Job 40:6-24

Job 40:6-24 YBCV

Nigbana ni OLUWA da Jobu lohùn lati inu ìji ajayika wá o si wipe: Di àmure giri li ẹgbẹ rẹ bi ọkunrin, emi o bi ọ lere, ki iwọ ki o si kọ́ mi li ẹkọ́. Iwọ ha fẹ imu idajọ mi di asan? iwọ o si da mi lẹbi, ki iwọ ki o le iṣe olododo? Iwọ ni apá bi Ọlọrun, tabi iwọ le ifi ohùn san ãrá bi on? Fi ọlanla ati ọla-itayọ ṣe ara rẹ li ọṣọ, ki o si fi ogo ati ẹwa ọṣọ bò ara rẹ li aṣọ. Mu irunu ibinu rẹ jade, kiyesi gbogbo ìwa igberaga, ki o si rẹ̀ ẹ silẹ. Wò gbogbo ìwa igberaga, ki o si rẹ̀ ẹ silẹ, ki o si tẹ enia buburu mọlẹ ni ipo wọn. Fi wọn sin pọ̀ ninu erupẹ, ki o si di oju wọn ni ikọkọ. Nigbana li emi o yìn ọ pe, ọwọ ọ̀tun ara rẹ le igba ọ la. Njẹ nisisiyi kiyesi Behemotu ti mo da pẹlu rẹ, on a ma jẹ koriko bi ọ̀da-malu. Wò o nisisiyi, agbara rẹ̀ wà li ẹgbẹ́ rẹ̀, ati ipa rẹ̀ ninu iṣan ikún rẹ̀. On a ma jù ìru rẹ̀ bi igi kedari, iṣan itan rẹ̀ dijọ pọ̀. Egungun rẹ̀ ni ogusọ idẹ, egungun rẹ̀ dabi ọpa irin. On ni olu nipa ọ̀na Ọlọrun; ẹniti o da a o fi idà rẹ̀ le e lọwọ. Nitõtọ oke nlanla ni imu ohun jijẹ fun u wá, nibiti gbogbo ẹranko igbẹ ima ṣire. O dubulẹ labẹ igi Lotosi, ninu ifefe bibò ati ẹrẹ. Igi Lotosi ṣiji wọn bò o, igi arọrọ odò yi i kakiri. Kiyesi i, odò nla ṣan jọjọ, on kò salọ, o wà lailewu bi o ba ṣe odò Jordani ti ṣan lọ si ẹnu rẹ̀. Ẹnikan ha le imu u li oju rẹ̀ tabi a ma fi ọkọ gun imú rẹ̀?