Joṣ 10:7-15

Joṣ 10:7-15 Yoruba Bible (YCE)

Joṣua bá lọ láti Giligali, òun ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀, pẹlu gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ akikanju ati akọni. OLUWA wí fún Joṣua pé, “Má bẹ̀rù wọn, nítorí pé mo ti fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́. Ẹnikẹ́ni ninu wọn kò ní lè ṣẹgun rẹ.” Joṣua jálù wọ́n lójijì, lẹ́yìn tí ó ti fi gbogbo òru rìn láti Giligali. OLUWA mú kí ìpayà bá àwọn ará Amori, nígbà tí wọ́n rí àwọn ọmọ Israẹli, àwọn ọmọ Israẹli bá bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n ní ìpakúpa ní Gibeoni. Wọ́n lé wọn gba ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Beti Horoni, wọ́n sì pa wọ́n títí dé Aseka ati Makeda. Bí wọ́n sì ti ń sá lọ fún àwọn ọmọ Israẹli, tí wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ ní ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Beti Horoni, OLUWA mú kí àwọn òkúta ńláńlá máa bọ́ lù wọ́n láti ojú ọ̀run, títí tí wọ́n fi dé Aseka, wọ́n sì kú. Àwọn tí òkúta ńláńlá wọnyi pa pọ̀ ju àwọn tí àwọn ọmọ Israẹli fi idà pa lọ. Ní ọjọ́ tí OLUWA fi àwọn ará Amori lé àwọn ọmọ Israẹli lọ́wọ́, Joṣua bá OLUWA sọ̀rọ̀ lójú gbogbo Israẹli, ó ní, “Ìwọ oòrùn, dúró jẹ́ẹ́ ní Gibeoni. Ìwọ òṣùpá, sì dúró jẹ́ẹ́ ní àfonífojì Aijaloni.” Oòrùn bá dúró jẹ́ẹ́, òṣùpá náà sì dúró jẹ́ẹ́, títí tí àwọn ọmọ Israẹli fi gbẹ̀san tán lára àwọn ọ̀tá wọn. Wọ́n kọ ọ́ sinu ìwé Jaṣari pé, oòrùn dúró ní agbede meji ojú ọ̀run, kò sì tètè wọ̀ fún bí odidi ọjọ́ kan. Irú ọjọ́ bẹ́ẹ̀ kò wáyé rí ṣáájú ìgbà náà, bẹ́ẹ̀ sì ni, láti ìgbà náà, kò sì tíì tún ṣẹlẹ̀, pé kí OLUWA gba ọ̀rọ̀ sí eniyan lẹ́nu, èyí ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ nítorí pé, OLUWA jà fún Israẹli. Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli bá pada sí àgọ́ wọn ní Giligali.

Joṣ 10:7-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua gòkè lọ láti Gilgali pẹ̀lú gbogbo ogun rẹ̀, àti akọni nínú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀. OLúWA sì sọ fún Joṣua pé, “Má ṣe bẹ̀rù wọn; Mo ti fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́. Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wọn ti yóò lè dojúkọ ọ́.” Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti wọ́de ogun ní gbogbo òru náà láti Gilgali, Joṣua sì yọ sí wọn lójijì. OLúWA mú kí wọn dààmú níwájú àwọn Israẹli, wọ́n sì pa wọ́n ní ìpakúpa ní Gibeoni. Israẹli sì lépa wọn ní ọ̀nà tí ó lọ sí Beti-Horoni, ó sì pa wọ́n dé Aseka, àti Makkeda. Bí wọ́n sì tí ń sá ní iwájú Israẹli ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ní ọ̀nà láti Beti-Horoni títí dé Aseka, OLúWA rọ yìnyín ńlá sí wọn láti ọ̀run wá, àwọn tí ó ti ipa yìnyín kú sì pọ̀ ju àwọn tí àwọn ará Israẹli fi idà pa lọ. Ní ọjọ́ tí OLúWA fi àwọn ọmọ Amori lé Israẹli lọ́wọ́, Joṣua sọ fún OLúWA níwájú àwọn ará Israẹli: “Ìwọ oòrùn, dúró jẹ́ẹ́ ní orí Gibeoni, Ìwọ òṣùpá, dúró jẹ́ẹ́ lórí Àfonífojì Aijaloni.” Bẹ́ẹ̀ ni oòrùn náà sì dúró jẹ́ẹ́, òṣùpá náà sì dúró, títí tí ìlú náà fi gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ nínú ìwé Jaṣari. Oòrùn sì dúró ní agbede-méjì ọ̀run, kò sì wọ̀ ní ìwọ̀n odindi ọjọ́ kan. Kò sí ọjọ́ tí o dàbí rẹ̀ ṣáájú tàbí ní ẹ̀yìn rẹ̀, ọjọ́ tí OLúWA gbọ́ ohùn ènìyàn. Dájúdájú OLúWA jà fún Israẹli! Nígbà náà ni Joṣua àti gbogbo Israẹli padà sí ibùdó ní Gilgali.