Lef 25:47-55

Lef 25:47-55 YBCV

Ati bi alejò tabi atipo kan ba di ọlọrọ̀ lọdọ rẹ, ati arakunrin rẹ kan leti ọdọ rẹ̀ ba di talakà, ti o ba si tà ara rẹ̀ fun alejò tabi atipo na leti ọdọ rẹ, tabi fun ibatan idile alejò na: Lẹhin igbati o tà ara rẹ̀ tán, a si tún le rà a pada; ọkan ninu awọn arakunrin rẹ̀ le rà a: Ibaṣe arakunrin õbi rẹ̀, tabi ọmọ arakunrin õbi rẹ̀, le rà a, tabi ibatan rẹ̀ ninu idile rẹ̀ le rà a; tabi bi o ba di ọlọrọ̀, o le rà ara rẹ̀. Ki o si ba ẹniti o rà a ṣìro lati ọdún ti o ti tà ara rẹ̀ fun u titi di ọdún jubeli: ki iye owo ìta rẹ̀ ki o si ri gẹgẹ bi iye ọdún, gẹgẹ bi ìgba alagbaṣe ni ki o ri fun u. Bi ọdún rẹ̀ ba kù pupọ̀ sibẹ̀, gẹgẹ bi iye wọn ni ki o si san owo ìrasilẹ rẹ̀ pada ninu owo ti a fi rà a. Bi o ba si ṣepe kìki ọdún diẹ li o kù titi di ọdún jubeli, njẹ ki o ba a ṣìro, gẹgẹ bi iye ọdún rẹ̀ ni ki o san owo ìrasilẹ rẹ̀ pada. Bi alagbaṣe ọdọdún ni ki o ma ba a gbé: ki on ki o máṣe fi irorò sìn i li oju rẹ. Bi a kò ba si fi wọnyi rà a silẹ, njẹ ki o jade lọ li ọdún jubeli, ati on, ati awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀. Nitoripe iranṣẹ mi li awọn ọmọ Israeli iṣe; iranṣẹ mi ni nwọn ti mo mú lati ilẹ Egipti jade wá: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.