Joel Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Nǹkan díẹ̀ ni a mọ̀ nípa Joẹli nítorí pé kò sí ẹ̀rí tí ó dánilójú nípa ìgbé-ayé rẹ̀. Ṣugbọn, ó dàbí ẹni pé láàrin ẹẹdẹgbẹta ọdún kí á tó bí OLUWA wa, (5th or 4th B.C.) ni a kọ ìwé yìí, ní àkókò ìjọba orílẹ̀-èdè Pasia. Joẹli sọ nípa eeṣú tí yóo ya wọ ìlú, ati pé ọ̀dá yóo run ilẹ̀ Palẹstini. Nítorí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọnyi, ó ṣe akiyesi pé ọjọ́ OLUWA ní ń bọ̀, nígbà tí OLUWA yóo jẹ àwọn tí wọ́n tako ọ̀nà òdodo rẹ̀ níyà. Wolii Joẹli jíṣẹ́ ìpè OLUWA fún àwọn ọmọ Israẹli, pé kí wọ́n ronu piwa da, ati pé OLUWA ṣe ìlérí fún àwọn eniyan náà pé òun óo ṣì mú ohun gbogbo pada bọ̀ sípò fún wọn. Ìlérí kan tí Ọlọrun tún ṣe fún àwọn eniyan náà tí ó sì ṣe pataki pupọ ni pé òun óo rán ẹ̀mí mímọ́ òun sórí gbogbo eniyan: atọkunrin atobinrin, àtọmọdé àtàgbà, láìya ẹnikẹ́ni sọ́tọ̀.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Àdánù tí eeṣú kó bá orílẹ̀-èdè náà 1:1—2:17
Ìlérí ati mú ohun gbogbo pada bọ̀ sípò 2:18-27
Ọjọ́ OLUWA 2:28—3:21

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Joel Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀