Lef 22:1-16

Lef 22:1-16 YBCV

OLUWA si sọ fun Mose pe, Sọ fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, ki nwọn ki o yà ara wọn sọ̀tọ kuro ninu ohun mimọ́ awọn ọmọ Israeli, ki nwọn ki o má si ṣe bà orukọ mimọ́ mi jẹ́ ninu ohun wọnni, ti nwọn yàsimimọ́ fun mi: Emi li OLUWA, Wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ninu gbogbo irú-ọmọ nyin ninu awọn iran nyin, ti o ba sunmọ ohun mimọ́, ti awọn ọmọ Israeli yàsimimọ́ fun OLUWA, ti o ní aimọ́ rẹ̀ lara rẹ̀, ọkàn na li a o ke kuro niwaju mi: Emi li OLUWA. Ẹnikẹni ninu irú-ọmọ Aaroni ti iṣe adẹtẹ, tabi ti o ní isun; ki o máṣe jẹ ninu ohun mimọ́, titi on o fi di mimọ́. Ati ẹnikẹni ti o farakàn ohun ti iṣe aimọ́, bi okú, tabi ọkunrin ti ohun-irú nti ara rẹ̀ jade; Tabi ẹniti o ba farakàn ohun ti nrakò kan, ti yio sọ ọ di aimọ́, tabi enia kan ti yio sọ ọ di aimọ́, irú aimọ́ ti o wù ki o ní; Ọkàn ti o ba farakàn ọkan ninu irú ohun bẹ̃ ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ, ki o má si ṣe jẹ ninu ohun mimọ́, bikoṣepe o ba fi omi wẹ̀ ara rẹ̀. Nigbati õrùn ba si wọ̀, on o di mimọ́; lẹhin eyinì ki o si ma jẹ ninu ohun mimọ́, nitoripe onjẹ rẹ̀ ni. On kò gbọdọ jẹ ẹran ti o kú fun ara rẹ̀, tabi eyiti ẹranko fàya, lati fi i bà ara rẹ̀ jẹ́: Emi li OLUWA. Nitorina ki nwọn ki o ma pa ìlana mi mọ́, ki nwọn ki o máṣe rù ẹ̀ṣẹ nitori rẹ̀, nwọn a si kú nitorina, bi nwọn ba bà a jẹ́: Emi li OLUWA ti o yà wọn simimọ́. Alejò kan kò gbọdọ jẹ ninu ohun mimọ́: alabagbé alufa, tabi alagbaṣe kò gbọdọ jẹ ninu ohun mimọ́ na. Ṣugbọn bi alufa ba fi owo rẹ̀ rà ẹnikan, ki o jẹ ninu rẹ̀; ẹniti a si bi ninu ile rẹ̀, ki nwọn ki o ma jẹ ninu onjẹ rẹ̀. Bi ọmọbinrin alufa na ba si ní alejò kan li ọkọ, obinrin na kò le jẹ ninu ẹbọ fifì ohun mimọ́. Ṣugbọn bi ọmọbinrin alufa na ba di opó, tabi ẹni-ikọsilẹ, ti kò si lí ọmọ, ti o si pada wá si ile baba rẹ̀, bi ìgba ewe rẹ̀, ki o ma jẹ ninu onjẹ baba rẹ̀: ṣugbọn alejò kan kò gbọdọ jẹ ninu rẹ̀. Bi ẹnikan ba si jẹ ninu ohun mimọ́ li aimọ̀, njẹ ki o fi idamarun rẹ̀ lé e, ki o si fi i fun alufa pẹlu ohun mimọ́ na. Nwọn kò si gbọdọ bà ohun mimọ́ awọn ọmọ Israeli jẹ́, ti nwọn mú fun OLUWA wá: Tabi lati jẹ ki nwọn ki o rù aiṣedede ti o mú ẹbi wá, nigbati nwọn ba njẹ ohun mimọ́ wọn: nitoripe Emi li OLUWA ti o yà wọn simimọ́.