Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba gbọ́ ọ̀rọ mi, ti o ba si gbà ẹniti o rán mi gbọ́, o ni iye ti kò nipẹkun, on kì yio si wá si idajọ; ṣugbọn o ti ré ikú kọja bọ si ìye.
Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Wakati na mbọ̀, o si de tan nisisiyi, nigbati awọn okú yio gbọ́ ohùn Ọmọ Ọlọrun: awọn ti o ba gbọ yio si yè.
Nitoripe gẹgẹ bi Baba ti ni iye ninu ara rẹ̀; gẹgẹ bẹ̃li o si fifun Ọmọ lati ni iye ninu ara rẹ̀;
O si fun u li aṣẹ lati mã ṣe idajọ pẹlu, nitoriti on iṣe Ọmọ-enia.
Ki eyi ki o máṣe yà nyin li ẹnu; nitoripe wakati mbọ̀, ninu eyiti gbogbo awọn ti o wà ni isà okú yio gbọ́ ohùn rẹ̀.
Nwọn o si jade wá; awọn ti o ṣe rere, si ajinde ìye; awọn ti o si ṣe buburu, si ajinde idajọ.
Emi kò le ṣe ohun kan fun ara mi: bi mo ti ngbọ́, mo ndajọ: ododo si ni idajọ mi; nitori emi kò wá ifẹ ti emi tikarami, bikoṣe ifẹ ti ẹniti o rán mi.
Bi emi ba njẹri ara mi, ẹrí mi kì iṣe otitọ.
Ẹlomiran li ẹniti njẹri mi; emi si mọ̀ pe, otitọ li ẹrí mi ti o jẹ́.
Ẹnyin ti ranṣẹ lọ sọdọ Johanu, on si ti jẹri si otitọ.
Ṣugbọn emi kò gba ẹrí lọdọ enia: ṣugbọn nkan wọnyi li emi nsọ, ki ẹnyin ki o le là.
On ni fitila ti o njó, ti o si ntànmọlẹ: ẹnyin si fẹ fun sã kan lati mã yọ̀ ninu imọlẹ rẹ̀.
Ṣugbọn emi ni ẹri ti o pọ̀ju ti Johanu lọ: nitori iṣẹ ti Baba ti fifun mi lati ṣe pari, iṣẹ na pãpã ti emi nṣe ni njẹri mi pe, Baba li o rán mi.
Ati Baba ti o rán mi ti jẹri mi. Ẹnyin kò gbọ́ ohùn rẹ̀ nigba kan ri, bẹ̃li ẹ kò ri àwọ rẹ̀.
Ẹ kò si ni ọ̀rọ rẹ̀ lati ma gbé inu nyin: nitori ẹniti o rán, on li ẹnyin kò gbagbọ́.
Ẹnyin nwá inu iwe-mimọ́ nitori ẹnyin rò pe ninu wọn li ẹnyin ni ìye ti kò nipẹkun; wọnyi si li awọn ti njẹri mi.
Ẹnyin kò si fẹ lati wá sọdọ mi, ki ẹnyin ki o le ni ìye.
Emi kò gbà ogo lọdọ enia.
Ṣugbọn emi mọ̀ nyin pe, ẹnyin tikaranyin kò ni ifẹ Ọlọrun ninu nyin.
Emi wá li orukọ Baba mi, ẹnyin kò si gbà mi: bi ẹlomiran ba wá li orukọ ara rẹ̀, on li ẹnyin ó gbà.
Ẹnyin o ti ṣe le gbagbọ́, ẹnyin ti ngbà ogo lọdọ ara nyin, ti kò wá ogo ti o ti ọdọ Ọlọrun nikan wá?
Ẹ máṣe rò pe, emi ó fi nyin sùn lọdọ Baba: ẹniti nfi nyin sùn wà, ani Mose, ẹniti ẹnyin gbẹkẹle.
Nitoripe ẹnyin iba gbà Mose gbọ́, ẹnyin iba gbà mi gbọ́: nitori o kọ iwe nipa ti emi.
Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba gbà iwe rẹ̀ gbọ́, ẹnyin o ti ṣe gbà ọ̀rọ mi gbọ́?