Lef 20
20
Ìjìyà fún Ìwà Àìgbọràn
1OLUWA si sọ fun Mose pe,
2Iwọ o si sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnikẹni ninu awọn ọmọ Israeli, tabi ninu awọn alejò ti nṣe atipo ni Israeli, ti o ba fi ninu irú-ọmọ rẹ̀ fun Moleki; pipa ni ki a pa a: ki awọn enia ilẹ na ki o sọ ọ li okuta pa.
3Emi o si kọju mi si ọkunrin na, emi o si ke e kuro lãrin awọn enia rẹ̀; nitoriti o fi ninu irú-ọmọ rẹ̀ fun Moleki, lati sọ ibi mimọ́ mi di aimọ́, ati lati bà orukọ mimọ́ mi jẹ́.
4Bi awọn enia ilẹ na ba si mú oju wọn kuro lara ọkunrin na, nigbati o ba fi ninu irú-ọmọ rẹ̀ fun Moleki, ti nwọn kò si pa a:
5Nigbana li emi o kọju si ọkunrin na, ati si idile rẹ̀, emi o si ke e kuro, ati gbogbo awọn ti o ṣe àgbere tọ̀ ọ lẹhin, lati ma ṣe àgbere tọ̀ Moleki lẹhin, lãrin awọn enia wọn.
6Ati ọkàn ti o ba yipada tọ̀ awọn ti o ní ìmọ afọṣẹ, ati ajẹ́, lati ṣe àgbere tọ̀ wọn lẹhin, ani emi o kọju mi si ọkàn na, emi o si ke e kuro lãrin awọn enia rẹ̀.
7Nitorina ẹnyin yà ara nyin simimọ́, ki ẹnyin ki o si jẹ́ mimọ́: nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.
8Ki ẹnyin ki o si ma pa ìlana mi mọ́, ki ẹnyin si ma ṣe wọn: Emi li OLUWA ti nyà nyin simimọ́.
9Ẹnikẹni ti o ba fi baba tabi iya rẹ̀ ré, pipa li a o pa a: o fi baba on iya rẹ̀ ré; ẹ̀jẹ rẹ̀ wà lori rẹ̀.
10Ati ọkunrin na ti o bá aya ọkunrin miran ṣe panṣaga, ani on ti o bá aya ẹnikeji rẹ̀ ṣe panṣaga, panṣaga ọkunrin ati panṣaga obinrin li a o pa nitõtọ.
11Ati ọkunrin ti o bá aya baba rẹ̀ dàpọ, o tú ìhoho baba rẹ̀: pipa li a o pa awọn mejeji; ẹ̀jẹ wọn yio wà lori wọn.
12Ọkunrin kan ti o ba bá aya ọmọ rẹ̀ dàpọ, pipa ni ki a pa awọn mejeji: nwọn ṣe rudurudu; ẹ̀jẹ wọn wà lori wọn.
13Ati ọkunrin ti o ba bá ọkunrin dàpọ, bi ẹni ba obinrin dàpọ, awọn mejeji li o ṣe ohun irira: pipa li a o pa wọn; ẹ̀jẹ wọn yio wà lori wọn.
14Ati ọkunrin ti o ba fẹ́ obinrin ati iya rẹ̀, ìwabuburu ni: iná li a o fi sun wọn, ati on ati awọn; ki ìwabuburu ki o má ṣe sí lãrin nyin.
15Ati ọkunrin ti o ba bá ẹranko dàpọ, pipa ni ki a pa a: ki ẹnyin ki o si pa ẹranko na.
16Bi obinrin kan ba si sunmọ ẹranko kan, lati dubulẹ tì i, ki iwọ ki o pa obinrin na, ati ẹranko na: pipa ni ki a pa wọn; ẹ̀jẹ wọn yio wà lori wọn.
17Ati bi ọkunrin kan ba fẹ́ arabinrin rẹ̀, ọmọbinrin baba rẹ̀, tabi ọmọbinrin iya rẹ̀, ti o si ri ìhoho rẹ̀, ti on si ri ìhoho rẹ̀; ohun buburu ni; a o si ke wọn kuro loju awọn enia wọn: o tú ìhoho arabinrin rẹ̀; on o rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀.
18Ati bi ọkunrin kan ba bá obinrin dàpọ ti o ní ohun obinrin rẹ̀ lara, ti o ba si tú u ni ìhoho; o tú isun rẹ̀ ni ìhoho, obinrin na si fi isun ẹ̀jẹ rẹ̀ hàn: awọn mejeji li a o si ke kuro lãrin awọn enia wọn.
19Iwọ kò si gbọdọ tú ìhoho arabinrin iya rẹ, tabi ti arabinrin baba rẹ: nitoripe o tú ìhoho ibatan rẹ̀: nwọn o rù ẹ̀ṣẹ wọn.
20Bi ọkunrin kan ba si bá aya arakunrin õbi rẹ̀ dàpọ, o tú ìhoho arakunrin õbi rẹ̀: nwọn o rù ẹ̀ṣẹ wọn; nwọn o kú li ailọmọ.
21Bi ọkunrin kan ba si fẹ́ aya arakunrin rẹ̀, ohun-aimọ́ ni: o tú ìhoho arakunrin rẹ̀; nwọn o jẹ́ alailọmọ.
22Nitorina li ẹnyin o ṣe ma pa gbogbo ìlana mi mọ́, ati gbogbo idajọ mi, ki ẹnyin si ma ṣe wọn: ki ilẹ na, ninu eyiti mo mú nyin wá tẹ̀dó si, ki o má ṣe bì nyin jade.
23Ẹnyin kò si gbọdọ rìn ninu ìlana orilẹ-ède, ti emi lé jade kuro niwaju nyin: nitoriti nwọn ṣe gbogbo wọnyi, nitorina ni mo ṣe korira wọn.
24Ṣugbọn emi ti wi fun nyin pe, Ẹnyin o ní ilẹ wọn, ati pe emi o fi i fun nyin lati ní i, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin, ti o yà nyin sọ̀tọ kuro ninu awọn orilẹ-ède.
25Nitorina ki ẹnyin ki o fi ìyatọ sãrin ẹranko mimọ́ ati alaimọ́, ati sãrin ẹiyẹ alaimọ́ ati mimọ́: ki ẹnyin ki o má si ṣe fi ẹranko, tabi ẹiyẹ, tabi ohunkohun alãye kan ti nrakò lori ilẹ, ti mo ti yàsọ̀tọ fun nyin bi alaimọ́, sọ ọkàn nyin di irira.
26Ki ẹnyin ki o si jẹ́ mimọ́ fun mi: nitoripe mimọ́ li Emi OLUWA, mo si ti yà nyin sọ̀tọ kuro ninu awọn orilẹ-ède, ki ẹnyin ki o le jẹ́ ti emi.
27Ọkunrin pẹlu tabi obinrin ti o ní ìmo afọṣẹ, tabi ti iṣe ajẹ́, pipa ni ki a pa a: okuta ni ki a fi sọ wọn pa: ẹ̀jẹ wọn yio wà lori wọn.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Lef 20: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.