Lef 23
23
Àwọn Àjọ̀dún Ẹ̀sìn
1OLUWA si sọ fun Mose pe,
2Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, ajọ OLUWA, ti ẹnyin o pè fun apejọ mimọ́, wọnyi li ajọ mi.
3Ijọ́ mẹfa ni ki a ṣe iṣẹ: ṣugbọn ni ijọ́ keje li ọjọ́ isimi, apejọ mimọ́; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ kan ninu rẹ̀: nitoripe ọjọ́-isimi OLUWA ni ninu ibujoko nyin gbogbo.
4Wọnyi li ajọ OLUWA, ani apejọ mimọ́, ti ẹnyin o pè li akokò wọn.
Àjọ̀dún Ìrékọjá ati Àìwúkàrà
(Num 28:16-25)
5Ni ijọ́ kẹrinla oṣù kini, li aṣalẹ, li ajọ irekọja OLUWA.
6Ati li ọjọ́ kẹdogun oṣù na li ajọ àkara alaiwu si OLUWA: ijọ́ meje li ẹnyin o jẹ àkara alaiwu.
7Li ọjọ́ kini ki ẹnyin ki o ní apejọ mimọ́: ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara ninu rẹ̀.
8Bikoṣe ki ẹnyin ki o ru ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA ni ijọ́ meje: ni ijọ́ keje ni apejọ mimọ́: ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara.
9OLUWA si sọ fun Mose pe,
10Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba dé ilẹ ti mo fi fun nyin, ti ẹnyin o si ma ṣe ikore rẹ̀, nigbana ni ki ẹnyin ki o mú ìdi-ọkà kan akọ́so ikore nyin tọ̀ alufa wá:
11On o si fì ìdi-ọkà na niwaju OLUWA, lati ṣe itẹwọgbà fun nyin: ni ijọ́ keji lẹhin ọjọ́-isimi ni ki alufa ki o fì i.
12Li ọjọ́ ti ẹnyin fì ìdi-ọkà ni ki ẹnyin ki o rubọ akọ ọdọ-agutan ọlọdún kan alailabùku fun ẹbọ sisun si OLUWA.
13Ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀ ki o jẹ́ meji idamẹwa òṣuwọn iyẹfun daradara, ti a fi oróro pò, ẹbọ ti a fi iná ṣe ni si OLUWA fun õrun didùn: ati ẹbọ ohun-mimu rẹ̀ ni ki o ṣe ọtí-waini idamẹrin òṣuwọn hini.
14Ẹnyin kò si gbọdọ jẹ àkara, tabi ọkà yiyan, tabi ọkà tutù ninu ipẹ́, titi yio fi di ọjọ́ na gan ti ẹnyin mú ọrẹ-ẹbọ tọ̀ Ọlọrun nyin wá: ki o si jasi ìlana titilai ni iran-iran nyin ni ibujoko nyin gbogbo.
Àjọ̀dún Ìkórè
(Num 28:26-31)
15Lati ijọ́ keji lẹhin ọjọ́-isimi, ni ọjọ́ ti ẹnyin mú ìdi-ọkà ẹbọ fifì nì wá, ki ẹnyin ki o si kà ọjọ́-isimi meje pé;
16Ani di ijọ́ keji lẹhin ọjọ́-isimi keje, ki ẹnyin ki o kà ãdọta ọjọ́; ki ẹnyin ki o si ru ẹbọ ohunjijẹ titun si OLUWA.
17Ki ẹnyin ki o si mú lati inu ibugbé nyin wá, ìṣu-àkara fifì meji ti idamẹwa meji òṣuwọn: ki nwọn ki o jẹ́ ti iyẹfun daradara, ki a fi iwukàra yan wọn, akọ́so ni nwọn fun OLUWA.
18Pẹlu àkara na ki ẹnyin ki o si fi ọdọ-agutan meje ọlọdún kan alailabukù rubọ, ati ẹgbọrọ akọmalu kan, ati àgbo meji: ki nwọn ki o jẹ́ ẹbọ sisun si OLUWA, pẹlu ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn, ani ẹbọ ti a fi iná ṣe olõrùn didùn ni si OLUWA.
19Nigbana ni ki ẹnyin ki o fi obukọ kan ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati akọ ọdọ-agutan meji ọlọdún kan ru ẹbọ alafia.
20Ki alufa ki o si fi wọn pẹlu àkara àwọn akọ́so fun ẹbọ fifì niwaju OLUWA, pẹlu ọdọ-agutan meji nì: ki nwọn ki o si jẹ́ mimọ́ si OLUWA fun alufa na.
21Ki ẹnyin ki o si kede li ọjọ́ na gan; ki o le jẹ́ apejọ mimọ́ fun nyin: ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan: yio si ma ṣe ìlana fun nyin titilai ni ibujoko nyin gbogbo ni iran-iran nyin.
22Nigbati ẹnyin ba nṣe ikore ilẹ nyin, iwọ kò gbọdọ ṣa ẹba oko rẹ li aṣatán, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ pèṣẹ́ ikore rẹ̀: ki iwọ ki o fi i silẹ fun awọn talaka, ati fun alejò: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.
Àjọ̀dún Ọdún Titun
(Num 29:1-6)
23OLUWA si sọ fun Mose pe,
24Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Li oṣù keje, li ọjọ́ kini oṣù ni ki ẹnyin ki o ní isimi; iranti ifunpe, apejọ mimọ́.
25Ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan: bikoṣepe ki ẹnyin ki o ru ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA.
Ọjọ́ Ètùtù
(Num 29:7-11)
26OLUWA si sọ fun Mose pe,
27Ijọ́ kẹwa oṣù keje yi ni ki o ṣe ọjọ́ ètutu: ki apejọ mimọ́ wà fun nyin, ki ẹnyin ki o si pọ́n ọkàn nyin loju, ki ẹ si ru ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA.
28Ẹnyin kò si gbọdọ ṣe iṣẹ kan li ọjọ́ na yi: nitoripe ọjọ́ ètutu ni, lati ṣètutu fun nyin niwaju OLUWA Ọlọrun nyin.
29Nitoripe ọkànkọkàn ti kò ba pọ́n ara rẹ̀ loju li ọjọ́ na yi, on li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀.
30Ati ọkànkọkan ti o ba ṣe iṣẹ kan li ọjọ́ na yi, ọkàn na li emi o run kuro lãrin awọn enia rẹ̀.
31Ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹkiṣẹ kan: ki o jẹ́ ìlana titilai ni iran-iran nyin ni ibujoko nyin gbogbo.
32Ọjọ́-isimi ni fun nyin, ki ẹnyin ki o si pọn ọkàn nyin loju: lo ọjọ́ kẹsan oṣù na li alẹ, lati alẹ dé alẹ, ni ki ẹnyin ki o ma pa ọjọ́-isimi nyin mọ́.
Àjọ Àgọ́
(Num 29:12-40)
33OLUWA si sọ fun Mose pe,
34Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ọjọ́ kẹdogun oṣù keje yi li ajọ agọ́ ni ijọ́ meje si OLUWA.
35Li ọjọ́ kini li apejọ mimọ́: ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan.
36Ijọ meje ni ki ẹnyin fi ru ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA: ni ijọ́ kẹjọ li apejọ́ mimọ́ fun nyin; ki ẹnyin ki o si ru ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA; ọjọ́ ajọ ni; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan.
37Wọnyi li ajọ OLUWA, ti ẹnyin o kedé lati jẹ́ apejọ mimọ́, lati ru ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA, ẹbọ sisun, ati ẹbọ ohunjijẹ, ẹbọ, ati ẹbọ ohunmimu, olukuluku wọn li ọjọ́ rẹ̀:
38Pẹlu ọjọ́-isimi OLUWA, ati pẹlu ẹ̀bun nyin, ati pẹlu gbogbo ẹjẹ́ nyin, ati pẹlu gbogbo ẹbọ atinuwá nyin ti ẹnyin fi fun OLUWA.
39Pẹlupẹlu li ọjọ́ kẹdogun oṣù keje na, nigbati ẹnyin ba ṣe ikore eso ilẹ tán, ki ẹnyin ki o si ṣe ajọ si OLUWA ni ijọ́ meje: li ọjọ́ kini ki isimi ki o wà, ati li ọjọ́ kẹjọ ki isimi ki o wà,
40Li ọjọ́ kini ki ẹnyin ki o si mú eso igi daradara, imọ̀-ọpẹ, ati ẹká igi ti o bò, ati ti igi wilo odò; ki ẹnyin ki o si ma yọ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun nyin ni ijọ́ meje.
41Ki ẹnyin ki o si ma pa a mọ́ li ajọ fun OLUWA ni ijọ́ meje li ọdún: ìlana ni titilai ni iran-iran nyin: ki ẹnyin ki o ma ṣe e li oṣù keje.
42Ki ẹnyin ki o ma gbé inu agọ́ ni ijọ́ meje; gbogbo ibilẹ ni Israeli ni ki o gbé inu agọ́:
43Ki iran-iran nyin ki o le mọ̀ pe, Emi li o mu awọn ọmọ Israeli gbé inu agọ́, nigbati mo mú wọn lati ilẹ Egipti jade wá: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.
44Mose si sọ gbogbo ajọ OLUWA wọnyi fun awọn ọmọ Israeli.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Lef 23: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.