Lef 9:7-24

Lef 9:7-24 Bibeli Mimọ (YBCV)

Mose si sọ fun Aaroni pe, Sunmọ pẹpẹ, ki o si ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ rẹ, ati ẹbọ sisun rẹ, ki o si ṣètutu fun ara rẹ, ati fun awọn enia: ki o si ru ọrẹ-ẹbọ awọn enia, ki o si ṣètutu fun wọn; bi OLUWA ti fi aṣẹ lelẹ. Aaroni si sunmọ pẹpẹ, o si pa ọmọ malu ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ti iṣe ti on tikalarẹ̀. Awọn ọmọ Aaroni si mú ẹ̀jẹ na tọ̀ ọ wá: o si tẹ̀ iká rẹ̀ bọ̀ inu ẹ̀jẹ na, o si tọ́ ọ sara iwo pẹpẹ, o si dà ẹ̀jẹ na si isalẹ pẹpẹ: Ṣugbọn ọrá, ati iwe, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ ti ẹbọ ẹ̀ṣẹ, o sun u lori pẹpẹ; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose. Ati ẹran ati awọ li o fi iná sun lẹhin ibudó. O si pa ẹbọ sisun: awọn ọmọ Aaroni si mú ẹ̀jẹ rẹ̀ tọ̀ ọ wá, o si fi i wọ́n ori pẹpẹ yiká. Nwọn si mú ẹbọ sisun tọ̀ ọ wá, ti on ti ipín rẹ̀, ati ori: o si sun wọn lori pẹpẹ. O si ṣìn ifun ati itan rẹ̀, o si sun wọn li ẹbọ sisun lori pẹpẹ. O si mú ọrẹ-ẹbọ awọn enia wá, o si mú obukọ, ti iṣe ẹbọ ẹ̀ṣẹ fun awọn enia, o si pa a, o si fi i rubọ ẹ̀ṣẹ, bi ti iṣaju. O si mú ẹbọ sisun wá, o si ru u gẹgẹ bi ìlana na. O si mú ẹbọ ohunjijẹ wá, o si bù ikunwọ kan ninu rẹ̀, o si sun u lori pẹpẹ, pẹlu ẹbọ sisun owurọ̀. O si pa akọmalu ati àgbo fun ẹbọ alafia, ti iṣe ti awọn enia; awọn ọmọ Aaroni si mú ẹ̀jẹ na tọ̀ ọ wá, o si fi i wọ́n ori pẹpẹ yiká. Ati ọrá inu akọmalu na ati ti inu àgbo na, ìru rẹ̀ ti o lọrá, ati eyiti o bò ifun, ati iwe, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ: Nwọn si fi ọrá na lé ori igẹ̀ wọnni, o si sun ọrà na lori pẹpẹ. Ati igẹ̀ na ati itan ọtún ni Aaroni fì li ẹbọ fifì niwaju OLUWA; bi Mose ti fi aṣẹ lelẹ. Aaroni si gbé ọwọ́ rẹ̀ soke si awọn enia, o si sure fun wọn; o si sọkalẹ kuro ni ibi irubọ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ẹbọ sisun, ati ẹbọ alafia. Mose ati Aaroni si wọ̀ inu agọ́ ajọ, nwọn si jade, nwọn si sure fun awọn enia: ogo OLUWA si farahàn fun gbogbo enia. Iná kan si ti ọdọ OLUWA jade wá, o si jó ẹbọ sisun ati ọrá ori pẹpẹ na; nigbati gbogbo awọn enia ri i, nwọn hó kùhu, nwọn si dojubolẹ.

Lef 9:7-24 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn náà, Mose sọ fún Aaroni pé, “Súnmọ́ ibi pẹpẹ, kí o sì rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, ati ẹbọ sísun rẹ, kí o sì ṣe ètùtù fún ara rẹ ati fún àwọn eniyan náà. Gbé ẹbọ àwọn eniyan náà wá, kí o sì ṣe ètùtù fún wọn, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ.” Aaroni bá súnmọ́ ibi pẹpẹ náà, ó pa ọ̀dọ́ mààlúù fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀. Àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá fún un, ó sì ti ìka bọ̀ ọ́, ó fi kan ara ìwo pẹpẹ, ó sì da ẹ̀jẹ̀ yòókù sí ìdí pẹpẹ. Ó mú ọ̀rá ọ̀dọ́ mààlúù náà, ati àwọn kíndìnrín rẹ̀ ati ẹ̀dọ̀ rẹ̀ kúrò ninu ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ó sun wọ́n lórí pẹpẹ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. Ó sì dáná sun ẹran ati awọ mààlúù náà lẹ́yìn ibùdó. Ó pa ẹran ẹbọ sísun, àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ, ó sì dà á sí ara pẹpẹ yípo. Wọ́n gbé ẹran ẹbọ sísun tí wọ́n ti gé sí wẹ́wẹ́, ati orí rẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ, ó sì sun wọ́n lórí pẹpẹ. Ó fọ àwọn nǹkan inú rẹ̀, ati ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì sun wọ́n papọ̀ pẹlu ẹbọ sísun lórí pẹpẹ. Lẹ́yìn náà ó fa ẹran ẹbọ sísun àwọn eniyan náà kalẹ̀, ó mú ewúrẹ́ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan náà, ó pa á, ó sì fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ti àkọ́kọ́. Ó gbé ẹran ẹbọ sísun wá, ó sì fi rúbọ gẹ́gẹ́ bí ìlànà. Ó gbé ẹbọ ohun jíjẹ wá, ó bu ẹ̀kúnwọ́ kan ninu rẹ̀, ó sì sun ún lórí pẹpẹ ní ẹ̀gbẹ́ ẹbọ sísun ti òwúrọ̀. Ó pa akọ mààlúù ati àgbò ẹbọ alaafia fún àwọn eniyan, àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, ó sì dà á sórí pẹpẹ náà yípo. Ó mú ọ̀rá akọ mààlúù, ati ti àgbò náà, pẹlu ìrù wọn tí ó lọ́ràá, ati ọ̀rá tí ó bo àwọn nǹkan inú wọn, ati kíndìnrín ati ẹ̀dọ̀ wọn. Ó kó gbogbo ọ̀rá náà lé orí igẹ̀ ẹran náà; ó sun ún lórí pẹpẹ. Ṣugbọn ó mú àwọn igẹ̀ ẹran náà ati itan ọ̀tún wọn, ó fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA, bí Mose ti pa á láṣẹ. Lẹ́yìn náà, Aaroni kọjú sí àwọn eniyan náà, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó sì súre fún wọn. Lẹ́yìn náà, ó sọ̀kalẹ̀ láti ibi tí ó ti ń rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia. Mose ati Aaroni bá wọ inú Àgọ́ Àjọ lọ. Nígbà tí wọ́n jáde, wọ́n súre fún àwọn eniyan náà, ògo OLUWA sì yọ sí gbogbo wọn. Lójijì, iná ṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ OLUWA wá, ó jó ẹbọ sísun náà, ati ọ̀rá tí ó wà lórí pẹpẹ. Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan rí i, wọ́n kígbe sókè, wọ́n sì dojúbolẹ̀.

Lef 9:7-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Mose sọ fún Aaroni pé, “Wá sí ibi pẹpẹ kí o sì rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti ẹbọ sísun rẹ, kí o sì ṣe ètùtù fún ara rẹ àti fún àwọn ènìyàn; rú ẹbọ ti àwọn ènìyàn náà, kí o sì ṣe ètùtù fún wọn gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti pa á láṣẹ.” Aaroni sì wá sí ibi pẹpẹ, ó pa akọ ọmọ màlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀. Àwọn ọmọ Aaroni sì mú ẹ̀jẹ̀ náà tọ̀ ọ́ wá, ó sì ti ìka ọwọ́ rẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà, ó fi sí orí ìwo pẹpẹ, ó sì da ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ. Ó sun ọ̀rá, kíndìnrín àti ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, èyí tó mú láti inú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, lórí pẹpẹ bí OLúWA ti pa á láṣẹ fún Mose. Ó sì sun ara ẹran àti awọ rẹ̀ ní ẹ̀yìn ibùdó. Lẹ́yìn èyí ó pa ẹran tó wà fún ẹbọ sísun. Àwọn ọmọ Aaroni sì mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, ó sì wọn yí pẹpẹ náà ká. Wọ́n sì ń mú ẹbọ sísun náà fún un ní ègé kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú orí rẹ̀, ó sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ. Ó fọ nǹkan inú rẹ̀ àti ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sun wọ́n lórí ẹbọ sísun tó wà lórí pẹpẹ. Aaroni mú ẹbọ tó jẹ́ ti àwọn ènìyàn wá. Ó mú òbúkọ èyí tó dúró fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn ó sì pa á, ó fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ti àkọ́kọ́. Ó mú ẹbọ sísun wá, ó sì rú u gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí a fi lélẹ̀. Ó tún mu ẹbọ ohun jíjẹ wá, ó bu ẹ̀kúnwọ́ kan nínú rẹ̀, ó sì sun ún lórí pẹpẹ ní àfikún ẹbọ sísun tí àárọ̀. Ó pa akọ màlúù àti àgbò bí ẹbọ àlàáfíà fún àwọn ènìyàn. Àwọn ọmọ Aaroni sì mú ẹ̀jẹ̀ ẹran náà tọ̀ ọ́ wá, ó sì wọn yí pẹpẹ náà ká. Ṣùgbọ́n ọ̀rá akọ màlúù àti àgbò náà: ìrù rẹ̀ tí ó lọ́ràá, básí ọ̀rá, ọ̀rá kíndìnrín, àti ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀: gbogbo rẹ̀ ni wọ́n kó lórí igẹ̀ ẹran náà. Aaroni sì sun ọ̀rá náà lórí pẹpẹ. Aaroni fi igẹ̀ àti itan ọ̀tún ẹran náà níwájú OLúWA gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì bí Mose ṣe pa á láṣẹ. Aaroni sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí àwọn ènìyàn, ó sì súre fún wọn. Lẹ́yìn tó sì ti rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ sísun àti ẹbọ àlàáfíà, ó sọ̀kalẹ̀. Mose àti Aaroni sì wọ inú àgọ́ ìpàdé. Nígbà tí wọ́n jáde, wọ́n súre fún àwọn ènìyàn, ògo OLúWA sì farahàn sí gbogbo ènìyàn, Iná sì jáde láti ọ̀dọ̀ OLúWA, ó sì jó ẹbọ sísun àti ọ̀rá orí pẹpẹ. Nígbà tí gbogbo ènìyàn sì rí èyí wọ́n hó ìhó ayọ̀, wọ́n sì dojúbolẹ̀.