Lef 25:47-55

Lef 25:47-55 Yoruba Bible (YCE)

“Bí àlejò tí ó wà láàrin yín bá di ọlọ́rọ̀ tí arakunrin rẹ̀ tí ó jẹ́ aládùúgbò rẹ̀ sì di aláìní, tí ó sì ta ara rẹ̀ fún àlejò náà, tabi fún ọ̀kan ninu ìdílé àlejò yín, lẹ́yìn tí ó bá ti ta ara rẹ̀, wọ́n lè rà á pada: ọ̀kan ninu àwọn arakunrin rẹ̀ lè rà á pada. Arakunrin baba tabi ìyá rẹ̀, tabi ọ̀kan ninu àwọn ìbátan rẹ̀ tabi ẹnìkan ninu àwọn ẹbí rẹ̀ le rà á pada. Bí òun pàápàá bá sì di ọlọ́rọ̀, ó lè ra ara rẹ̀ pada. Kí òun ati ẹni tí ó rà á jọ ṣírò iye ọdún tí ó fi ta ara rẹ̀, láti ọdún tí ó ti ta ara rẹ̀ fún un títí di ọdún jubili. Iye ọdún tí ó bá kù ni wọn yóo fi ṣírò owó ìràpadà rẹ̀. Wọn yóo ṣírò àkókò tí ó ti lò lọ́dọ̀ olówó rẹ̀ bí àkókò tí alágbàṣe wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Bí iye ọdún tí ó kù bá pọ̀, yóo ṣírò iye tí owó ìràpadà rẹ̀ kù ninu iye tí wọ́n san lórí rẹ̀, yóo sì san án pada. Bí ọdún tí ó kù tí ọdún jubili yóo fi pé kò bá pọ̀ mọ́, wọn yóo jọ ṣírò iye ọdún tí ó kù fún un láti fi sìn ín, òun ni yóo sì fi ṣírò owó ìràpadà rẹ̀ tí ó kù tí yóo san. Ọkunrin tí ó ta ara rẹ̀ yìí yóo dàbí iranṣẹ tí à ń gbà lọdọọdun sí ẹni tí ó rà á; ẹni tí ó rà á kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ líle mú un lójú rẹ̀. Bí ẹnikẹ́ni kò bá ra ẹni náà pada lọ́nà tí a ti là sílẹ̀ wọnyi, wọ́n gbọdọ̀ dá òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ sílẹ̀ nígbà tí ó bá di ọdún jubili. Nítorí pé, iranṣẹ mi ni àwọn ọmọ Israẹli jẹ́, iranṣẹ mi tí mo kó jáde láti ilẹ̀ Ijipti ni wọ́n. Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ.

Lef 25:47-55 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“ ‘Bí àlejò kan láàrín yín tàbí ẹni tí ń gbé àárín yín fún ìgbà díẹ̀ bá lọ́rọ̀ tí ọmọ Israẹli sì tálákà dé bi pé ó ta ara rẹ̀ lẹ́rú fún àlejò tàbí ìdílé àlejò náà. Ó lẹ́tọ̀ọ́ si ki a rà á padà lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ta ara rẹ̀. Ọ̀kan nínú ìbátan rẹ̀ le è rà á padà. Àbúrò baba rẹ̀ ọkùnrin tàbí àbúrò rẹ̀ obìnrin tàbí ẹnikẹ́ni tí ó bá a tan nínú ìdílé rẹ̀ le è rà á padà: Bí ó bá sì ti là (Lówólọ́wọ́) ó lè ra ara rẹ̀ padà. Kí òun àti olówó rẹ̀ ka iye ọdún tí ó ta ara rẹ̀ títí dé ọdún ìdásílẹ̀ kí iye owó ìdásílẹ̀ rẹ̀ jẹ́ iye tí wọ́n ń san lórí alágbàṣe fún iye ọdún náà. Bí iye ọdún rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù bá pọ̀, kí iye owó fún ìràpadà rẹ̀ pọ̀. Bí ó bá sì ṣe pé kìkì ọdún díẹ̀ ni ó kù títí di ọdún jubili, kí ó ṣe ìṣirò rẹ̀, kí ó sì san owó náà bí iye ìṣirò rẹ̀ padà. Bí ẹ ti ń ṣe sí i lọ́dọọdún, ẹ rí i dájú pé olówó rẹ̀ kò korò mọ́ ọ. “ ‘Bí a kò bá rà á padà nínú gbogbo ọ̀nà wọ̀nyí, kí ẹ tú òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ sílẹ̀ ní ọdún ìdásílẹ̀. Nítorí pé ìránṣẹ́ ni àwọn ọmọ Israẹli jẹ́ fún mi. Ìránṣẹ́ mi ni wọ́n, tí mo mú jáde láti Ejibiti wá. Èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín.