Bi iwọ ba tun ọkàn rẹ ṣe, ti iwọ si nawọ rẹ sọdọ rẹ̀. Bi aiṣedede kan ba mbẹ lọwọ rẹ, mu u kuro si ọ̀na jijin rére, máṣe jẹ ki iwàkiwa kó wà ninu agọ rẹ. Nigbana ni iwọ o gbe oju rẹ soke laini abawọn, ani iwọ o duro ṣinṣin, iwọ kì yio si bẹ̀ru. Nitoripe iwọ o gbagbe òṣi rẹ, iwọ o si ranti rẹ̀ bi omi ti o ti ṣàn kọja lọ. Ọjọ aiye rẹ yio si mọlẹ jù ọsan gangan lọ, bi okunkun tilẹ bò ọ mọlẹ nisisiyi, iwọ o dabi owurọ̀. Iwọ o si wà lailewu, nitoripe ireti wà, ani iwọ o rin ilẹ rẹ wò, iwọ o si simi li alafia. Iwọ o si dubulẹ pẹlu kì yio si sí ẹniti yio dẹ̀ruba ọ, ani ọ̀pọ enia yio ma wá oju-rere rẹ. Ṣugbọn oju eniakenia yio mófo, nwọn kì yio le sala, ireti wọn a si dabi ẹniti o jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ.
Kà Job 11
Feti si Job 11
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Job 11:13-20
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò