọ inú ìkùukùu náà. Ohùn kan ti inú ìkùukùu náà wá, ó ní “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹ máa gbọ́ tirẹ̀!” Bí wọ́n ti gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, Jesu nìkan ni wọ́n rí. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bá pa ẹnu mọ̀, wọn kò sọ ohun tí wọ́n gbọ́ ati ohun tí wọ́n rí ní àkókò náà fún ẹnikẹ́ni.

Luk 9:1-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ó sì pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá jọ, ó sì fún wọn ní agbára àti àṣẹ lórí àwọn ẹ̀mí èṣù gbogbo, àti láti wo ààrùn sàn. Ó sì rán wọn lọ wàásù ìjọba Ọlọ́run, àti láti mú àwọn ọlọkùnrùn láradá. Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe mú nǹkan lọ́wọ́ fún àjò yín, ọ̀pá, tàbí àpò tàbí àkàrà, tàbí owó: bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin má sì ṣe ní ẹ̀wù méjì. Ní ilékílé tí ẹ̀yin bá sì wọ̀, níbẹ̀ ni kí ẹ̀yin gbé, láti ibẹ̀ ni kí ẹ̀yin sì ti jáde. Iye àwọn tí kò bá si gbà yín, nígbà tí ẹ̀yin bá jáde kúrò ní ìlú náà, ẹ gbọn eruku ẹsẹ̀ yín fún ẹ̀rí sí wọn.” Wọ́n sì lọ, wọ́n ń la ìletò kọjá wọ́n sì ń wàásù ìhìnrere, wọ́n sì ń mú ènìyàn láradá níbi gbogbo. Herodu tetrarki gbọ́ nǹkan gbogbo èyí tí a ṣe láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá: ó sì dààmú, nítorí tí àwọn ẹlòmíràn ń wí pé, Johanu ni ó jíǹde kúrò nínú òkú; Àwọn ẹlòmíràn sì wí pé Elijah ni ó farahàn; àwọn ẹlòmíràn sì wí pé, ọ̀kan nínú àwọn wòlíì àtijọ́ ni ó jíǹde. Herodu sì wí pé, “Johanu ni mo ti bẹ́ lórí: ṣùgbọ́n ta ni èyí tí èmi ń gbọ́ irú nǹkan wọ̀nyí sí?” Ó sì ń fẹ́ láti rí i. Nígbà tí àwọn aposteli sì padà dé, wọ́n ròyìn ohun gbogbo fún un tí wọ́n ti ṣe. Ó sì mú wọn, lọ sí apá kan níbi tí a ń pè ní Betisaida. Nígbà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn sì mọ̀, wọ́n tẹ̀lé e: ó sì gbà wọ́n, ó sì sọ̀rọ̀ ìjọba Ọlọ́run fún wọn; àwọn tí ó fẹ́ ìmúláradá, ni ó sì mú láradá. Nígbà tí ọjọ́ bẹ̀rẹ̀ sí rọlẹ̀, àwọn méjìlá wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Tú ìjọ ènìyàn ká, kí wọn lè lọ sí ìletò àti sí ìlú yíká, kí wọn lè wò, àti kí wọn lè wá oúnjẹ: nítorí ijù ni àwa sá wà níhìn-ín.” Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Ẹ fi oúnjẹ fún wọn jẹ!” Wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa kò ní ju ìṣù àkàrà márùn-ún lọ, pẹ̀lú ẹja méjì: bí kò ṣe pé àwa lọ ra oúnjẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí.” Nítorí àwọn ọkùnrin náà tó ìwọ̀n ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn. Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Kí wọ́n mú wọn jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́, ní àràádọ́ta.” Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n sì mú gbogbo wọn jókòó. Nígbà náà ni ó mú ìṣù àkàrà márùn-ún, àti ẹja méjì náà, nígbà tí ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó súre sí i, ó sì bù ú, ó sì fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, kí wọn gbé e kalẹ̀ níwájú àwọn ènìyàn. Wọ́n sì jẹ, gbogbo wọn sì yó: wọ́n ṣa agbọ̀n méjìlá jọ nínú àjẹkù tí ó kù. Ó sì ṣe, nígbà tí ó ku òun nìkan ó gbàdúrà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀: ó sì bi wọ́n pé, “Ta ni àwọn ènìyàn ń fi mí pè?” Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Johanu Onítẹ̀bọmi; ṣùgbọ́n ẹlòmíràn ní Elijah ni; àti àwọn ẹlòmíràn wí pé, ọ̀kan nínú àwọn wòlíì àtijọ́ ni ó jíǹde.” Ó sì bi wọ́n pé, “Ṣùgbọ́n ta ni ẹ̀yin ń fi èmi pè?” Peteru sì dáhùn, wí pe, “Kristi ti Ọlọ́run.” Ó sì kìlọ̀ fún wọn, pé, kí wọn má ṣe sọ èyí fún ẹnìkan. Ó sì wí pé, “Ọmọ ènìyàn yóò jìyà ohun púpọ̀, a ó sì kọ̀ ọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà, olórí àlùfáà àti láti ọ̀dọ̀ àwọn akọ̀wé, a ó sì pa á, ní ọjọ́ kẹta a ó sì jí i dìde.” Ó sì wí fún gbogbo wọn pé, “Bí ẹnìkan bá ń fẹ́ láti máa tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó sì gbé àgbélébùú rẹ̀ ní ọjọ́ gbogbo, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ọkàn rẹ̀ là, yóò sọ ọ́ nù: ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọkàn rẹ̀ nù nítorí mi, òun náà ni yóò sì gbà á là. Nítorí pé èrè kín ni fún ènìyàn, bí ó jèrè gbogbo ayé, tí ó sì sọ ara rẹ̀ nù tàbí kí ó fi ṣòfò. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá tijú mi, àti ọ̀rọ̀ mi, òun ni ọmọ ènìyàn yóò tijú rẹ̀ nígbà tí ó bá dé inú ògo tirẹ̀, àti ti baba rẹ̀, àti ti àwọn angẹli mímọ́. “Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín nítòótọ́, ẹlòmíràn dúró níhìn-ín yìí, tí kì yóò rí ikú, títí wọn ó fi rí ìjọba Ọlọ́run.” Ó sì ṣe bí ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́jọ lẹ́yìn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó mú Peteru àti Johanu àti Jakọbu, ó gun orí òkè lọ láti lọ gbàdúrà. Bí ó sì ti ń gbàdúrà, àwọ̀ ojú rẹ̀ yípadà, aṣọ rẹ̀ sì funfun gbòò, Sì kíyèsi i, àwọn ọkùnrin méjì, Mose àti Elijah, wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀: Tí wọ́n fi ara hàn nínú ògo, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ ikú rẹ̀, tí òun yóò ṣe parí ní Jerusalẹmu. Ṣùgbọ́n ojú Peteru àti ti àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ wúwo fún oorun. Nígbà tí wọ́n sì tají, wọ́n rí ògo rẹ̀, àti ti àwọn ọkùnrin méjèèjì tí ó bá a dúró. Ó sì ṣe, nígbà tí wọ́n lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, Peteru wí fún Jesu pé, “Olùkọ́, ó dára fún wa kí a máa gbé ìhín yìí: jẹ́ kí àwa pa àgọ́ mẹ́ta; ọ̀kan fún ìwọ, àti ọ̀kan fún Mose, àti ọ̀kan fún Elijah.” (Kò mọ èyí tí òun ń wí.) Bí ó ti ń sọ báyìí, ìkùùkuu kan wá, ó ṣíji bò wọ́n: ẹ̀rù sì bà wọ́n nígbà tí wọ́n ń wọ inú ìkùùkuu lọ. Ohùn kan sì ti inú ìkùùkuu wá wí pé, “Èyí yìí ni àyànfẹ́ ọmọ mi: ẹ máa gbọ́ tirẹ̀.” Nígbà tí ohùn náà sì dákẹ́, Jesu nìkan ṣoṣo ni a rí. Wọ́n sì pa á mọ́, wọn kò sì sọ ohunkóhun tí wọ́n rí fún ẹnikẹ́ni ní ọjọ́ wọ̀nyí.