Lef 9:7-24

Lef 9:7-24 YBCV

Mose si sọ fun Aaroni pe, Sunmọ pẹpẹ, ki o si ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ rẹ, ati ẹbọ sisun rẹ, ki o si ṣètutu fun ara rẹ, ati fun awọn enia: ki o si ru ọrẹ-ẹbọ awọn enia, ki o si ṣètutu fun wọn; bi OLUWA ti fi aṣẹ lelẹ. Aaroni si sunmọ pẹpẹ, o si pa ọmọ malu ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ti iṣe ti on tikalarẹ̀. Awọn ọmọ Aaroni si mú ẹ̀jẹ na tọ̀ ọ wá: o si tẹ̀ iká rẹ̀ bọ̀ inu ẹ̀jẹ na, o si tọ́ ọ sara iwo pẹpẹ, o si dà ẹ̀jẹ na si isalẹ pẹpẹ: Ṣugbọn ọrá, ati iwe, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ ti ẹbọ ẹ̀ṣẹ, o sun u lori pẹpẹ; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. Ati ẹran ati awọ li o fi iná sun lẹhin ibudó. O si pa ẹbọ sisun: awọn ọmọ Aaroni si mú ẹ̀jẹ rẹ̀ tọ̀ ọ wá, o si fi i wọ́n ori pẹpẹ yiká. Nwọn si mú ẹbọ sisun tọ̀ ọ wá, ti on ti ipín rẹ̀, ati ori: o si sun wọn lori pẹpẹ. O si ṣìn ifun ati itan rẹ̀, o si sun wọn li ẹbọ sisun lori pẹpẹ. O si mú ọrẹ-ẹbọ awọn enia wá, o si mú obukọ, ti iṣe ẹbọ ẹ̀ṣẹ fun awọn enia, o si pa a, o si fi i rubọ ẹ̀ṣẹ, bi ti iṣaju. O si mú ẹbọ sisun wá, o si ru u gẹgẹ bi ìlana na. O si mú ẹbọ ohunjijẹ wá, o si bù ikunwọ kan ninu rẹ̀, o si sun u lori pẹpẹ, pẹlu ẹbọ sisun owurọ̀. O si pa akọmalu ati àgbo fun ẹbọ alafia, ti iṣe ti awọn enia; awọn ọmọ Aaroni si mú ẹ̀jẹ na tọ̀ ọ wá, o si fi i wọ́n ori pẹpẹ yiká. Ati ọrá inu akọmalu na ati ti inu àgbo na, ìru rẹ̀ ti o lọrá, ati eyiti o bò ifun, ati iwe, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ: Nwọn si fi ọrá na lé ori igẹ̀ wọnni, o si sun ọrà na lori pẹpẹ. Ati igẹ̀ na ati itan ọtún ni Aaroni fì li ẹbọ fifì niwaju OLUWA; bi Mose ti fi aṣẹ lelẹ. Aaroni si gbé ọwọ́ rẹ̀ soke si awọn enia, o si sure fun wọn; o si sọkalẹ kuro ni ibi irubọ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ẹbọ sisun, ati ẹbọ alafia. Mose ati Aaroni si wọ̀ inu agọ́ ajọ, nwọn si jade, nwọn si sure fun awọn enia: ogo OLUWA si farahàn fun gbogbo enia. Iná kan si ti ọdọ OLUWA jade wá, o si jó ẹbọ sisun ati ọrá ori pẹpẹ na; nigbati gbogbo awọn enia ri i, nwọn hó kùhu, nwọn si dojubolẹ.