ẸKÚN JEREMAYA 1:1-6

ẸKÚN JEREMAYA 1:1-6 YCE

Ẹ wò ó bí ìlú tí ó kún fún eniyan tẹ́lẹ̀ ti di ahoro, tí ó wá dàbí opó! Ìlú tí ó tóbi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tẹ́lẹ̀! Tí ó sì dàbí ọmọ ọba obinrin láàrin àwọn ìlú yòókù. Ó ti wá di ẹni àmúsìn. Ó ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn lóru, omijé ń dà lójú rẹ̀, kò sì sí ẹni tí yóo tù ú ninu, láàrin àwọn alajọṣepọ rẹ̀. Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti dà á, wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì di ọ̀tá rẹ̀. Juda ti lọ sí ìgbèkùn, wọ́n sì ń fi tipátipá mú un sìn. Nisinsinyii, ó ń gbé ààrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, kò sì ní ibi ìsinmi. Ọwọ́ àwọn tí wọn ń lépa rẹ̀ ti tẹ̀ ẹ́, ninu ìdààmú rẹ̀. Àwọn ọ̀nà tó lọ sí Sioni ń ṣe ìdárò, nítorí kò sí ẹni tí ó ń gba ibẹ̀ lọ síbi àwọn àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀ mọ́. Àwọn ẹnubodè rẹ̀ ti di ahoro, àwọn alufaa rẹ̀ sì ń kẹ́dùn. Wọ́n ń pọ́n àwọn ọmọbinrin rẹ̀ lójú, òun pàápàá sì ń joró lọpọlọpọ. Àwọn ọ̀tá ilẹ̀ Juda ti borí rẹ̀, wọ́n ti wá di ọ̀gá rẹ̀, nítorí pé, OLUWA ń jẹ ẹ́ níyà fún ọpọlọpọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, àwọn ọ̀tá ti ti àwọn ọmọ rẹ̀ ṣáájú, wọ́n ti kó wọn nígbèkùn lọ. Gbogbo ògo Jerusalẹmu ti fò lọ kúrò lára rẹ̀, àwọn olórí rẹ̀ dàbí àgbọ̀nrín tí kò rí koríko tútù jẹ; agbára kò sí fún wọn mọ́, wọ́n ń sálọ níwájú àwọn tí ń lé wọn.