Joh 11:55-57

Joh 11:55-57 YBCV

Ajọ irekọja awọn Ju si sunmọ etile: ọ̀pọlọpọ lati igberiko wá si gòke lọ si Jerusalemu ṣiwaju irekọja, lati yà ara wọn si mimọ́. Nigbana ni nwọn nwá Jesu, nwọn si mba ara wọ́n sọ, bi nwọn ti duro ni tẹmpili, wipe, Ẹnyin ti rò o si? pe kì yio wá si ajọ? Njẹ awọn olori alufa ati awọn Farisi ti paṣẹ pe bi ẹnikan ba mọ̀ ibi ti o gbé wà, ki o fi i hàn, ki nwọn ki o le mu u.

Àwọn fídíò fún Joh 11:55-57