Lef 27:14-34

Lef 27:14-34 YBCV

Bi enia kan yio ba si yà ile rẹ̀ sọtọ̀ lati jẹ́ mimọ́ fun OLUWA, njẹ ki alufa ki o diyelé e, ibaṣe rere tabi buburu: bi alufa ba ti diyelé e, bẹ̃ni ki o ri. Ati bi ẹniti o yà a sọ̀tọ ba nfẹ́ rà ile rẹ̀ pada, njẹ ki o fi idamarun owo idiyelé rẹ̀ kún u, yio si jẹ́ tirẹ̀. Bi enia kan ba si nfẹ́ yà ninu oko ti o jogún sọ̀tọ fun OLUWA, njẹ ki idiyelé rẹ ki o jẹ́ bi irugbìn rẹ̀: òṣuwọn homeri irugbìn barle kan ãdọta ṣekeli fadakà. Bi o ba yà oko rẹ̀ sọ̀tọ lati ọdún jubeli wá, gẹgẹ bi idiyelé rẹ bẹ̃ni ki o ri. Ṣugbọn bi o ba yà oko rẹ̀ sọtọ̀ lẹhin ọdún jubeli, njẹ ki alufa ki o ṣìro owo rẹ̀ fun u, gẹgẹ bi ìwọn ọdún ti o kù, titi di ọdún jubeli, a o si din i kù ninu idiyelé rẹ. Ati bi ẹniti o yà oko na sọtọ̀ ba fẹ́ rà a pada, njẹ ki o fi idamarun owo idiyelé rẹ kún u, yio si jẹ́ tirẹ̀. Bi on kò ba si fẹ́ rà oko na pada, tabi bi o ba ti tà oko na fun ẹlomiran, ki a máṣe rà a pada mọ́. Ṣugbọn oko na, nigbati o ba yọ li ọdún jubeli, ki o jẹ́ mimọ́ fun OLUWA, bi oko ìya-sọtọ; iní rẹ̀ yio jẹ́ ti alufa. Ati bi ẹnikan ba yà oko kan sọ̀tọ fun OLUWA ti on ti rà, ti ki iṣe ninu oko ti o jogún; Njẹ ki alufa ki o ṣìro iye idiyelé rẹ̀ fun u, titi di ọdún jubeli: ki on ki o si fi idiyelé rẹ li ọjọ́ na, bi ohun mimọ́ fun OLUWA. Li ọdún jubeli ni ki oko na ki o pada sọdọ ẹniti o rà a, ani sọdọ rẹ̀ ti ẹniti ini ilẹ na iṣe. Ki gbogbo idiyelé rẹ ki o si jẹ́ gẹgẹ bi ṣekeli ibi mimọ́: ogún gera ni ṣekeli kan. Kìki akọ́bi ẹran, ti iṣe akọ́bi ti OLUWA, li ẹnikan kò gbọdọ yàsọtọ; ibaṣe akọmalu, tabi agutan: ti OLUWA ni. Bi o ba ṣe ti ẹran alaimọ́ ni, njẹ ki o gbà a silẹ gẹgẹ bi idiyelé rẹ, ki o si fi idamarun rẹ̀ kún u: tabi bi kò ba si rà a pada, njẹ ki a tà a, gẹgẹ bi idiyelé rẹ. Ṣugbọn kò sí ohun ìyasọtọ kan, ti enia ba yàsọtọ fun OLUWA ninu ohun gbogbo ti o ní, ati enia, ati ẹran, ati ilẹ-iní rẹ̀, ti a gbọdọ tà tabi ti a gbọdọ rà pada: ohun gbogbo ti a ba yàsọtọ mimọ́ julọ ni si OLUWA. Kò sí ẹni ìyasọtọ ti a ba yàsọtọ ninu enia, ti a le gbàsilẹ; pipa ni ki a pa a. Ati gbogbo idamẹwa ilẹ na ibaṣe ti irugbìn ilẹ na, tabi ti eso igi, ti OLUWA ni: mimọ́ ni fun OLUWA. Bi o ba ṣepe enia ba ràpada rára ninu ohun idamẹwa rẹ̀, ki o si fi idamarun kún u. Ati gbogbo idamẹwa ọwọ́ ẹran, tabi ti agbo-ẹran, ani ohunkohun ti o ba kọja labẹ ọpá, ki ẹkẹwa ki o jẹ́ mimọ́ fun OLUWA. Ki o máṣe yẹ̀ ẹ wò bi o jẹ́ rere tabi buburu, bẹ̃li on kò gbọdọ pàrọ rẹ̀: bi o ba si ṣepe o pàrọ rẹ̀ rára, njẹ ati on ati ipàrọ rẹ̀ yio jẹ́ mimọ́; a kò gbọdọ rà a pada. Wọnyi li ofin, ti OLUWA palaṣẹ fun Mose fun awọn ọmọ Israeli li òke Sinai.