“Níbo ni ọgbọ́n ti ń wá; níbo sì ni ìmọ̀ wà? Ó pamọ́ lójú gbogbo ẹ̀dá alààyè, ati lójú àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run. Ìparun ati ikú jẹ́wọ́ pé, ‘Àhesọ ni ohun tí a gbọ́ nípa rẹ̀.’ “Ọlọrun nìkan ló mọ ọ̀nà rẹ̀, òun nìkan ló mọ ibùjókòó rẹ̀. Nítorí pé ó ń wo gbogbo ayé, ó sì ń rí ohun gbogbo tí ó wà lábẹ́ ọ̀run. Nígbà tí ó fún afẹ́fẹ́ ní agbára, tí ó sì ṣe ìdíwọ̀n omi, nígbà tí ó pàṣẹ fún òjò, tí ó sì lànà fún mànàmáná. Lẹ́yìn náà ó rí i, ó sì sọ ọ́ jáde, ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, ó sì dán an wò. Nígbà náà ni ó sọ fún eniyan pé, ‘Wò ó, ìbẹ̀rù OLUWA ni ọgbọ́n, kí á yẹra fún ibi sì ni ìmọ̀.’ ”
Kà JOBU 28
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: JOBU 28:20-28
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò