LEFITIKU 25:47-55

LEFITIKU 25:47-55 YCE

“Bí àlejò tí ó wà láàrin yín bá di ọlọ́rọ̀ tí arakunrin rẹ̀ tí ó jẹ́ aládùúgbò rẹ̀ sì di aláìní, tí ó sì ta ara rẹ̀ fún àlejò náà, tabi fún ọ̀kan ninu ìdílé àlejò yín, lẹ́yìn tí ó bá ti ta ara rẹ̀, wọ́n lè rà á pada: ọ̀kan ninu àwọn arakunrin rẹ̀ lè rà á pada. Arakunrin baba tabi ìyá rẹ̀, tabi ọ̀kan ninu àwọn ìbátan rẹ̀ tabi ẹnìkan ninu àwọn ẹbí rẹ̀ le rà á pada. Bí òun pàápàá bá sì di ọlọ́rọ̀, ó lè ra ara rẹ̀ pada. Kí òun ati ẹni tí ó rà á jọ ṣírò iye ọdún tí ó fi ta ara rẹ̀, láti ọdún tí ó ti ta ara rẹ̀ fún un títí di ọdún jubili. Iye ọdún tí ó bá kù ni wọn yóo fi ṣírò owó ìràpadà rẹ̀. Wọn yóo ṣírò àkókò tí ó ti lò lọ́dọ̀ olówó rẹ̀ bí àkókò tí alágbàṣe wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Bí iye ọdún tí ó kù bá pọ̀, yóo ṣírò iye tí owó ìràpadà rẹ̀ kù ninu iye tí wọ́n san lórí rẹ̀, yóo sì san án pada. Bí ọdún tí ó kù tí ọdún jubili yóo fi pé kò bá pọ̀ mọ́, wọn yóo jọ ṣírò iye ọdún tí ó kù fún un láti fi sìn ín, òun ni yóo sì fi ṣírò owó ìràpadà rẹ̀ tí ó kù tí yóo san. Ọkunrin tí ó ta ara rẹ̀ yìí yóo dàbí iranṣẹ tí à ń gbà lọdọọdun sí ẹni tí ó rà á; ẹni tí ó rà á kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ líle mú un lójú rẹ̀. Bí ẹnikẹ́ni kò bá ra ẹni náà pada lọ́nà tí a ti là sílẹ̀ wọnyi, wọ́n gbọdọ̀ dá òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ sílẹ̀ nígbà tí ó bá di ọdún jubili. Nítorí pé, iranṣẹ mi ni àwọn ọmọ Israẹli jẹ́, iranṣẹ mi tí mo kó jáde láti ilẹ̀ Ijipti ni wọ́n. Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ.