Bẹ̃ni Joṣua gòke lati Gilgali lọ, on ati gbogbo awọn ọmọ-ogun pẹlu rẹ̀, ati gbogbo awọn alagbara akọni. OLUWA si wi fun Joṣua pe, Má ṣe bẹ̀ru wọn: nitoriti mo ti fi wọn lé ọ lọwọ; ki yio sí ọkunrin kan ninu wọn ti yio le duro niwaju rẹ. Joṣua si yọ si wọn lojijì; o si gòke lati Gilgali lọ ni gbogbo oru na. OLUWA si fọ́ wọn niwaju Israeli, o si pa wọn ni ipakupa ni Gibeoni, o si lepa wọn li ọ̀na òke Beti-horoni, o si pa wọn dé Aseka, ati dé Makkeda. O si ṣe, bi nwọn ti nsá niwaju Israeli, ti nwọn dé gẹrẹgẹrẹ Beti-horoni, OLUWA rọ̀ yinyin nla si wọn lati ọrun wá titi dé Aseka, nwọn si kú: awọn ti o ti ipa yinyin kú, o pọ̀ju awọn ti awọn ọmọ Israeli fi idà pa lọ. Nigbana ni Joṣua wi fun OLUWA li ọjọ́ ti OLUWA fi awọn Amori fun awọn ọmọ Israeli, o si wi li oju Israeli pe, Iwọ, Õrùn, duro jẹ lori Gibeoni; ati Iwọ, Oṣupa, li afonifoji Aijaloni. Õrùn si duro jẹ, oṣupa si duro, titi awọn enia fi gbẹsan lara awọn ọtá wọn. A kò ha kọ eyi nã sinu iwé Jaṣeri? Bẹ̃li õrùn duro li agbedemeji ọrun, kò si yára lati wọ̀ nìwọn ọjọ́ kan tọ̀tọ. Kò sí ọjọ́ ti o dabi rẹ̀ ṣaju rẹ̀ tabi lẹhin rẹ̀, ti OLUWA gbọ́ ohùn enia: nitoriti OLUWA jà fun Israeli. Joṣua si pada, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, si ibudó ni Gilgali.
Kà Joṣ 10
Feti si Joṣ 10
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Joṣ 10:7-15
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò