Joel 2:25-26
Joel 2:25-26 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi o si mu ọdun wọnni padà fun nyin wá, eyi ti ẽṣú on iru kòkoro jewejewe, ati iru kòkoro keji, ati iru kòkoro jewejewe miràn ti fi jẹ, awọn ogun nla mi ti mo rán sãrin nyin. Ẹnyin o si jẹun li ọ̀pọlọpọ, ẹ o si yó, ẹ o si yìn orukọ Oluwa Ọlọrun nyin, ẹniti o fi iyanu ba nyin lò; oju kì o si tì awọn enia mi lai.
Joel 2:25-26 Yoruba Bible (YCE)
Gbogbo ohun tí ẹ pàdánù ní àwọn ọdún tí àwọn ọmọ ogun mi tí mo rán si yín ti jẹ oko yín; ati èyí tí eṣú wẹẹrẹ jẹ, ati èyí tí eṣú ńláńlá jẹ, gbogbo rẹ̀ ni n óo dá pada fun yín. Ẹ óo jẹ oúnjẹ àjẹyó ati àjẹtẹ́rùn, ẹ óo sì yin orúkọ OLUWA Ọlọrun yín, tí ó ṣe ohun ìyanu ńlá fun yín, ojú kò sì ní ti àwọn eniyan mi mọ́ lae.
Joel 2:25-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Èmi yóò sì mú ọdún wọ̀nyí ti eṣú jẹ run padà fún un yín. Èyí tí eṣú agénijẹ àti eṣú jewéjewé ọwọ́ eṣú agénijẹ àti kòkòrò ajẹnirun mìíràn ti fi jẹ àwọn ogun ńlá mi tí mo rán sí àárín yín. Ẹ̀yin yóò ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti jẹ, títí ẹ̀yin yóò fi yó ẹ ó sì yín orúkọ OLúWA Ọlọ́run yín, ẹni tí ó fi ìyanu bá yín lò; ojú kì yóò sì ti àwọn ènìyàn mi láéláé.