Job 15

15
Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Keji
(Job 15:1—21:34)
1NIGBANA ni Elifasi, ara Tema, dahùn wipe,
2Ọlọgbọ́n a ma sọ̀rọ ìmọ asan, ki o si ma fi afẹfẹ ila õrùn kún ara rẹ̀ ninu:
3On le ma fi aroye sọ̀rọ ti kò li ère, tabi pẹlu ọ̀rọ ninu eyiti kò le fi ṣe rere?
4Ani iwọ ṣa ìbẹru tì, iwọ si dí adura lọna niwaju Ọlọrun.
5Nitoripe ẹnu ara rẹ li o jẹwọ ẹ̀ṣẹ rẹ, iwọ si yàn ahọn alarekereke li ãyò.
6Ẹnu ara rẹ li o da ọ lẹbi, kì iṣe emi, ani ète ara rẹ li o jẹri tì ọ.
7Iwọ́ ha iṣe ọkunrin ti a kọ́ bi? tabi a ha dá ọ ṣaju awọn oke?
8Iwọ gburo aṣiri Ọlọrun ri, tabi iwọ ha dá ọgbọ́n duro sọdọ ara rẹ?
9Kini iwọ mọ̀ ti awa kò mọ̀, oye kili o ye ọ ti kò si ninu wa.
10Elewú ogbó ati ògbologbo enia wà pẹlu wa, ti nwọn gbó jù baba rẹ lọ.
11Itunu Ọlọrun ha kere lọdọ rẹ, ọ̀rọ kan si ṣe jẹjẹ jù lọdọ rẹ.
12Ẽṣe ti aiya rẹ fi ndà ọ kiri, tabi kini iwọ tẹjumọ wofin.
13Ti iwọ fi yi ẹmi rẹ pada lodi si Ọlọrun, ti o fi njẹ ki ọ̀rọkọrọ ki o ma bọ li ẹnu rẹ bẹ̃?
14Kili enia ti o fi mọ́? ati ẹniti a tinu obinrin bi ti yio fi ṣe olododo?
15Kiyesi i, on (Ọlọrun) kò gbẹkẹle awọn ẹni-mimọ́ rẹ̀, ani awọn ọrun kò mọ́ li oju rẹ̀.
16Ambọtori enia, ẹni irira ati elẽri, ti nmu ẹ̀ṣẹ bi ẹni mu omi.
17Emi o fi hàn ọ, gbọ́ ti emi, eyi ti emi si ri, on li emi o si sọ.
18Ti awọn ọlọgbọ́n ti pa ni ìtan lati ọdọ awọn baba wọn wá, ti nwọn kò si fi pamọ́.
19Awọn ti a fi ilẹ aiye fun nikan, alejo kan kò si là wọn kọja.
20Enia buburu nṣe lãlã, pẹlu irora li ọjọ rẹ̀ gbogbo, ati iye ọdun li a dá silẹ fun aninilara.
21Iró ìbẹru mbẹ li eti rẹ̀, ninu irora ni alaparun a dide si i.
22O kò gbagbọ pe on o jade kuro ninu okunkun; a si ṣa a sapakan fun idà.
23O nwò kakiri fun onjẹ, wipe, nibo li o wà, o mọ̀ pe ọjọ òkunkun sunmọ tosi.
24Ipọnju pẹlu irora ọkàn yio mu u bẹ̀ru, nwọn o si ṣẹgun rẹ̀ bi ọba ti imura ogun.
25Nitoripe o ti nawọ rẹ̀ jade lodi si Ọlọrun, o si mura rẹ̀ le lodi si Olodumare.
26O sure, o si fi ẹhin giga kọlu u, ani fi ike-koko apata rẹ̀ ti o nipọn.
27Nitoriti on fi ọra rẹ̀ bo ara rẹ̀ loju, o si ṣe jabajába ọra si ẹgbẹ rẹ̀.
28On si gbe inu ahoro ilu itakété, ati ninu ileyile ti enia kò gbe mọ́, ti o mura tan lati di àlapa.
29On kò le ilà, bẹ̃ni ohun ini rẹ̀ kò le iduro pẹ, bẹ̃ni kò le imu pipé rẹ̀ duro pẹ lori aiye.
30On kì yio jade kuro ninu okunkun, ọ̀wọ-iná ni yio jo ẹká rẹ̀, ati nipasẹ ẹmi ẹnu rẹ̀ ni yio ma kọja lọ kuro.
31Ki on ki o má ṣe gbẹkẹle asan, o tan ara rẹ̀ jẹ; nitoripe asan ni yio jasi ère rẹ̀.
32A o mu u ṣẹ ṣaju pipe ọjọ rẹ̀, ẹka rẹ̀ kì yio si tutu.
33Yio si gbòn talubọ eso rẹ̀ dànu bi àjara, yio si rẹ̀ itana rẹ̀ nù bi ti igi olifi.
34Nitoripe ajọ awọn àgabagebe yio tuka, iná ni yio si jo agọ abẹtẹlẹ.
35Nwọn loyun ìwa-ika, nwọn si bi ẹ̀ṣẹ, ikùn wọn si pèse ẹ̀tan.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Job 15: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀