Ọkan ninu awujọ si wi fun u pe, Olukọni, sọ fun arakunrin mi ki o pín mi li ogún. O si wi fun u pe, Ọkunrin yi, tali o fi mi jẹ onidajọ tabi olùpín-ogún wá fun nyin? O si wi fun wọn pe, Kiyesara ki ẹ si mã ṣọra nitori ojukòkoro: nitori igbesi aiye enia ki iduro nipa ọ̀pọ ohun ti o ni. O si pa owe kan fun wọn, wipe, Ilẹ ọkunrin kan ọlọrọ̀ so eso ọ̀pọlọpọ: O si rò ninu ara rẹ̀, wipe, Emi o ti ṣe, nitoriti emi kò ni ibiti emi o gbé kó eso mi jọ si? O si wipe, Eyi li emi o ṣe: emi o wó aká mi palẹ, emi o si kọ́ eyi ti o tobi; nibẹ̀ li emi o gbé tò gbogbo eso ati ọrọ̀ mi jọ si. Emi o si wi fun ọkàn mi pe, Ọkàn, iwọ li ọrọ̀ pipọ ti a tò jọ fun ọ̀pọ ọdún; simi mã jẹ, mã mu, mã yọ̀. Ṣugbọn Ọlọrun wi fun u pe, Iwọ aṣiwere, li oru yi li a o bère ẹmi rẹ lọwọ rẹ: njẹ titani nkan wọnni yio ha ṣe, ti iwọ ti pèse silẹ?
Kà Luk 12
Feti si Luk 12
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Luk 12:13-20
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò