Job 28:20-28

Job 28:20-28 YBCV

Nibo ha li ọgbọn ti jade wá; tabi nibo ni ibi oye? A ri pe, o lumọ kuro li oju awọn alãyè gbogbo, o si fara sin fun ẹiyẹ oju ọrun. Ibi iparun (Abaddoni) ati ikú wipe, Awa ti fi etí wa gburo rẹ̀. Ọlọrun li o moye ipa ọ̀na rẹ̀, o si mọ̀ ipo rẹ̀, Nitoripe o woye de opin aiye, o si ri gbogbo isalẹ ọrun. Lati dà òṣuwọn fun afẹfẹ, o si fi òṣuwọn wọ̀n omiyomi. Nigbati o paṣẹ fun òjo, ti o si la ọ̀na fun mànamana ãrá: Nigbana li o ri i, o si sọ ọ jade, o pèse rẹ̀ silẹ, ani o si wadi rẹ̀ ri. Ati fun enia li o wipe, kiyesi i; Ẹru Oluwa, eyi li ọgbọ́n, ati lati jade kuro ninu ìwa-buburu eyi li oye!

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Job 28:20-28