Job 40:6-24
Job 40:6-24 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni OLUWA da Jobu lohùn lati inu ìji ajayika wá o si wipe: Di àmure giri li ẹgbẹ rẹ bi ọkunrin, emi o bi ọ lere, ki iwọ ki o si kọ́ mi li ẹkọ́. Iwọ ha fẹ imu idajọ mi di asan? iwọ o si da mi lẹbi, ki iwọ ki o le iṣe olododo? Iwọ ni apá bi Ọlọrun, tabi iwọ le ifi ohùn san ãrá bi on? Fi ọlanla ati ọla-itayọ ṣe ara rẹ li ọṣọ, ki o si fi ogo ati ẹwa ọṣọ bò ara rẹ li aṣọ. Mu irunu ibinu rẹ jade, kiyesi gbogbo ìwa igberaga, ki o si rẹ̀ ẹ silẹ. Wò gbogbo ìwa igberaga, ki o si rẹ̀ ẹ silẹ, ki o si tẹ enia buburu mọlẹ ni ipo wọn. Fi wọn sin pọ̀ ninu erupẹ, ki o si di oju wọn ni ikọkọ. Nigbana li emi o yìn ọ pe, ọwọ ọ̀tun ara rẹ le igba ọ la. Njẹ nisisiyi kiyesi Behemotu ti mo da pẹlu rẹ, on a ma jẹ koriko bi ọ̀da-malu. Wò o nisisiyi, agbara rẹ̀ wà li ẹgbẹ́ rẹ̀, ati ipa rẹ̀ ninu iṣan ikún rẹ̀. On a ma jù ìru rẹ̀ bi igi kedari, iṣan itan rẹ̀ dijọ pọ̀. Egungun rẹ̀ ni ogusọ idẹ, egungun rẹ̀ dabi ọpa irin. On ni olu nipa ọ̀na Ọlọrun; ẹniti o da a o fi idà rẹ̀ le e lọwọ. Nitõtọ oke nlanla ni imu ohun jijẹ fun u wá, nibiti gbogbo ẹranko igbẹ ima ṣire. O dubulẹ labẹ igi Lotosi, ninu ifefe bibò ati ẹrẹ. Igi Lotosi ṣiji wọn bò o, igi arọrọ odò yi i kakiri. Kiyesi i, odò nla ṣan jọjọ, on kò salọ, o wà lailewu bi o ba ṣe odò Jordani ti ṣan lọ si ẹnu rẹ̀. Ẹnikan ha le imu u li oju rẹ̀ tabi a ma fi ọkọ gun imú rẹ̀?
Job 40:6-24 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà náà ni OLUWA tún bá Jobu sọ̀rọ̀ láti inú ìjì líle, ó ní, “Múra gírí bí ọkunrin, mo ní ìbéèrè láti bi ọ́, o óo sì dá mi lóhùn. Ṣé o fẹ́ sọ pé mò ń ṣe àìdára ni? O fẹ́ dá mi lẹ́bi kí á lè dá ọ láre? Ṣé o lágbára bí èmi Ọlọrun, àbí o lè sán wàá bí ààrá, nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, fi ọlá ati ìyìn ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́, kí o sì fi ògo ati ẹwà bo ara rẹ bí aṣọ. Fi ibinu rẹ hàn, wo gbogbo àwọn agbéraga, kí o sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀. Wo gbogbo àwọn agbéraga, kí o sì sọ wọ́n di yẹpẹrẹ, rún àwọn ẹni ibi mọ́lẹ̀ ní ipò wọn. Bo gbogbo wọn mọ́lẹ̀ papọ̀, dì wọ́n ní ìgbèkùn sí ipò òkú. Nígbà náà ni n óo gbà pé, agbára rẹ lè fún ọ ní ìṣẹ́gun. “Wo Behemoti, ẹran ńlá inú omi, tí mo dá gẹ́gẹ́ bí mo ti dá ọ, koríko ni ó ń jẹ bíi mààlúù! Wò ó bí ó ti lágbára tó! Ati irú okun tí awọ inú rẹ̀ ní. Ìrù rẹ̀ dúró ṣánṣán bí igi kedari, gbogbo iṣan itan rẹ̀ dì pọ̀. Egungun rẹ̀ dàbí ọ̀pá idẹ, ọwọ́ ati ẹsẹ̀ rẹ̀ rí bí irin. “Ó wà lára àwọn ohun àkọ́kọ́ tí èmi Ọlọrun dá, sibẹ ẹlẹ́dàá rẹ̀ nìkan ló lè pa á. Orí àwọn òkè ni ó ti ń rí oúnjẹ jẹ, níbi tí àwọn ẹranko ìgbẹ́ ti ń ṣeré. Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi lotusi, lábẹ́ ọ̀pá ìyè ninu ẹrẹ̀. Igi lotusi ni ó ń ṣíji bò ó, igi tí ó wà létí odò yí i ká. Kò náání ìgbì omi, kò bẹ̀rù bí odò Jọdani tilẹ̀ ru dé bèbè rẹ̀. Ṣé eniyan lè fi ìwọ̀ mú un? Tabi kí á fi ọ̀kọ̀ lu ihò sí imú rẹ̀?
Job 40:6-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ní OLúWA dá Jobu lóhùn láti inú ìjì àyíká wá, ó sì wí pé: “Di àmùrè gírí ní ẹgbẹ́ rẹ bí ọkùnrin, èmi ó bi ọ léèrè, kí ìwọ kí ó sì dá mi lóhùn. “Ìwọ ha fẹ́ mú ìdájọ́ mi di asán? Ìwọ ó sì dá mi lẹ́bi, kí ìwọ lè ṣe olódodo Ìwọ ni apá bí Ọlọ́run tàbí ìwọ lè fi ohùn sán àrá bí òun? Fi ọláńlá àti ọlá ìtayọ rẹ̀ ṣe ara rẹ ní ọ̀ṣọ́, tí ó sì fi ògo àti títóbi ọ̀ṣọ́ bo ara ní aṣọ. Mú ìrunú ìbínú rẹ jáde; kíyèsí gbogbo ìwà ìgbéraga rẹ kí o sì rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀. Wo gbogbo ìwà ìgbéraga, ènìyàn kí o sì rẹ ẹ sílẹ̀ kí o sì tẹ ènìyàn búburú mọ́lẹ̀ ní ipò wọn. Sin gbogbo wọn papọ̀ nínú erùpẹ̀, kí o sì di ojú ìkọ̀kọ̀ wọn ní isà òkú Nígbà náà ní èmi ó yìn ọ́ pé, ọwọ́ ọ̀tún ara rẹ lè gbà ọ́ là. “Ǹjẹ́ nísinsin yìí kíyèsi Behemoti, tí mo dá pẹ̀lú rẹ, òun a máa jẹ koríko bí ọ̀dá màlúù. Wò o nísinsin yìí, agbára rẹ wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ, àti ipa rẹ nínú ìṣàn ìkún rẹ. Òun a máa jù ìrù rẹ̀ bí i igi kedari; Iṣan itan rẹ̀ dìjọ pọ̀. Egungun rẹ̀ ní ògùṣọ̀ idẹ; Egungun rẹ̀ dàbí ọ̀pá irin. Òun ni olórí nínú àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run; síbẹ̀ Ẹlẹ́dàá rẹ̀ fi idà rẹ̀ lé e lọ́wọ́. Nítòótọ́ òkè ńláńlá ní i mu ohun jíjẹ fún un wá, níbi tí gbogbo ẹranko igbó máa ṣiré ní ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀. Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi lótusì, lábẹ́ eèsún àti ẹrẹ̀. Igi lótusì ṣíji wọn bò o; igi arọrọ odò yí i káàkiri. Kíyèsi i, odò ńlá sàn jọjọ, òun kò sálọ; ó wà láìléwu bí ó bá ṣe pé odò Jordani ti ṣàn lọ sí ẹnu rẹ̀. Ẹnìkan ha lè mú un ní ojú rẹ̀, tàbí dẹkùn fún tàbí a máa fi ọ̀kọ̀ gún imú rẹ̀?