Job 32

32
Ọ̀rọ̀ Elihu
(Job 32:1—37:24)
1BẸ̃NI awọn ọkunrin mẹtẹta wọnyi dakẹ lati da Jobu lohùn, nitori o ṣe olododo loju ara rẹ̀.
2Nigbana ni inu bi Elihu, ọmọ Barakeli, ara Busi, lati ibatan idile Ramu; o binu si Jobu, nitoriti o da ara rẹ̀ lare kàka ki o da Ọlọrun lare.
3Inu rẹ̀ si bi si awọn ọ̀rẹ rẹ̀ mẹtẹta, nitoriti nwọn kò ni idahùn, bẹ̃ni nwọn dá Jobu lẹbi.
4Njẹ Elihu ti duro titi Jobu fi sọ̀rọ tan, nitoriti awọn wọnyi dàgba jù on lọ ni iye ọjọ.
5Nigbati Elihu ri pe idahùn ọ̀rọ kò si li ẹnu awọn ọkunrin mẹtẹta wọnyi, nigbana ni o binu.
6Elihu, ọmọ Barakeli, ara Busi, dahùn o si wipe, Ọmọde li emi, àgba si li ẹnyin; njẹ nitorina ni mo duro, mo si mbẹ̀ru lati fi ìmọ mi hàn nyin.
7Emi wipe, ọjọ-jọjọ ni iba sọ̀rọ, ati ọ̀pọlọpọ ọdun ni iba ma kọ́ni li ọgbọ́n.
8Ṣugbọn ẹmi kan ni o wà ninu enia, ati imisi Olodumare ni isi ma fun wọn li oye.
9Enia nlanla kì iṣe ọlọgbọ́n, bẹ̃ni awọn àgba li oye idajọ kò ye.
10Nitorina li emi ṣe wipe, ẹ dẹtisilẹ si mi, emi pẹlu yio fi ìmọ mi hàn.
11Kiyesi i, emi ti duro de ọ̀rọ nyin, emi fetisi aroye nyin, nigbati ẹnyin nwá ọ̀rọ ti ẹnyin o sọ.
12Ani mo fiyesi nyin tinutinu, si kiyesi i, kò si ẹnikan ninu nyin ti o le já Jobu li irọ́, tabi ti o lè ida a lohùn ọ̀rọ rẹ̀!
13Ki ẹnyin ki o má ba wipe, awa wá ọgbọ́n li awari: Ọlọrun li o lè bi i ṣubu, kì iṣe enia.
14Bi on kò ti sọ̀rọ si mi, bẹ̃li emi kì yio fi ọ̀rọ nyin da a lohùn.
15Ẹnu si yà wọn, nwọn kò si dahùn mọ́, nwọn ṣiwọ ọ̀rọ isọ.
16Mo si reti, nitoriti nwọn kò si fọhùn, nwọn dakẹ jẹ, nwọn kò si dahùn mọ́.
17Bẹ̃li emi o si dahùn nipa ti emi, emi pẹlu yio si fi ìmọ mi hàn.
18Nitoripe emi kún fun ọ̀rọ sisọ, ẹmi nrọ̀ mi ni inu mi.
19Kiyesi i, ikùn mi dabi ọti-waini, ti kò ni oju-iho; o mura tan lati bẹ́ bi igo-awọ titun.
20Emi o sọ, ki ara ki o le rọ̀ mi, emi o ṣi ète mi, emi o si dahùn.
21Lotitọ emi kì yio ṣe ojusaju enia, bẹ̃li emi kì yio si ṣe ipọnni fun ẹnikan.
22Nitoripe emi kò mọ̀ ọ̀rọ ipọnni sọ, ni ṣiṣe bẹ̃ Ẹlẹda mi yio mu mi kuro lọgan.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Job 32: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀