BAWO ni ilu ṣe joko nikan, eyi ti o ti kún fun enia! o wà bi opó! on ti iṣe ẹni-nla lãrin awọn orilẹ-ède! ọmọ-alade obinrin lãrin igberiko, on di ẹrú! On sọkun gidigidi li oru, omije rẹ̀ si wà ni ẹ̀rẹkẹ rẹ̀: lãrin gbogbo awọn olufẹ rẹ̀, kò ni ẹnikẹni lati tù u ninu: gbogbo awọn ọrẹ rẹ̀ ti ba a lo ẹ̀tan, nwọn di ọta rẹ̀. Juda lọ si àjo nitori ipọnju ati isin-ẹrú nla: o joko lãrin awọn orilẹ-ède, on kò ri isimi: gbogbo awọn ti nlepa rẹ̀ ba a ni ibi hiha. Ọ̀na Sioni wọnni nṣọ̀fọ, nitori ẹnikan kò wá si ajọ-mimọ́: gbogbo ẹnu-bode rẹ̀ dahoro: awọn alufa rẹ̀ kẹdun, awọn wundia rẹ̀ nkãnu, on si wà ni kikoro ọkàn. Awọn aninilara rẹ̀ bori, awọn ọta rẹ̀ ri rere: nitori Oluwa ti pọn ọ loju nitori ọ̀pọlọpọ irekọja rẹ̀; awọn ọmọ wẹrẹ rẹ̀ lọ si igbekun niwaju awọn aninilara. Gbogbo ẹwà ọmọbinrin Sioni si ti lọ kuro lọdọ rẹ̀: awọn ijoye rẹ̀ dabi agbọnrin ti kò ri pápá oko tutu, nwọn si lọ laini agbara niwaju alepa nì
Kà Ẹk. Jer 1
Feti si Ẹk. Jer 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Ẹk. Jer 1:1-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò