Ní ọjọ́ kan, bí Jesu ti ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ ninu Tẹmpili, tí ó ń waasu ìyìn rere fún wọn, àwọn olórí alufaa, àwọn amòfin, ati àwọn àgbà wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Wọ́n bi í pé, “Sọ fún wa irú àṣẹ tí o fi ń ṣe àwọn nǹkan wọnyi; ta ni ó sì fún ọ ní àṣẹ yìí?”
Ó dá wọn lóhùn pé, “Èmi náà yóo bi yín ní ọ̀rọ̀ kan, ẹ dá mi lóhùn. Ìrìbọmi tí Johanu ń ṣe, láti ọ̀run wá ni, tabi láti ọ̀dọ̀ eniyan?”
Wọ́n ń bá ara wọn sọ pé, “Bí a bá sọ pé, ‘Láti ọ̀run ni,’ yóo bi wá pé, ‘Kí ló dé tí ẹ kò fi gbà á gbọ́?’ Bí a bá sọ pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ eniyan ni,’ gbogbo àwọn eniyan yóo sọ wá ní òkúta pa, nítorí wọ́n gbà dájú pé wolii ni Johanu.” Wọ́n bá dá a lóhùn pé, “A kò mọ ibi tí ó ti wá.”
Jesu bá sọ fún wọn pé, “Èmi náà kò ní sọ irú àṣẹ tí mo fi ń ṣe nǹkan wọnyi fún yín.”
Ó wá pa òwe yìí fún àwọn eniyan. Ó ní, “Ọkunrin kan gbin àjàrà sinu ọgbà kan, ó gba àwọn alágbàro sibẹ, ó bá lọ sí ìrìn àjò. Ó pẹ́ níbi tí ó lọ. Nígbà tí ó yá, ó rán ẹrú rẹ̀ kan sí àwọn alágbàro náà. Ṣugbọn àwọn alágbàro yìí lù ú, wọ́n bá dá a pada ní ọwọ́ òfo. Ọkunrin yìí tún rán ẹrú mìíràn. Àwọn alágbàro yìí tún lù ú, wọ́n fi àbùkù kàn án, wọ́n bá tún dá òun náà pada ní ọwọ́ òfo. Ọkunrin yìí tún rán ẹnìkẹta. Wọ́n tilẹ̀ ṣe òun léṣe ni, ní tirẹ̀, wọ́n bá lé e jáde. Ẹni tí ó ni ọgbà yìí wá rò ninu ara rẹ̀ pé, ‘Kí ni n óo ṣe o? N óo rán àyànfẹ́ ọmọ mi, bóyá wọn yóo bọlá fún un.’ Ṣugbọn nígbà tí àwọn alágbàro yìí rí i, wọ́n bà ara wọn sọ pé, ‘Àrólé rẹ̀ nìyí. Ẹ jẹ́ kí á pa á, kí ogún rẹ̀ lè di tiwa.’ Ni wọ́n bá mú un jáde kúrò ninu ọgbà náà, wọ́n bá pa á.
“Kí ni ẹni tí ó ni ọgbà náà yóo wá ṣe? Yóo pa àwọn alágbàro wọnyi, yóo sì gbé ọgbà rẹ̀ fún àwọn mìíràn láti tọ́jú.”
Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n ní “Ọlọrun má jẹ́!”
Jesu bá wò wọ́n lójú, ó ní, “Ǹjẹ́ kí ni ìtumọ̀ àkọsílẹ̀ yìí,
‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀,
òun ni ó di òkúta pataki ní igun ilé.’
Bí ẹnikẹ́ni bá ṣubú lu òkúta yìí, olúwarẹ̀ yóo fọ́ yángá-yángá, bí òkúta yìí bá sì bọ́ lu ẹnikẹ́ni, rírẹ́ ni yóo rẹ́ olúwarẹ̀ pẹ́tẹ́pẹ́tẹ́.”
Àwọn akọ̀wé ati àwọn olórí alufaa gbèrò láti mú un ní wakati náà, nítorí wọ́n mọ̀ pé àwọn ni ó pa òwe yìí mọ́; ṣugbọn wọ́n bẹ̀rù àwọn eniyan.
Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣọ́ ọ. Wọ́n rán àwọn amí kí wọ́n ṣe bí eniyan rere, kí wọ́n lè ká ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu, kí wọn wá fi lé gomina lọ́wọ́, kí gomina dá sẹ̀ría fún un. Wọ́n bi í pé, “Olùkọ́ni, a mọ̀ pé tààrà ni ò ń sọ̀rọ̀, tí o sì ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́. O kì í wo ojú eniyan kí o tó sọ̀rọ̀. Ṣugbọn pẹlu òtítọ́ ni ò ń kọ́ eniyan ní ọ̀nà Ọlọrun. Ṣé ó tọ́ fún wa láti san owó-orí fún Kesari, àbí kò tọ́?”
Ṣugbọn ó ti mọ ẹ̀tàn wọn. Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ fi owó fadaka kan hàn mí.” Ó bá bi wọ́n léèrè pé, “Àwòrán ati àkọlé ta ni ti ara rẹ̀ yìí?”
Wọ́n ní, “Ti Kesari ni.”
Ó bá wí fún wọn pé, “Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ fi ohun tí ó bá jẹ́ ti Kesari fún Kesari, kí ẹ sì fi ohun tí ó bá jẹ́ ti Ọlọrun fún Ọlọrun.”
Wọn kò lè mú ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu lójú gbogbo eniyan. Ìdáhùn rẹ̀ yà wọ́n lẹ́nu, wọ́n bá dákẹ́.