Job 32:6-10

Job 32:6-10 YBCV

Elihu, ọmọ Barakeli, ara Busi, dahùn o si wipe, Ọmọde li emi, àgba si li ẹnyin; njẹ nitorina ni mo duro, mo si mbẹ̀ru lati fi ìmọ mi hàn nyin. Emi wipe, ọjọ-jọjọ ni iba sọ̀rọ, ati ọ̀pọlọpọ ọdun ni iba ma kọ́ni li ọgbọ́n. Ṣugbọn ẹmi kan ni o wà ninu enia, ati imisi Olodumare ni isi ma fun wọn li oye. Enia nlanla kì iṣe ọlọgbọ́n, bẹ̃ni awọn àgba li oye idajọ kò ye. Nitorina li emi ṣe wipe, ẹ dẹtisilẹ si mi, emi pẹlu yio fi ìmọ mi hàn.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Job 32:6-10