Joel 1
1
1Ọ̀RỌ Oluwa ti o tọ̀ Joeli ọmọ Petueli wá.
Ìdárò Nítorí Ìparun Nǹkan Ọ̀gbìn
2Gbọ́ eyi, ẹnyin arugbo, si fi eti silẹ, gbogbo ẹnyin ará ilẹ na. Eyi ha wà li ọjọ nyin, tabi li ọjọ awọn baba nyin?
3Ẹ sọ ọ fun awọn ọmọ nyin, ati awọn ọmọ nyin fun awọn ọmọ wọn, ati awọn ọmọ wọn fun iran miràn.
4Eyi ti iru kòkoro kan jẹ kù ni ẽṣú jẹ; ati eyi ti ẽṣú jẹ kù ni kòkoro miràn jẹ; eyiti kòkoro na si jẹ kù ni kòkoro miràn jẹ.
5Ji, ẹnyin ọmùti, ẹ si sọkun; si hu, gbogbo ẹnyin ọmùti waini, nitori ọti-waini titun; nitoriti a ké e kuro li ẹnu nyin.
6Nitori orilẹ-ède kan goke wá si ilẹ mi, o li agbara, kò si ni iye, ehin ẹniti iṣe ehin kiniun, o si ni erìgi abo kiniun.
7O ti pa àjara mi run, o si ti ya ẹ̀ka igi ọ̀pọtọ́ mi kuro, o ti bó o jalẹ, o si sọ ọ nù; awọn ẹ̀ka rẹ̀ li a si sọ di funfun.
8Ẹ pohùnrére-ẹkun bi wundia ti a fi aṣọ ọ̀fọ dì li àmure, nitori ọkọ igbà ewe rẹ̀.
9A ké ọrẹ-jijẹ ati ọrẹ-mimu kuro ni ile Oluwa; awọn alufa, awọn iranṣẹ Oluwa, ṣọ̀fọ.
10Oko di ìgboro, ilẹ nṣọ̀fọ, nitori a fi ọkà ṣòfo: ọti-waini titun gbẹ, ororo mbuṣe.
11Ki oju ki o tì nyin, ẹnyin agbẹ̀; ẹ hu, ẹnyin olùtọju àjara, nitori alikamà ati nitori ọkà barli; nitori ikorè oko ṣègbe.
12Ajara gbẹ, igi ọ̀pọtọ́ si rọgbẹ; igi pomegranate, igi ọ̀pẹ pẹlu, ati igi appili, gbogbo igi igbo li o rọ: nitoriti ayọ̀ rọgbẹ kuro lọdọ awọn ọmọ enia.
13Ẹ dì ara nyin li amùre, si pohùnrére ẹkún ẹnyin alufa: ẹ hu, ẹnyin iranṣẹ pẹpẹ: ẹ wá, fi gbogbo oru dùbulẹ ninu aṣọ-ọ̀fọ, ẹnyin iranṣẹ Ọlọrun mi: nitori ti a dá ọrẹ-jijẹ, ati ọrẹ-mimu duro ni ile Ọlọrun nyin.
14Ẹ yà àwẹ kan si mimọ́, ẹ pè ajọ kan ti o ni irònu, ẹ pè awọn agbà, ati gbogbo awọn ará ilẹ na jọ si ile Oluwa Ọlọrun nyin, ki ẹ si kepe Oluwa,
15A! fun ọjọ na, nitori ọjọ Oluwa kù si dẹ̀dẹ, ati bi iparun lati ọwọ́ Olodumare ni yio de.
16A kò ha ké onjẹ kuro niwaju oju wa, ayọ̀ ati inu didùn kuro ninu ile Ọlọrun wa?
17Irugbìn bajẹ ninu ebè wọn, a sọ aká di ahoro, a wó abà palẹ; nitoriti a mu ọ̀ka rọ.
18Awọn ẹranko ti nkerora to! awọn agbo-ẹran dãmu, nitoriti nwọn kò ni papa oko; nitõtọ, a sọ awọn agbo agùtan di ahoro.
19Oluwa, si ọ li emi o ké, nitori iná ti run pápa oko tutú aginju, ọwọ́ iná si ti jo gbogbo igi igbẹ.
20Awọn ẹranko igbẹ gbé oju soke si ọ pẹlu: nitoriti awọn iṣàn omi gbẹ, iná si ti jó awọn pápa oko aginju run.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Joel 1: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.