Lef 27:14-34
Lef 27:14-34 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi enia kan yio ba si yà ile rẹ̀ sọtọ̀ lati jẹ́ mimọ́ fun OLUWA, njẹ ki alufa ki o diyelé e, ibaṣe rere tabi buburu: bi alufa ba ti diyelé e, bẹ̃ni ki o ri. Ati bi ẹniti o yà a sọ̀tọ ba nfẹ́ rà ile rẹ̀ pada, njẹ ki o fi idamarun owo idiyelé rẹ̀ kún u, yio si jẹ́ tirẹ̀. Bi enia kan ba si nfẹ́ yà ninu oko ti o jogún sọ̀tọ fun OLUWA, njẹ ki idiyelé rẹ ki o jẹ́ bi irugbìn rẹ̀: òṣuwọn homeri irugbìn barle kan ãdọta ṣekeli fadakà. Bi o ba yà oko rẹ̀ sọ̀tọ lati ọdún jubeli wá, gẹgẹ bi idiyelé rẹ bẹ̃ni ki o ri. Ṣugbọn bi o ba yà oko rẹ̀ sọtọ̀ lẹhin ọdún jubeli, njẹ ki alufa ki o ṣìro owo rẹ̀ fun u, gẹgẹ bi ìwọn ọdún ti o kù, titi di ọdún jubeli, a o si din i kù ninu idiyelé rẹ. Ati bi ẹniti o yà oko na sọtọ̀ ba fẹ́ rà a pada, njẹ ki o fi idamarun owo idiyelé rẹ kún u, yio si jẹ́ tirẹ̀. Bi on kò ba si fẹ́ rà oko na pada, tabi bi o ba ti tà oko na fun ẹlomiran, ki a máṣe rà a pada mọ́. Ṣugbọn oko na, nigbati o ba yọ li ọdún jubeli, ki o jẹ́ mimọ́ fun OLUWA, bi oko ìya-sọtọ; iní rẹ̀ yio jẹ́ ti alufa. Ati bi ẹnikan ba yà oko kan sọ̀tọ fun OLUWA ti on ti rà, ti ki iṣe ninu oko ti o jogún; Njẹ ki alufa ki o ṣìro iye idiyelé rẹ̀ fun u, titi di ọdún jubeli: ki on ki o si fi idiyelé rẹ li ọjọ́ na, bi ohun mimọ́ fun OLUWA. Li ọdún jubeli ni ki oko na ki o pada sọdọ ẹniti o rà a, ani sọdọ rẹ̀ ti ẹniti ini ilẹ na iṣe. Ki gbogbo idiyelé rẹ ki o si jẹ́ gẹgẹ bi ṣekeli ibi mimọ́: ogún gera ni ṣekeli kan. Kìki akọ́bi ẹran, ti iṣe akọ́bi ti OLUWA, li ẹnikan kò gbọdọ yàsọtọ; ibaṣe akọmalu, tabi agutan: ti OLUWA ni. Bi o ba ṣe ti ẹran alaimọ́ ni, njẹ ki o gbà a silẹ gẹgẹ bi idiyelé rẹ, ki o si fi idamarun rẹ̀ kún u: tabi bi kò ba si rà a pada, njẹ ki a tà a, gẹgẹ bi idiyelé rẹ. Ṣugbọn kò sí ohun ìyasọtọ kan, ti enia ba yàsọtọ fun OLUWA ninu ohun gbogbo ti o ní, ati enia, ati ẹran, ati ilẹ-iní rẹ̀, ti a gbọdọ tà tabi ti a gbọdọ rà pada: ohun gbogbo ti a ba yàsọtọ mimọ́ julọ ni si OLUWA. Kò sí ẹni ìyasọtọ ti a ba yàsọtọ ninu enia, ti a le gbàsilẹ; pipa ni ki a pa a. Ati gbogbo idamẹwa ilẹ na ibaṣe ti irugbìn ilẹ na, tabi ti eso igi, ti OLUWA ni: mimọ́ ni fun OLUWA. Bi o ba ṣepe enia ba ràpada rára ninu ohun idamẹwa rẹ̀, ki o si fi idamarun kún u. Ati gbogbo idamẹwa ọwọ́ ẹran, tabi ti agbo-ẹran, ani ohunkohun ti o ba kọja labẹ ọpá, ki ẹkẹwa ki o jẹ́ mimọ́ fun OLUWA. Ki o máṣe yẹ̀ ẹ wò bi o jẹ́ rere tabi buburu, bẹ̃li on kò gbọdọ pàrọ rẹ̀: bi o ba si ṣepe o pàrọ rẹ̀ rára, njẹ ati on ati ipàrọ rẹ̀ yio jẹ́ mimọ́; a kò gbọdọ rà a pada. Wọnyi li ofin, ti OLUWA palaṣẹ fun Mose fun awọn ọmọ Israeli li òke Sinai.
Lef 27:14-34 Yoruba Bible (YCE)
“Nígbà tí ẹnìkan bá ya ilé rẹ̀ sọ́tọ̀ fún OLUWA, alufaa yóo wò ó bóyá ó dára tabi kò dára; iyekíye tí alufaa bá pè é ni iye rẹ̀. Bí ẹni tí ó ya ilé yìí sọ́tọ̀ fún OLUWA bá fẹ́ rà á pada, yóo san iye tí ilé náà bá tó, yóo sì tún fi ìdámárùn-ún iye owó rẹ̀ lé e. Nígbà tí ó bá san owó ilé náà pada, ilé yóo di tirẹ̀. “Bí ẹnìkan bá ya apá kan ninu ilẹ̀ tí ó jogún sọ́tọ̀ fún OLUWA, ìwọ̀n èso tí eniyan bá lè rí ká lórí ilẹ̀ náà ni wọn yóo fi díye lé e. Bí a bá lè rí ìwọ̀n Homeri baali kan ká ninu rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, iye rẹ̀ yóo jẹ́ aadọta ìwọ̀n ṣekeli fadaka. Bí ó bá jẹ́ pé láti ọdún jubili ni ó ti ya ilẹ̀ náà sọ́tọ̀ fún OLUWA, iyekíye tí ilẹ̀ náà bá tó lójú yín kò gbọdọ̀ dín. Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé lẹ́yìn ọdún Jubili ni ó ya ilẹ̀ rẹ̀ sọ́tọ̀ fún OLUWA, alufaa yóo ṣírò iye tí ó tó, gẹ́gẹ́ bí iye ọdún tí ó kù kí ọdún Jubili mìíràn pé bá ti pẹ́ sí, ẹ óo ṣí iye owó ọdún tí ó dínkù kúrò lára iye ilẹ̀ náà. Bí ẹni tí ó ya ilẹ̀ náà sọ́tọ̀ fún OLUWA bá fẹ́ rà á pada, yóo san iye tí ó bá tó, yóo sì fi ìdámárùn-ún owó rẹ̀ lé e, ilẹ̀ náà yóo sì di tirẹ̀. Ṣugbọn bí kò bá fẹ́ ra ilẹ̀ náà pada, tabi ti ó bá ti ta ilẹ̀ náà fún ẹlòmíràn, kò ní ẹ̀tọ́ láti rà á pada mọ́. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n bá jọ̀wọ́ ilẹ̀ náà ní ọdún Jubili, ó níláti jẹ́ mímọ́ fún OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ tí wọ́n ti fi fún OLUWA; yóo sì di ohun ìní alufaa. “Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé rírà ni ó ra ilẹ̀ tí ó yà sọ́tọ̀ fún OLUWA, tí kì í ṣe apá kan ninu ilẹ̀ àjogúnbá tirẹ̀, alufaa yóo ṣírò iye tí ilẹ̀ náà bá tó títí di ọdún Jubili, ẹni náà yóo sì san iye rẹ̀ ní ọjọ́ náà bí ohun ìyàsọ́tọ̀ fún OLUWA. Nígbà tí ó bá di ọdún Jubili, ilẹ̀ yìí yóo pada di ti ẹni tí wọ́n rà á lọ́wọ́ rẹ̀, tí ilẹ̀ yìí jẹ́ ilẹ̀ àjogúnbá rẹ̀ láàárọ̀ ọjọ́. “Ìwọ̀n ṣekeli tí wọn ń lò ninu ibi mímọ́ ni kí ẹ máa lò láti wọn ohun gbogbo: Ogún ìwọ̀n gera ni yóo jẹ́ ìwọ̀n ṣekeli kan. “Ṣugbọn gbogbo ẹran tí ó bá ti jẹ́ àkọ́bí, ti OLUWA ni, ẹnikẹ́ni kò ṣẹ̀ṣẹ̀ tún ní yà á sọ́tọ̀ mọ́; kì báà jẹ́ mààlúù tabi aguntan, ti OLUWA ni. Bí ó bá jẹ́ ẹran tí kò mọ́, kí ó san owó rẹ̀ pada gẹ́gẹ́ bí iye tí ẹ bá dá lé e, kí ó sì fi ìdámárùn-ún owó náà lé e. Bí ẹni tí ó ni í kò bá sì rà á pada, kí wọ́n tà á ní iyekíye tí ẹ bá dá lé e. “Ṣugbọn ohunkohun tí eniyan bá ti fi fún OLUWA, kì báà jẹ́ eniyan ni, tabi ẹranko, tabi ilẹ̀ àjogúnbá rẹ̀, yóo jẹ́ títà tabi kí ó rà á pada. Ohunkohun tí a bá ti fi fún OLUWA, ó di mímọ́ jùlọ fún OLUWA. Ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá yà sọ́tọ̀ pé ó gbọdọ̀ jẹ́ pípa láàrin àwọn eniyan, ẹnìkan kò gbọdọ̀ rà á pada, pípa ni wọ́n gbọdọ̀ pa á. “Gbogbo ìdámẹ́wàá ilẹ̀ náà, kì báà jẹ́ ti èso ilẹ̀, tabi ti èso igi, ti OLUWA ni; mímọ́ ni fún OLUWA. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ra ìdámẹ́wàá rẹ̀ pada, ó níláti fi ìdámárùn-ún ìdámẹ́wàá yìí lé e. Ìdámẹ́wàá gbogbo agbo mààlúù, ati ti agbo aguntan jẹ́ ti OLUWA. Bí ẹran mẹ́wàá bá kọjá lábẹ́ ọ̀pá darandaran, ikẹwaa gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún OLUWA. Darandaran náà kò gbọdọ̀ bèèrè bóyá ó dára tabi kò dára, bẹ́ẹ̀ ni kò sì gbọdọ̀ pààrọ̀ rẹ̀. Bí ó bá fẹ́ pààrọ̀ rẹ̀, ati èyí tí ó fi pààrọ̀ ati èyí tí ó pààrọ̀, mejeeji jẹ́ mímọ́ fún OLUWA, ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ rà á pada.” Àwọn òfin tí a ti kà sílẹ̀ wọnyi ni OLUWA fún Mose lórí Òkè Sinai fún àwọn ọmọ Israẹli.
Lef 27:14-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá ya ilẹ̀ rẹ̀ sí mímọ́ fún OLúWA: kí àlùfáà kó sọ iye tí yóò san gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ náà ti dára tàbí bàjẹ́ sí: iye owó náà ni kí ó jẹ́. Bí ẹni tí ó yá ilé náà sí mímọ́ bá fẹ́ rà á padà. Jẹ́ kí ó fi ìdámárùn-ún owó ìdíyelé rẹ̀ kún ún, yóò si jẹ́ tirẹ̀. “ ‘Bí ẹnìkan bá sì ya ara ilẹ̀ ìdílé rẹ̀ sí mímọ́ fún OLúWA. Iye tí ó bá jẹ́ ni kí wọ́n ṣètò gẹ́gẹ́ bí iye èso tí a ó fi gbìn ín. Àádọ́ta ṣékélì fàdákà fún òṣùwọ̀n homeri irúgbìn barle. Bí ó ba ṣe pé ní ọdún ìdásílẹ̀ ni ó ya ilẹ̀ náà sí mímọ́. Iye owó tí wọn sọtẹ́lẹ̀ náà ni kí o san. Bí ó bá ya ilẹ̀ náà sí mímọ́ lẹ́yìn ọdún ìdásílẹ̀ kí àlùfáà sọ iye owó tí yóò san fún ọdún tókù kí ọdún ìdásílẹ̀ mìíràn tó pé iye owó tí ó gbọdọ̀ jẹ yóò dínkù. Bí ẹni tí ó ya ilẹ̀ sí mímọ́ bá fẹ́ rà á padà: kí ó san iye owó náà pẹ̀lú àfikún ìdámárùn-ún. Ilẹ̀ náà yóò sì di tirẹ̀. Bí kò bá ra ilẹ̀ náà padà tàbí bí ó bá tà á fún ẹlòmíràn kò le è ri rà padà mọ́. Bí a bá fi ilẹ̀ náà sílẹ̀ ní ọdún ìdásílẹ̀ yóò di mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ tí a fi fún OLúWA. Yóò sì di ohun ìní àlùfáà. “ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá ya ilẹ̀ tí ó ti rà tí kì í ṣe ilẹ̀ ìdílé rẹ̀ sí mímọ́ fún OLúWA. Kí àlùfáà sọ iye tí ó tọ títí di ọdún ìdásílẹ̀. Kí ọkùnrin náà sì san iye owó náà ní ọjọ́ náà gẹ́gẹ́ bí ohun mímọ́ sí OLúWA. Ní ọdún ìdásílẹ̀ ilẹ̀ náà yóò padà di ti ẹni tí ó ni í, lọ́wọ́ ẹni tí a ti rà á. Gbogbo iye owó wọ̀nyí gbọdọ̀ wà ní ìbámu pẹ̀lú ṣékélì ibi mímọ́, ogún gera. “ ‘Kò sí ẹni tí ó gbọdọ̀ ya gbogbo àkọ́bí ẹran sọ́tọ̀. Èyí jẹ́ ti OLúWA nípasẹ̀ òfin àkọ́bí: yálà akọ màlúù ni tàbí àgùntàn, ti OLúWA ni. Bí ó bá jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹran tí kò mọ́, nígbà náà ni kí ó rà á padà gẹ́gẹ́ bí ìdíyelé rẹ̀, kí ó sì fi ìdámárùn-ún lé e, tàbí bí a kò bá rà á padà kí ẹ tà á gẹ́gẹ́ bí ìdíyelé rẹ̀. “ ‘Ohun tí a bá yà sí mímọ́ pátápátá láti ọwọ́ ẹnikẹ́ni sí OLúWA tàbí ẹranko tàbí ilẹ̀ tí ó jogún: òun kò gbọdọ̀ tà á kí ó rà á padà. Gbogbo ohun ìyàsọ́tọ̀ bẹ́ẹ̀ di mímọ́ jùlọ fún OLúWA. “ ‘Ẹni tí ẹ bá ti yà sọ́tọ̀ fún pípa, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ rà á padà, pípa ni kí ẹ pa á. “ ‘Gbogbo ìdámẹ́wàá ilẹ̀ náà yálà tí èso ilẹ̀ ni, tàbí tí èso igi, ti OLúWA ni. Mímọ́ ni fún OLúWA. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ra ìdámẹ́wàá nǹkan rẹ̀ padà: o gbọdọ̀ fi márùn-ún kún un. Gbogbo ìdámẹ́wàá àgbò àti ẹran ọ̀sìn, àní ìdámẹ́wàá ẹran tó bá kọjá lábẹ́ ọ̀pá darandaran kí ó jẹ́ mímọ́ fún OLúWA. Ènìyàn kò gbọdọ̀ wádìí bóyá ó dára tàbí kò dára, kò sì gbọdọ̀ pààrọ̀ rẹ̀. Bí ó bá pààrọ̀ rẹ̀: àti èyí tí ó pààrọ̀ àti èyí tí ó fi pààrọ̀ ni kí ó jẹ́ mímọ́. Wọn kò gbọdọ̀ rà á padà.’ ” Àwọn àṣẹ wọ̀nyí ni OLúWA pa fún Mose fún àwọn ọmọ Israẹli ní orí òkè Sinai.