LUKU 5:1-3

LUKU 5:1-3 YCE

Ní àkókò kan, bí Jesu ti dúró létí òkun Genesarẹti, ọ̀pọ̀ eniyan péjọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ó rí àwọn ọkọ̀ meji létí òkun. Àwọn apẹja ti kúrò ninu àwọn ọkọ̀ yìí, wọ́n ń fọ àwọ̀n wọn. Jesu bá wọ inú ọ̀kan ninu àwọn ọkọ̀ náà tí ó jẹ́ ti Simoni, ó ní kí wọ́n tù ú kúrò létí òkun díẹ̀. Ni ó bá jókòó ninu ọkọ̀, ó ń kọ́ àwọn eniyan.

Àwọn fídíò fún LUKU 5:1-3