Lef 22

22
Àwọn Ohun Ìrúbọ Gbọdọ̀ Jẹ́ Mímọ́
1OLUWA si sọ fun Mose pe,
2Sọ fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, ki nwọn ki o yà ara wọn sọ̀tọ kuro ninu ohun mimọ́ awọn ọmọ Israeli, ki nwọn ki o má si ṣe bà orukọ mimọ́ mi jẹ́ ninu ohun wọnni, ti nwọn yàsimimọ́ fun mi: Emi li OLUWA,
3Wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ninu gbogbo irú-ọmọ nyin ninu awọn iran nyin, ti o ba sunmọ ohun mimọ́, ti awọn ọmọ Israeli yàsimimọ́ fun OLUWA, ti o ní aimọ́ rẹ̀ lara rẹ̀, ọkàn na li a o ke kuro niwaju mi: Emi li OLUWA.
4Ẹnikẹni ninu irú-ọmọ Aaroni ti iṣe adẹtẹ, tabi ti o ní isun; ki o máṣe jẹ ninu ohun mimọ́, titi on o fi di mimọ́. Ati ẹnikẹni ti o farakàn ohun ti iṣe aimọ́, bi okú, tabi ọkunrin ti ohun-irú nti ara rẹ̀ jade;
5Tabi ẹniti o ba farakàn ohun ti nrakò kan, ti yio sọ ọ di aimọ́, tabi enia kan ti yio sọ ọ di aimọ́, irú aimọ́ ti o wù ki o ní;
6Ọkàn ti o ba farakàn ọkan ninu irú ohun bẹ̃ ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ, ki o má si ṣe jẹ ninu ohun mimọ́, bikoṣepe o ba fi omi wẹ̀ ara rẹ̀.
7Nigbati õrùn ba si wọ̀, on o di mimọ́; lẹhin eyinì ki o si ma jẹ ninu ohun mimọ́, nitoripe onjẹ rẹ̀ ni.
8On kò gbọdọ jẹ ẹran ti o kú fun ara rẹ̀, tabi eyiti ẹranko fàya, lati fi i bà ara rẹ̀ jẹ́: Emi li OLUWA.
9Nitorina ki nwọn ki o ma pa ìlana mi mọ́, ki nwọn ki o máṣe rù ẹ̀ṣẹ nitori rẹ̀, nwọn a si kú nitorina, bi nwọn ba bà a jẹ́: Emi li OLUWA ti o yà wọn simimọ́.
10Alejò kan kò gbọdọ jẹ ninu ohun mimọ́: alabagbé alufa, tabi alagbaṣe kò gbọdọ jẹ ninu ohun mimọ́ na.
11Ṣugbọn bi alufa ba fi owo rẹ̀ rà ẹnikan, ki o jẹ ninu rẹ̀; ẹniti a si bi ninu ile rẹ̀, ki nwọn ki o ma jẹ ninu onjẹ rẹ̀.
12Bi ọmọbinrin alufa na ba si ní alejò kan li ọkọ, obinrin na kò le jẹ ninu ẹbọ fifì ohun mimọ́.
13Ṣugbọn bi ọmọbinrin alufa na ba di opó, tabi ẹni-ikọsilẹ, ti kò si lí ọmọ, ti o si pada wá si ile baba rẹ̀, bi ìgba ewe rẹ̀, ki o ma jẹ ninu onjẹ baba rẹ̀: ṣugbọn alejò kan kò gbọdọ jẹ ninu rẹ̀.
14Bi ẹnikan ba si jẹ ninu ohun mimọ́ li aimọ̀, njẹ ki o fi idamarun rẹ̀ lé e, ki o si fi i fun alufa pẹlu ohun mimọ́ na.
15Nwọn kò si gbọdọ bà ohun mimọ́ awọn ọmọ Israeli jẹ́, ti nwọn mú fun OLUWA wá:
16Tabi lati jẹ ki nwọn ki o rù aiṣedede ti o mú ẹbi wá, nigbati nwọn ba njẹ ohun mimọ́ wọn: nitoripe Emi li OLUWA ti o yà wọn simimọ́.
17OLUWA si sọ fun Mose pe,
18Sọ fun Aaroni, ati fun awọn ọmọ rẹ̀, ati fun gbogbo awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ninu ile Israeli, tabi ninu awọn alejò ni Israeli, ti o ba fẹ́ ru ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ nitori ẹjẹ́ wọn gbogbo, ati nitori ẹbọ rẹ̀ atinuwá gbogbo, ti nwọn nfẹ́ ru si OLUWA fun ẹbọ sisun;
19Ki o le dà fun nyin, akọ alailabùkun ni ki ẹnyin ki o fi ru u, ninu malu, tabi ninu agutan, tabi ninu ewurẹ.
20Ṣugbọn ohunkohun ti o ní abùku, li ẹnyin kò gbọdọ múwa: nitoripe ki yio dà fun nyin.
21Ati ẹnikẹni ti o ba ru ẹbọ alafia si OLUWA, lati san ẹjẹ́, tabi ẹbọ ifẹ́-atinuwá ni malu tabi agutan, ki o pé ki o ba le dà; ki o máṣe sí abùku kan ninu rẹ̀.
22Afọju, tabi fifàya, tabi eyiti a palara, tabi elegbo, elekuru, tabi oni-ipẹ́, wọnyi li ẹnyin kò gbọdọ fi rubọ si OLUWA, bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ fi ninu wọn ṣe ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA lori pẹpẹ.
23Ibaṣe akọmalu tabi ọdọ-agutan ti o ní ohun ileke kan, tabi ohun abùku kan, eyinì ni ki iwọ ma fi ru ẹbọ ifẹ́-atinuwá; ṣugbọn fun ẹjẹ́ ki yio dà.
24Ẹnyin kò gbọdọ mú eyiti kóro rẹ̀ fọ́, tabi ti a tẹ̀, tabi ti a ya, tabi ti a là, wá rubọ si OLUWA; ki ẹnyin máṣe e ni ilẹ nyin.
25Bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ ti ọwọ́ alejò rubọ àkara Ọlọrun nyin ninu gbogbo wọnyi; nitoripe ibàjẹ́ wọn mbẹ ninu wọn, abùku si mbẹ ninu wọn: nwọn ki yio dà fun nyin.
26OLUWA si sọ fun Mose pe,
27Nigbati a ba bi akọmalu kan, tabi agutan kan, tabi ewurẹ kan, nigbana ni ki o gbé ijọ meje lọdọ iya rẹ̀; ati lati ijọ́ kẹjọ ati titi lọ on o di itẹwọgbà fun ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA.
28Ibaṣe abomalu tabi agutan, ẹnyin kò gbọdọ pa a ati ọmọ rẹ̀ li ọjọ́ kanna.
29Nigbati ẹnyin ba si ru ẹbọ ọpẹ́ si OLUWA, ẹ ru u ki o le dà.
30Li ọjọ́ na ni ki a jẹ ẹ; ẹnyin kò gbọdọ ṣẹ́kù silẹ ninu rẹ̀ titi di ijọ́ keji: Emi li OLUWA.
31Nitorina ni ki ẹnyin ki o ma pa aṣẹ mi mọ́, ki ẹnyin si ma ṣe wọn: Emi li OLUWA.
32Bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ bà orukọ mimọ́ mi jẹ́; bikoṣe ki a yà mi simimọ́ lãrin awọn ọmọ Israeli: Emi li OLUWA ti nyà nyin simimọ́,
33Ti o mú nyin jade lati ilẹ Egipti wá, lati ma ṣe Ọlọrun nyin: Emi li OLUWA.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Lef 22: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀