Joh 21:1-14

Joh 21:1-14 Bibeli Mimọ (YBCV)

LẸHIN nkan wọnyi, Jesu tún fi ara rẹ̀ hàn fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ leti okun Tiberia; bayi li o si farahàn. Simoni Peteru, ati Tomasi ti a npè ni Didimu, ati Natanaeli ara Kana ti Galili, ati awọn ọmọ Sebede, ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ meji miran jùmọ wà pọ̀. Simoni Peteru wi fun wọn pe, Emi nlọ ipẹja. Nwọn wi fun u pe, Awa pẹlu mba ọ lọ. Nwọn jade, nwọn si wọ̀ inú ọkọ̀; li oru na nwọn kò si mú ohunkohun. Ṣugbọn nigbati ilẹ bẹrẹ si imọ́, Jesu duro leti okun: ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin kò mọ̀ pe Jesu ni. Nitorina Jesu wi fun wọn pe, Ẹnyin ọmọde, ẹ li onjẹ diẹ bi? Nwọn da a lohùn wipe, Rára o. O si wi fun wọn pe, Ẹ sọ àwọn si apa ọtùn ọkọ̀, ẹnyin ó si ri. Nitorina nwọn sọ ọ, nwọn kò si le fà a jade nitori ọpọ ẹja. Nitorina li ọmọ-ẹhin na ti Jesu fẹran wi fun Peteru pe, Oluwa ni. Nigbati Simoni Peteru gbọ́ pe Oluwa ni, bẹli o di amure ẹ̀wu rẹ̀ mọra, (nitori o wà ni ìhoho), o si gbé ara rẹ̀ sọ sinu okun. Ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin iyoku mu ọkọ̀ kekere kan wá (nitoriti nwọn kò jina silẹ, ṣugbọn bi iwọn igba igbọnwọ); nwọn nwọ́ àwọn nã ti o kún fun ẹja. Nigbati nwọn gúnlẹ, nwọn ri iná ẹyín nibẹ, ati ẹja lori rẹ̀, ati akara. Jesu wi fun wọn pe, Ẹ mú ninu ẹja ti ẹ pa nisisiyi wá. Nitorina Simoni Peteru gòke, o si fà àwọn na wálẹ, o kún fun ẹja nla, o jẹ mẹtalelãdọjọ: bi nwọn si ti pọ̀ to nì, àwọn nã kò ya. Jesu wi fun wọn pe, Ẹ wá jẹun owurọ̀. Kò si si ẹnikan ninu awọn ọmọ-ẹhin ti o jẹ bi i pe, Tani iwọ iṣe? nitoriti nwọn mọ̀ pe Oluwa ni. Jesu wá, o si mu akara, o si fifun wọn, gẹgẹ bẹ̃ si li ẹja. Eyi ni igba kẹta nisisiyi ti Jesu farahàn awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, lẹhin igbati o jinde kuro ninu okú.

Joh 21:1-14 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn èyí, Jesu tún fara han àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ní òkun Tiberiasi. Bí ó ṣe farahàn wọ́n nìyí: Simoni Peteru, ati Tomasi tí wọn ń pè ní Didimu (èyí ni “Ìbejì”) ati Nataniẹli ará Kana, ni ilẹ̀ Galili, ati àwọn ọmọ Sebede ati àwọn meji mìíràn ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wà ní ibìkan. Simoni Peteru sọ fún wọn pé, “Mò ń lọ pa ẹja.” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwa náà yóo bá ọ lọ.” Wọ́n bá jáde lọ, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi. Ní gbogbo alẹ́ ọjọ́ náà wọn kò rí ẹja kankan pa. Nígbà tí ó di àfẹ̀mọ́jú Jesu dúró ní èbúté, ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kò mọ̀ pé Jesu ni. Jesu bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ọmọde, ǹjẹ́ ẹ ní ohunkohun fún jíjẹ?” Wọ́n bá dá a lóhùn pé, “Rárá o!” Ó wí fún wọn pé, “Ẹ ju àwọ̀n sí apá ọ̀tún ọkọ̀, ẹ óo rí ẹja pa.” Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, ni wọn kò bá lè fa àwọ̀n mọ́, nítorí ọ̀pọ̀ ẹja. Ọmọ-ẹ̀yìn tí Jesu fẹ́ràn sọ fún Peteru pé, “Oluwa ni!” Nígbà tí Simoni Peteru gbọ́ pé Oluwa ni, ó wọ ẹ̀wù rẹ̀, nítorí ó ti bọ́ra sílẹ̀ fún iṣẹ́, ó bá bẹ́ sinu òkun, ó ń lúwẹ̀ẹ́ lọ sébùúté. Ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yòókù ń bọ̀ ninu ọkọ̀, nítorí wọn kò jìnnà sí èbúté, wọn kò jù bí ìwọ̀n ọgọrun-un ìgbésẹ̀ lọ. Nígbà tí wọ́n gúnlẹ̀, wọ́n rí ẹja lórí iná eléèédú, wọ́n tún rí burẹdi. Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ mú wá ninu ẹja tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ pa.” Nígbà náà ni Simoni Peteru gòkè, ó fa àwọ̀n sí èbúté. Àwọ̀n náà kún fún ẹja ńláńlá, mẹtalelaadọjọ. Ṣugbọn bí wọ́n ti pọ̀ tó yìí, àwọ̀n náà kò ya. Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ wá jẹun.” Kò sí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí ó bi í pé, “Ta ni ọ́?” Wọ́n mọ̀ pé Oluwa ni. Jesu wá, ó mú burẹdi, ó fi fún wọn. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó fún wọn ní ẹja jẹ. Èyí ni ó di ìgbà kẹta tí Jesu fara han àwọn ọmọ-ẹ̀yìn lẹ́yìn ajinde rẹ̀ ninu òkú.

Joh 21:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jesu tún fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ létí Òkun Tiberia; báyìí ni ó sì farahàn. Simoni Peteru, àti Tomasi tí a ń pè ní Didimu, àti Natanaeli ará Kana ti Galili, àti àwọn ọmọ Sebede, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjì mìíràn jùmọ̀ wà pọ̀. Simoni Peteru wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ pẹja!” Wọ́n wí fún un pé, “Àwa pẹ̀lú ń bá ọ lọ.” Wọ́n jáde, wọ́n sì wọ inú ọkọ̀ ojú omi; ní òru náà wọn kò sì mú ohunkóhun. Ṣùgbọ́n nígbà tí ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mọ́, Jesu dúró létí Òkun: ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kò mọ̀ pé Jesu ni. Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ọmọdé, ẹ ní ẹja díẹ̀ bí?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Rárá o.” Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ sọ àwọ̀n sí apá ọ̀tún ọkọ̀ ojú omi, ẹ̀yin yóò sì rí.” Nígbà tí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, wọn kò sì lè fà á jáde nítorí ọ̀pọ̀ ẹja. Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà tí Jesu fẹ́ràn wí fún Peteru pé, “Olúwa ni!” Nígbà tí Simoni Peteru gbọ́ pé Olúwa ni, bẹ́ẹ̀ ni ó di àmùrè ẹ̀wù rẹ̀ mọ́ra, nítorí tí ó wà ní ìhòhò, ó sì gbé ara rẹ̀ sọ sínú Òkun. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù mú ọkọ̀ ojú omi kékeré kan wá nítorí tí wọn kò jìnà sílẹ̀, ṣùgbọ́n bí ìwọ̀n igba ìgbọ̀nwọ́; wọ́n ń wọ́ àwọ̀n náà tí ó kún fún ẹja. Nígbà tí wọ́n gúnlẹ̀, wọ́n rí ẹ̀yín iná níbẹ̀ àti ẹja lórí rẹ̀ àti àkàrà. Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ mú nínú ẹja tí ẹ pa nísinsin yìí wá.” Nítorí náà, Simoni Peteru gòkè, ó sì fa àwọ̀n náà wálẹ̀, ó kún fún ẹja ńlá, ó jẹ́ mẹ́tàléláádọ́jọ: bí wọ́n sì ti pọ̀ tó náà, àwọ̀n náà kò ya. Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ wá jẹun òwúrọ̀.” Kò sì sí ẹnìkan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí ó jẹ́ bí i pé, “Ta ni ìwọ ṣe?” Nítorí tí wọ́n mọ̀ pé Olúwa ni. Jesu wá, ó sì mú àkàrà, ó sì fi fún wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹja. Èyí ni Ìgbà kẹta nísinsin yìí tí Jesu farahan àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí ó jíǹde kúrò nínú òkú.