LẸHIN nkan wọnyi, Jesu tún fi ara rẹ̀ hàn fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ leti okun Tiberia; bayi li o si farahàn.
Simoni Peteru, ati Tomasi ti a npè ni Didimu, ati Natanaeli ara Kana ti Galili, ati awọn ọmọ Sebede, ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ meji miran jùmọ wà pọ̀.
Simoni Peteru wi fun wọn pe, Emi nlọ ipẹja. Nwọn wi fun u pe, Awa pẹlu mba ọ lọ. Nwọn jade, nwọn si wọ̀ inú ọkọ̀; li oru na nwọn kò si mú ohunkohun.
Ṣugbọn nigbati ilẹ bẹrẹ si imọ́, Jesu duro leti okun: ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin kò mọ̀ pe Jesu ni.
Nitorina Jesu wi fun wọn pe, Ẹnyin ọmọde, ẹ li onjẹ diẹ bi? Nwọn da a lohùn wipe, Rára o.
O si wi fun wọn pe, Ẹ sọ àwọn si apa ọtùn ọkọ̀, ẹnyin ó si ri. Nitorina nwọn sọ ọ, nwọn kò si le fà a jade nitori ọpọ ẹja.
Nitorina li ọmọ-ẹhin na ti Jesu fẹran wi fun Peteru pe, Oluwa ni. Nigbati Simoni Peteru gbọ́ pe Oluwa ni, bẹli o di amure ẹ̀wu rẹ̀ mọra, (nitori o wà ni ìhoho), o si gbé ara rẹ̀ sọ sinu okun.
Ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin iyoku mu ọkọ̀ kekere kan wá (nitoriti nwọn kò jina silẹ, ṣugbọn bi iwọn igba igbọnwọ); nwọn nwọ́ àwọn nã ti o kún fun ẹja.
Nigbati nwọn gúnlẹ, nwọn ri iná ẹyín nibẹ, ati ẹja lori rẹ̀, ati akara.
Jesu wi fun wọn pe, Ẹ mú ninu ẹja ti ẹ pa nisisiyi wá.
Nitorina Simoni Peteru gòke, o si fà àwọn na wálẹ, o kún fun ẹja nla, o jẹ mẹtalelãdọjọ: bi nwọn si ti pọ̀ to nì, àwọn nã kò ya.
Jesu wi fun wọn pe, Ẹ wá jẹun owurọ̀. Kò si si ẹnikan ninu awọn ọmọ-ẹhin ti o jẹ bi i pe, Tani iwọ iṣe? nitoriti nwọn mọ̀ pe Oluwa ni.
Jesu wá, o si mu akara, o si fifun wọn, gẹgẹ bẹ̃ si li ẹja.
Eyi ni igba kẹta nisisiyi ti Jesu farahàn awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, lẹhin igbati o jinde kuro ninu okú.