O si ṣe, ni ijọ kan li ọjọ wọnni, bi o ti nkọ́ awọn enia ni tẹmpili ti o si nwasu ihinrere, awọn olori alufa, ati awọn pẹlu awọn agbagbà dide sí i,
Nwọn si wi fun u pe, Sọ fun wa, aṣẹ wo ni iwọ fi nṣe nkan wọnyi? tabi tali o fun ọ li aṣẹ yi?
O si dahùn o si wi fun wọn pe, Emi pẹlu yio si bi nyin lẽre ọ̀rọ kan; ẹ sọ fun mi.
Baptismu ti Johanu, lati ọrun wá ni tabi lọdọ enia?
Nwọn si ba ara wọn gbèro wipe, Bi awa ba wipe, Lati ọrun wá ni; on o wipe, Ẽṣe ti ẹnyin kò fi gbà a gbọ́?
Ṣugbọn bi awa ba si wipe, Lati ọdọ enia; gbogbo enia ni yio sọ wa li okuta; nitori nwọn gbagbọ pe, woli ni Johanu.
Nwọn si dahùn wipe, nwọn kò mọ̀ ibiti o ti wá.
Jesu si wi fun wọn pe, Njẹ emi ki yio wi fun nyin aṣẹ ti emi fi nṣe nkan wọnyi.
Nigbana li o bẹ̀rẹ si ipa owe yi fun awọn enia pe: Ọkunrin kan gbìn ọgba ajara kan, o si fi ṣe agbatọju fun awọn àgbẹ, o si lọ si àjo fun igba pipẹ.
Nigbati o si di akokò, o rán ọmọ-ọdọ rẹ̀ kan si awọn àgbẹ na, ki nwọn ki o le fun u ninu eso ọgba ajara na: ṣugbọn awọn àgbẹ lù u, nwọn si rán a pada lọwọ ofo.
O si tún rán ọmọ-ọdọ miran: nwọn si lù u pẹlu, nwọn si jẹ ẹ nìya, nwọn si rán a pada lọwọ ofo.
O si tún rán ẹkẹta: nwọn si ṣá a lọgbẹ pẹlu, nwọn si tì i jade.
Nigbana li oluwa ọgba ajara wipe, Ewo li emi o ṣe? emi o rán ọmọ mi ayanfẹ lọ: bọya nigbati nwọn ba ri i, nwọn o ṣojuṣaju fun u.
Ṣugbọn nigbati awọn àgbẹ na ri i, nwọn ba ara wọn gbèro pe, Eyi li arole: ẹ wá, ẹ jẹ ki a pa a, ki ogún rẹ̀ ki o le jẹ ti wa.
Bẹ̃ni nwọn si ti i jade sẹhin ọgba ajara, nwọn si pa a. Njẹ kili oluwa ọgba ajara na yio ṣe si wọn?
Yio wá, yio si pa awọn àgbẹ wọnni run, yio si fi ọgba ajara na fun awọn ẹlomiran. Nigbati nwọn si gbọ́, nwọn ni, Ki a má rí i.
Nigbati o si wò wọn, o ni, Ewo ha li eyi ti a ti kọwe pe, Okuta ti awọn ọmọle kọ̀ silẹ, on na li a sọ di pàtaki igun ile?
Ẹnikẹni ti o ba ṣubu lù okuta na yio fọ́; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba ṣubu lù, yio lọ̀ ọ lulú.
Awọn olori alufa ati awọn akọwe nwá ọna ati mu u ni wakati na; ṣugbọn nwọn bẹ̀ru awọn enia: nitoriti nwọn mọ̀ pe, o pa owe yi mọ wọn.
Nwọn si nṣọ ọ, nwọn si rán awọn amí ti nwọn jẹ ẹlẹtan fi ara wọn pe olõtọ enia, ki nwọn ki o le gbá ọ̀rọ rẹ̀ mu, ki nwọn ki o le fi i le agbara ati aṣẹ Bãlẹ.
Nwọn si bi i, wipe, Olukọni, awa mọ̀ pe, iwọ a ma sọrọ fun ni, iwọ a si ma kọ́-ni bi o ti tọ, bẹ̃ni iwọ kì iṣojuṣaju ẹnikan ṣugbọn iwọ nkọ́-ni li ọ̀na Ọlọrun li otitọ.
O tọ́ fun wa lati mã san owode fun Kesari, tabi kò tọ́?
Ṣugbọn o kiyesi arekereke wọn, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ndán mi wò?
Ẹ fi owo-idẹ kan hàn mi. Aworan ati akọle ti tani wà nibẹ? Nwọn si da a lohùn pe, Ti Kesari ni.
O si wi fun wọn pe, Njẹ ẹ fi ohun ti iṣe ti Kesari fun Kesari, ati ohun ti iṣe ti Ọlọrun fun Ọlọrun.
Nwọn kò si le gbá ọ̀rọ rẹ̀ mu niwaju awọn enia: ẹnu si yà wọn si idahùn rẹ̀, nwọn si pa ẹnu wọn mọ́.