“Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó bá gba ẹni tí ó rán mi níṣẹ́ gbọ́, olúwarẹ̀ ní ìyè ainipẹkun, kò ní wá sí ìdájọ́, ṣugbọn ó ti ré ikú kọjá, ó sì ti bọ́ sinu ìyè. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé àkókò ń bọ̀, ó tilẹ̀ dé tán báyìí, tí àwọn òkú yóo gbọ́ ohùn Ọmọ Ọlọrun, àwọn tí ó bá gbọ́ yóo yè. Nítorí bí Baba ti ní ìyè ninu ara rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó ti fún ọmọ ní agbára láti ní ìyè. Ó ti fún un ní àṣẹ láti ṣe ìdájọ́, nítorí òun ni Ọmọ-Eniyan. Ẹ má ṣe jẹ́ kí èyí yà yín lẹ́nu, nítorí àkókò ń bọ̀ nígbà tí gbogbo àwọn òkú tí ó wà ní ibojì yóo gbọ́ ohùn rẹ̀, tí wọn yóo sì jáde. Àwọn tí ó ti ṣe rere yóo jí dìde sí ìyè, àwọn tí ó ti ṣe ibi yóo jí dìde sí ìdálẹ́bi.
“Èmi kò lè dá nǹkankan ṣe. Ọ̀rọ̀ Baba mi tí mo bá gbọ́ ni mo fi ń ṣe ìdájọ́, òdodo sì ni ìdájọ́ mi; nítorí kì í ṣe ìfẹ́ tèmi ni mò ń wá bíkòṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́.
“Bí ó bá jẹ́ pé èmi ni mò ń jẹ́rìí ara mi, ẹ̀rí mi lè má jẹ́ òtítọ́. Ṣugbọn ẹlòmíràn ni ó ń jẹ́rìí mi, mo sì mọ̀ pé òtítọ́ ni ẹ̀rí tí ó ń jẹ́ nípa mi. Ẹ ti ranṣẹ lọ sọ́dọ̀ Johanu, ó sì ti jẹ́rìí òtítọ́. Kì í ṣe pé dandan ni fún mi pé kí eniyan jẹ́rìí gbè mí. Ṣugbọn mo sọ èyí fun yín kí ẹ lè ní ìgbàlà. Johanu dàbí fìtílà tí ó ń tàn, tí ó sì mọ́lẹ̀. Ó dùn mọ yín fún àkókò díẹ̀ láti máa yọ̀ ninu ìmọ́lẹ̀ tí ó fi fun yín. Ṣugbọn mo ní ẹ̀rí tí ó tóbi ju ti Johanu lọ. Àwọn iṣẹ́ tí Baba ti fún mi pé kí n parí, àní àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe, àwọn ni ẹlẹ́rìí mi pé Baba ni ó rán mi níṣẹ́. Baba tí ó rán mi níṣẹ́ ti jẹ́rìí mi. Ẹnikẹ́ni kò ì tíì gbọ́ ohùn rẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò rí i bí ó ti rí rí. Ẹ kò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbé inú yín nítorí ẹ kò gba ẹni tí ó rán níṣẹ́ gbọ́. Ẹ̀ ń wá inú Ìwé Mímọ́ káàkiri nítorí pé ẹ rò pé ẹ óo rí ọ̀rọ̀ ìyè ainipẹkun ninu rẹ̀. Ẹ̀rí mi gan-an ni wọ́n sì ń jẹ́. Sibẹ ẹ kò fẹ́ tọ̀ mí wá kí ẹ lè ní ìyè.
“Èmi kò wá ọlá láti ọ̀dọ̀ eniyan. Ṣugbọn mo mọ̀ yín, mo sì mọ̀ pé ẹ kò ní ìfẹ́ Ọlọrun ninu yín. Èmi wá ní orúkọ Baba mi, ẹ̀yin kò gbà mí. Ṣugbọn bí ẹlòmíràn bá wá ní orúkọ ara rẹ̀, ẹ óo gbà á. Báwo ni ẹ ti ṣe lè gbàgbọ́ nígbà tí ó jẹ́ pé láàrin ara yín ni ẹ ti ń gba ọlá, tí ẹ kò wá ọlá ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun nìkan ṣoṣo? Ẹ má ṣe rò pé èmi ni n óo fi yín sùn níwájú Baba, Mose tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé gan-an ni yóo fi yín sùn. Bí ẹ bá gba Mose gbọ́, ẹ̀ bá gbà mí gbọ́, nítorí èmi ni ọ̀rọ̀ ìwé tí ó kọ bá wí. Ṣugbọn bí ẹ kò bá gba ohun tí ó kọ gbọ́, báwo ni ẹ óo ti ṣe gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́?”