Joel 2:25-26

Joel 2:25-26 YBCV

Emi o si mu ọdun wọnni padà fun nyin wá, eyi ti ẽṣú on iru kòkoro jewejewe, ati iru kòkoro keji, ati iru kòkoro jewejewe miràn ti fi jẹ, awọn ogun nla mi ti mo rán sãrin nyin. Ẹnyin o si jẹun li ọ̀pọlọpọ, ẹ o si yó, ẹ o si yìn orukọ Oluwa Ọlọrun nyin, ẹniti o fi iyanu ba nyin lò; oju kì o si tì awọn enia mi lai.