Ẹk. Jer 1:1-6

Ẹk. Jer 1:1-6 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ wò ó bí ìlú tí ó kún fún eniyan tẹ́lẹ̀ ti di ahoro, tí ó wá dàbí opó! Ìlú tí ó tóbi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tẹ́lẹ̀! Tí ó sì dàbí ọmọ ọba obinrin láàrin àwọn ìlú yòókù. Ó ti wá di ẹni àmúsìn. Ó ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn lóru, omijé ń dà lójú rẹ̀, kò sì sí ẹni tí yóo tù ú ninu, láàrin àwọn alajọṣepọ rẹ̀. Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti dà á, wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì di ọ̀tá rẹ̀. Juda ti lọ sí ìgbèkùn, wọ́n sì ń fi tipátipá mú un sìn. Nisinsinyii, ó ń gbé ààrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, kò sì ní ibi ìsinmi. Ọwọ́ àwọn tí wọn ń lépa rẹ̀ ti tẹ̀ ẹ́, ninu ìdààmú rẹ̀. Àwọn ọ̀nà tó lọ sí Sioni ń ṣe ìdárò, nítorí kò sí ẹni tí ó ń gba ibẹ̀ lọ síbi àwọn àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀ mọ́. Àwọn ẹnubodè rẹ̀ ti di ahoro, àwọn alufaa rẹ̀ sì ń kẹ́dùn. Wọ́n ń pọ́n àwọn ọmọbinrin rẹ̀ lójú, òun pàápàá sì ń joró lọpọlọpọ. Àwọn ọ̀tá ilẹ̀ Juda ti borí rẹ̀, wọ́n ti wá di ọ̀gá rẹ̀, nítorí pé, OLUWA ń jẹ ẹ́ níyà fún ọpọlọpọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, àwọn ọ̀tá ti ti àwọn ọmọ rẹ̀ ṣáájú, wọ́n ti kó wọn nígbèkùn lọ. Gbogbo ògo Jerusalẹmu ti fò lọ kúrò lára rẹ̀, àwọn olórí rẹ̀ dàbí àgbọ̀nrín tí kò rí koríko tútù jẹ; agbára kò sí fún wọn mọ́, wọ́n ń sálọ níwájú àwọn tí ń lé wọn.

Ẹk. Jer 1:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Báwo ni ìlú ṣe jókòó nìkan, nígbà kan tí ó sì kún fún ènìyàn! Ó ti fìgbà kan jẹ́ ìlú olókìkí láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, tí ó wà ní ipò opó, Ẹni tí ó jẹ́ ọmọ ọbabìnrin láàrín ìlú ni ó padà di ẹrú. Ọ̀gànjọ́ òru ni ó fi máa ń sọkún kíkorò pẹ̀lú omijé ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ tí ó dúró sí ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀. Nínú gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ kò sí ọ̀kan nínú wọn láti rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún. Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti jọ̀wọ́ rẹ̀ wọ́n ti di alátakò rẹ̀. Lẹ́yìn ìjìyà àti ìpọ́njú nínú oko ẹrú, Juda lọ sí àjò Ó tẹ̀dó láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n kò rí ibi ìsinmi. Àwọn tí ó ń tẹ̀lé ká á mọ́ ibi tí kò ti le sá àsálà. Gbogbo ọ̀nà tí ó wọ Sioni ń ṣọ̀fọ̀, nítorí ẹnìkan kò wá sí àjọ̀dún tí a yàn. Gbogbo ẹnu-bodè rẹ̀ dahoro, àwọn àlùfáà rẹ̀ kẹ́dùn, àwọn wúńdíá rẹ̀ sì ń káàánú, òun gan an wà ní ọkàn kíkorò. Àwọn aninilára rẹ̀ gbogbo di olúwa rẹ̀, nǹkan sì rọrùn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀, OLúWA ti fún un ní ìjìyà tó tọ́ nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Àwọn ẹ̀ṣọ́ wẹ́wẹ́ rẹ̀ lọ sí oko ẹrú, ìgbèkùn níwájú àwọn ọ̀tá. Gbogbo ẹwà ti di ohun ìgbàgbé kúrò lọ́dọ̀ ọmọbìnrin Sioni. Àwọn ìjòyè rẹ̀ dàbí i àgbọ̀nrín tí kò rí ewé tútù jẹ; nínú àárẹ̀ wọ́n sáré níwájú ẹni tí ó ń lé wọn.