Luk 5:1-3

Luk 5:1-3 YBCV

O si ṣe, nigbati ijọ enia ṣù mọ́ ọ lati gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun, ti o si duro leti adagun Genesareti, O ri ọkọ̀ meji ti nwọn gún leti adagun: ṣugbọn awọn apẹja sọkalẹ kuro ninu wọn, nwọn nfọ̀ àwọn wọn. O si wọ̀ ọkan ninu awọn ọkọ̀ na, ti iṣe ti Simoni, o si bẹ̀ ẹ ki o tẹ̀ si ẹhin diẹ kuro ni ilẹ. O si joko, o si nkọ́ ijọ enia lati inu ọkọ̀ na.

Àwọn fídíò fún Luk 5:1-3