“Bí o bá fi ọkàn rẹ sí ohun tí ó tọ́, o óo lè nawọ́ sí i. Bí o bá ń dẹ́ṣẹ̀, má dẹ́ṣẹ̀ mọ́, má sì ṣe jẹ́ kí ìwà burúkú, wà ní ọwọ́ rẹ. Nígbà náà ni o óo tó lè fi ìgboyà gbójú sókè láìlẹ́bi; o óo wà láìléwu, o kò sì ní bẹ̀rù. O óo gbàgbé àwọn ìyọnu rẹ, nígbà tí o bá sì ranti rẹ̀, yóo dàbí ìkún omi tí ó ti wọ́ lọ. Ayé rẹ yóo mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán gangan lọ; òkùnkùn rẹ yóo sì dàbí òwúrọ̀. Ọkàn rẹ óo balẹ̀, nítorí pé o ní ìrètí, a óo dáàbò bò ọ́, o óo sì sinmi láìséwu. O óo sùn, láìsí ìdágìrì, ọpọlọpọ eniyan ni wọn óo sì máa wá ojurere rẹ. Àwọn ẹni ibi óo pòfo; gbogbo ọ̀nà tí wọ́n lè gbà sá àsálà ni yóo parẹ́ mọ́ wọn lójú, ikú ni yóo sì jẹ́ ìrètí wọn.”
Kà JOBU 11
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: JOBU 11:13-20
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò